« Fatwa 30 »






Bismillahir Rahmanir Rahim

 

Olodi-Sijo- Ahmadiyya ni Isilam

Ojo karundilogbon, osu kesan Odun

 

Al Fatwa International N° 30

 

Oludasile : Syed Abdul Hafeez Shah

Alabojuto eto iwe : Syed Rashid Ali.

 

 

Eyin onkawe

Assalamo Alaikun wa Rahmatullah wa Barakatuhu.

 

A se gafara pe o pe ki a to mu iroyin tuntun ti al-fatwa wa fun yin. Apapo idasimerin meji to gbeyin niyi.

 

Hazrat Syed Abdul Hafeez Shad pa ipo da, (di oloogbe).

 

Pelu edun okan ni a fi kede iku Hazrat Syed Abdul Hafeez Shad, eyi ti o waye ni. Ojo keji, osu keje. Eni adorun odun (90 years) nii se, ki o to jade laye. Inna lillahe wa inna ilahee Rajiuon. O je oguna-gbongbo, olusin ti Sindh. O si tun je oludasile ijo alatako Ahmadiyyah ijo ati Al Fatwa International.  Fun ogoji (40 years) odun ti o gbeyin ni igbesi aye re ni o fi gbe ni abule Gujjo ni agbegbe Thatta ti o si n waasu ihinrere lori ife ati alaafia ni sindh. O da Al-Hafeez Zakireen Tanzem sile nitori eyi. Ise kan pataki ti o ni igba aye re ni lati ri pe awon musulumini ni lati gbagbe aawo won, ki won si fi imo sokan latari ti Kahmah Tayyebah, gege bi Sahaba ti se.

 

Laise awawi ki ise pir, dipo bee o gbogun ti igbekele pir-Mureed fun idi pataki pe ero-okan re nipa awon ogbontagi awon sufi ode-oni ti won ni ohun gbogbo ayafi faiz lati odo awon asaaju won; nipa bee won ti so igbekele naa di eto kara-kata: O maa n so pe: mo n ko ohun ti mo mo, laipase fun awon akekoo mi mnu ase ti prii-mureedi, mo si nko ohun ti n ko mo. Zhikr (Iranti) ti Allah je akori wa ona re laye, iseda ife fun Allah (Olohun). Ojise nla Muhammad SAAW ninu okan awon akeko re ati ise Olohun ni o je koko lokan re: O bowo fun eda eniyan o si n fun olukuluku ni eto won. O maa n so pe: Alaanu ni Olohun.

 

Gbogbo irekoja wa gege bi eda eniyan ni Olohun yoo dariji, sugbon opolopo ni a o dalejo ni ojo idajo nitori ese elomiran. Nigba to ba ku dukiluku pelu tire lojo idajo, tani yoo le duro fun idariji elomiiran? O je sain logun ni Akl-e-Hala ati Siqd-e-Maqaal (Je halaal nikan ki o si so ooto) o si maa n sakiyesi ipile gbogbo ijosin won. O je agbateru igbe aye irorun. Opolopo eniyan lo maa n se abewo lodo re nitosi ati lona jijinna rere fun oniruuru isoro won, ti sain si n fi terintoyaya dawon lohun lati tan isoro won.

 

Gbogbo awon alejo re lo maa n buyi fun laifi ti eleya-meya, tabi ti olanini se, ti o si n dana ounje fun won funrare, eleyi si tesiwaju titi ojo aye re. O kere ju, eniyan mejo si mewaa lo maa n wa ninu yara ijeun re: ogunlogo awon odo lo fi awon obi won sile ti won si di akekoo labe re nitori iwa pele re, inurere, ikonimora ati isoro pele re. Sain naa si n se abojuto won lati rii wipe won n dagba sii ninu emi. Fun idi eyi iwaasun re kii po, dipo bayi igbe aye re ojoojumo si di awokose fun awon omo leyin re.

 

Ni odun 1988, Mirza Tahir Ahmad Qadiani, Khalifa kerin ati Olori Jamaat Ahmadiyyah se atejade iwe ipenija Mubahila fun gbogbo musulumi pata porongodo ti o si pe won ni opuro ati alaigbagbo, Sain faraya. O ni: subHan Allah! Eleyi ko lee je ti gbogbo Musulumi Ummah, awon omoleyin ojise-nla Olohun, Anobi Muhammad (ki ike Olohun ati anu re koma ba) ko le je alaigbagbo. Lati ojo naa ni o ti bere si tesiwaju lati maa lepa Qadianiyat Kaakiri origun mereerin aye ninu iwe ati eko re. Opo iwe kika ati iwe ilewo pelebe-pelebe ni o te jade, opo orile-ede ni o si bewo lati fi to awon Musulumi leti, pe ki won lodi si eko-etan Mirza Ghulam Ahmad Qudiani ni oruko Islam. Nipa ore-ofe Allah, mo dupe pe iru eniyan be emi yii ni anfaani lati ran-an lowo ninu ise yii. Ki Olohun (Allah) tubo fun mi ore-ofe lati tesiwaju ninu ikede yii. Amin.

 

Ni gbogbo igba ti o fi kede, opo igba ni Sain Abdul Hafeez Shah pe Mirza Tahir nija lori adura (Mubahila) ti o si n yee. Lowo Olohun ni iku ati iye wa, nigba ti akoko ba to fun eniyan lati lo, ko se eni to lee daa duro. Sugbon a ko le salai menuba pe Mirza Ghulam Ahmad Qadiani ati awon omoleyin re gbagbo pe OPURO KU NIGBA TI O WA LAAYE. AlHamdolillah, summa AlHamdolillah, Mirza Tahir Ahmad Qadiani je ipe Olorun ni ojo kokandinlogun osu kerin, odun 2003, 19-4-03 nigba aye Sain Abdul Hafeez Shah.

 

A bebe fun igbega ibujoko Sain Abdul Hafeez Shah, ki Olohun si fun wa ni hidayah lati tele awon eko re. Nipa ore-ofe ojise-nla re Muhammad SAAW, Amin.

 

Dokita; Syed Rashid Ali.

 

Iroyin lati Germany

Shaikh Raheel Ahmad gba Esin Islam

A bi Shaikh Raheem Ahmad sinu esin Ahmadi. Ogbontagi elesin Ahmadi ni awon ebi ti won si je olufokansin Mirza Ghulam Ahmad Qadiani fun bi iran meta. Oun paapaa ti fi taratara je okan pataki ninu ja maat, ti o si di ipo pataki-pataki mu ninu ijo jamaat ni Gamani (Germany). Pelu ore-ofe Olohun ni osu kejo odun 2003 oun ati idile re ko Ahmadiyyat sile won si gba Isilaamu-Islam. Ni ojo naa, o wi pe:

 

“A bi mi sinu Qudiani (Ahmadi) leyin ti mo ti keko fun opolopo odun, mo roo jinle daadaa, mo si rii daju pe ijo Jamaat Ahmadiyyat Qadiani kii se okan lara eya Isilaamu won kan n se eyi lati fi pa owo nipa fifi esin boju ni. Opo igba ni mo ti di awon ipo mu ninu Jamaat, mo si ti ni imo pupo nipa bayi, ninu eyi ti mo lero pe o ye ki n ja ara mi kuro ninu pe a nfi awuruju kowo jo ti mo si pinnu lati wa si inu esin otito ti Ojise mimo Muhammad Arabi Sall Allaho alaihe wassalam” (lwe lroyin Ojoojumo Ummat, Karachi, 27 August 2003).

 

Ninu oro re nigba ti o n ba awon eniyan soro ni Khatme Nabuwavat Conference ni Rabwah (Chanab Nagar) ni ojo kefa oju kesan-an Odun 2003, O so pe.

 

Eyin arami ninu esin Islam ti mo gba bu iyi kun emi ati awon ebi mi, ki I se mimoo se mi tabi pe mo kopa kan ni be; bi ko se pe otito lati orun wa gege bi Qurani se fihan ti o si n se ifonahan fun ehikeni ti o ba fe. Gbogbo eni ti o ba si ko ni yoo fi sile sinu okunkun biribiri (alaimokan Kufr). Ebun ope Olorun po lori mi, Sugbon ebun ope ti o poju nipe o fun eniyan lasan – lasan bi emi, emi ti mo ti laju sile si agbole Qadiani fun won iran keta si ekerin ni ore- ofe lati le bojuweyin ni ayika Qudiani. (eyin ara mi, beeni, Qadianiyat ki tomosona, dipo bee, eko etan saa ni) mo keko ni ilana Rabiwali, fun odindi odun merindinlogota. Olohun mu mi jade kuro ni okunkun wa sinu imole Islam. Ebun – ofe Olohun ko duro sibi, eniyan mesan-an ototo ninu ebi mi ni a tun jijo joko sibi ina imole ti ojise Muhammad SAAW, ati nitori Habib re SAAW, o fun mi ni iyi lati gba esin Islaamu pelu ebi. Alhamdolillah.

 

Nigba ti o n ba awon Musulumi soro, O gbawon niyanju pe ki won mase benu ate lu Qadiani, nitori pe ki se ife-inu re lo fi n se ohun to n se biko se pe eko-etan ti won fun – un. Eyi ti o se pataki ju ni pe ki won fi ife han sii, ki won si maa ba soro ologbon dipo ki won maa soro nipa iku, Hazrat Isa alaihe Asallam tabi Khatme Nabuwwat. Beere lowo awon ore Qadiani ohun to won mo nipa Mirza Sahib? Ohun ti won yoo so fun o ni pe won gbaa gege bi Maseeh Mowood ojise tabi muhaddith. Foro wa won lenu wo iru eniyan ti Mirza Sahib je boya o kunju iwon re nipa awon ti o n tele e, papa ati omo bibi inu re? So fun ki won se agbekale boya o ye leni ti a le gbagbo. Ope eniyan lasan le so nipa eyi. O dani loju gbangba pe won ko lee duro niwaju yin. Won ti fi awuruju boo loju, Sugbon pelu ise asekara ni awon ojogbon fi wa asiri ohun ikoko naa jade. Ohunkohun ti a baa fi bo won (Qadianis) loju yoo ka kuro ti a ba soro ologbon siwon pelu ogo Olohun.

 

Mo ti ni ami idaniloju pe Jamaat Ahmadiyya kii se esin musulumi, tabi eka re, Sugbon o je esin tirun ti o fara pe Islam ni ojise-nla Muhammad SAAW nigba ti a da. Ahmadiyyat sile lati owo Mirza Ghuki Ahmad Sahib. Leyin ti a gba Muhammad Mustafa SAAW, enikeni lo le di musulumi, sugbon esin Islam je esin ti Olorun yonu si, sugbon esin Qadianiyat je atowoda omo eniyan. Ko si ani-ani pe awon Qadiani pe won kii ke Kalima “la ilaha ill Allah Muhammadur Rasoolullah” amo won fi Mirza Sahub sinu re. Ti enikeni ba lodi si eyi e so pe ki won ka iwe Kalimatul Fasi lati owo Mirza Basheer ati Mirza Sahib. Sugbon nigba ti awon Musulumi ododo ban ka Kalima ti o wa lati odo Olohun ko si afikun ninu re, iru Kalima yen ni ojulowo Kalima Muhammad Mustafa SAAW. Ojise-nla fi sile fun opolopo awon sahaba sile leyin iku re sugbon ti o je pe awon ogunlogo ijo alagabangebe to gbeyin Mirza Sahib. Eni ti o ba je alabosi naa lo le duro ni ijo (Jamaat) Ahmadiyya. Gege bi Mirza Mahmud sahib funrare ida mokandinlogorun awon Ahmadi lo je alaisooto. Ijo Ahmaddiya je ijo to kan maa n gbowo lowo awon eniyan ti won kan fi esin boju lasan ni. Agbowo ipa niwon je.

 

O tesiwaja ninu oro re pelu awon Qadiani/Ahmadi, o ni.

 

Eyin ore mi ti e wa nibi, laisi ariyanjiyan, e je ki a gba pe ojise ni Mirza Ghulam Ahmad sahib. Se Olohun gba ebe awon ojise lori ara awon ijo won tabi ko se bee? Lara awon ebe ojise naa lati le je ki awon ijo re je olufokansin iberu Olorun ati asiwaju dada? Yala ebe Mirza ko je itewogba tabi ki o ma tile bebe fun igbega awon ijo re. Lona miiran ewe o ruwa loju bi Mirza Sahib se di ojise, gege bi ohun ti ijo wi, awon omo leyin re to oke million meji–200,000,000 (bi o tile je pe o ruwa loju die, e je ki a gba bee). Ko si eyo enikan ninu oye eniyan yi ti o kunju osuwo iberu Olohun, (Taqwa), ibowo fun Olorun, isedeedee, asaaju ti a lee yan fun khalifa).

 

Se laarin ebi Mirza nikan ni a ti le ri asaaju, oluberu Olohun, eni ti o n bowo fun Olorun? Lati bi ogoorun odun ti e ti wa ninu ijo yii, o ye ki enikan ti bi omo kan ti yoo ni iberu Olorun laikii se ebi Mirza Ghulam Ahmad Sahib, nitori naa o to akoko fun yin lati ronu pe kin ni en ri ninu ijo akura yii? E wa e wa sinu ijo Islam, lori egberun lona egbegberun oke aimoye eniyan le o ri ninu esin Islam.

 

E ti e je ki a ye igbe aye Mirza Sahib wo, e wo awon iwe re, oro re, e wo iwe ti awon ti won se afihan re biko se awon ti won te sugbon ti o wa ni ipamo. Ti eyin ko ri.

 

Bi emi, o ye ki eyin alara naa ti rii daju pe Mirza sahib kii se ojise tabi Muhaddith.

 

Ki Olorun tubo fi imole ati itosona re han wa ki a le wa ni ona isin tooto ti Muhammad salla Allah alaihe wa sallan. Amin.

 

(Akosile ti Sheikh Raheel Ahmad lati Germany Apejopo si khatne Nabuwuat ni Rabwah Pakistan, ni ojo kefa, osu kesan-an, odun 2003 6th September, 2003).

 

Kikuro ti Shaikh Raheel Ahmad kuro ni Jamaat kii se isele kekere. Idaamu ba awon Ahmadi pupo nitori pe okan gboogi ni ninu ijo ati wipe o je okan lara iran Ahmadi agba ti Rabwah. O papo mo ibewo si (Germany) ati yiyan Mirza Masroor Ahmadi gege bi Khalifa tuntun.

 

Pataki isele yii ye awon agba-agba ijo. (Jamaat) ati khalifa. Alabajo ti awon ijo (Jamaat) fi n gbero lati ri pe won pa Shaikh Raheel Ahmad.

 

Akewi ti Ahmadiyyat Muzaffar Ahmad naa gba esin ni (Germany).

 

Ipa ti kikuro Shaikh Raheel Ahmadi ni lara Jamaat ko tii ro rara nigba ti okan lara oguna-gbongbo egbe Ahmadi tun pinya pelu Ahmadiyyat ti o si gba esin Islam ni ojo kokandinlogun, osu kesan odun 2003 (6/9/03) Muzaffar Ahmad ti ojo, ori re je odun merindinlogoji. (36years) ni o je omo bibi ilu Peshawer ni orile ede Pakistan ti o si ti n gbe ni Germany fun odun pipe seyin. Nipa mimo riri ise re fun ijo Jamaat. O ti gba ohun-amin eye ti wura- (Gold medal) ti won si tun pee ni Akewi ti Ahmadiyyat. O si tun n sise gege bi okan pataki egbe ti Bait-ul-maal of Jamaat.

 

O kede lilo re nigbangba kuro ni Ahmadiyyat pe oun ti gba esin Islam ni Mosalasi Tauheed, ni Offenbach ni Germany lati owo Mailana Mushtaqur-Rahman. A fi idi re mule wipe Ameer ti ijo Husum, Muneer Ahmad, ati Ameer (Amiru) gbogbo-ogbo, Abdullah Wagushauser ni a ti fi to leti nipa iwe kiko, leyin eyi ti oun ati awon ebi gba iwe lati odo awon Ahmadiyya pe pipa ni won yoo pa won. Muzzafa Ahmad si ti kowe si Amiru agbegbe Columbus khan wipe won n dode won fun pipa ti ko ba jawo. Nipa eyi, o fi to won leti pe oun ko kan fe tun asiri bi awon Jamaat se n gboke gbodo, ati gbogbo akitiyan won nile ejo, bakan naa oun ko fe da ruke-rudo sile fun ijo (Jamaat) nipa dida emin won legbodo. Sugbon bi Jamaat ko ba dekun awon iwa arigi-daniyan, iwa-ese pelu ilara iwa asiwere won si oun, nigba naa won yoo pade ara won nile ejo (Iwe iroyin Umanat, Karachi 19 sept, 2003).

 

Ni ojo Jimoh ogunjo, osu kesan odun 2003, Muzaffar Ahmad n ba awon eniyan soron Mosalasi Tauheed, bayi pe:-

 

Ojo oni ni a ti ya soto fun gbogbo idile mi lapapo. A n jade kuro ninu etan arekereke, aigbagbo sinu ona Islam to mole to si gbooro. Itan so pe Quadiani ti n sote tembelekun, huwa ika, aikora-eni-ni-ijanu ti wa lati bi ogorun odun sehin. Idi iyipada mi niwonyi, Odindi odun meje ni mo fi kawe tosan-toru, pelu akiyesi awon iwa jamaat, yiyapa Jamaat kuro ni sunnat ojise nla SAAW, awon asa, ihuwa lodi si eda ati ihuwa lo di si Islam, orisirisi iwa keferi, ati igbagbo won, didori itumo Qurani kodo ati ipinu awon Muslim Ummat ni osu kerin ati (kesan odun 1974 ti o so nipa Qadiani (ti o fiwon han pe won ko si ninu agbo Islam).

 

Lona miran ewe, a gba pe Mirza Salib gbe ara re kale bii irugbin riro ti awon oyinbo – (self – cultivated seedling) to di orisa Akunlebo. Lakotan, oruko miran fun KUFR ni Qadianiism. Nitori naa emi ati awon eniyan mi, yapa kuro ninu gbogbo igbagbo iro yii a si kede iyipada wa si Islam.

 

Ewi urdu: hum aisay saada diloon kee-niyaz mandee say butoon nay kee hein jahaan mein khudeeyaan kiya kiya).

 

Nitori inu-rere awon oniwa-tutu eniyan bi awa, awon orisa ti se orisirisi ise kaakiri agbaye.

Ju gbogbo re lo a dupe pupo lowo Manlana Mushtaq -ur-Rehman, Manlana Mohammed Ahmed, Iftikhar Ahmed ati Shaikh Raheal Ahmad fun itonisona ati ipinnu re lati sise fun Islam.

 

(Daily Ummat, karadu 19th September, 2003).

 

ASISE-IBOJI lati ile-USA-Mirza AbuBakr Salahuddin pinya pelu Ahmadiyyat, o si gba Bahaism.

 

Ijo Ahmadiyyat ko tii bo ninu rotiroti iyapa Shaikh Raheel Ahmad, nigba ti okan lara awon giwa Ahmadi, ti o je alawo-dudu nile America Mirza AbuBakr Sallahuddin fi Ahmadiyya sile ti o si faramo Bahaism. O ti gbe igbese yi lati osu keje odun 2003, sugbon ko fii to enikeni leti nitori pe Jamaat wa ogbon lati pee pada si agbo won.

 

Odun ketadinlogbon (27years) niyi ti o ti fi ile-America se ibugbe. Okan lara igi leyin ogba ni o je fun Ahmadiyya ni America ati Qadiani ti o n si n sise ninu ile-ero agbohunsafefe ayara – bi-asa.

 

O si je alaga agbohun – safefe Qadiani pelu iwe meta otooto ti o ti ko sile. Oun kan naa ni o n se agbateru fun eto iwaasun Ahmadiyyat lori ero agbohunsafefe o si ti rowo mu riibe. Opo iwe ni a ti ko lati owo ogbeni AbuBakr fun iranlowo ihinrere Ahmadiyyat, ti o si je gbaju-gbaja laarin awon Ahmadi latari ero agbohun-safefef re, “IBOJI JESU” nibi ti o ti ri oruko BAALE IBOJI. Nidi ise re yii, o ni idaniloju lori awon iwe re pe Jesu (Isa omo ibrie Maryam AS) ku, a si sin in si Kashmir. Lakoko o fe ki ero igbohun-safefe re yii maa lo siwaju, nigba ti o fara pamo sabe agboorun Jamaat Ahmadiyya sugbon laipe o han kedere pe alagidi Ahmadi ni se. O sise ni ibamu pelu khalifa kerin, Mirza Tahir Ahmad eni ti a gboriyin fun ti o si ti so asotele ojo-wiwaju rere fun-un. Sugbon ose! Mirza Tahir kuna.

 

Gege bi a se gbo, o ti menu ba a ninu ifiwesile re pe oun ko ni igbagbo ninu Qadiani mo ati pe oun ti gba Bahaism gege bi olugbala, nitori naa oun fiwesile, oun ko gbogbo aigbagbo ati ise Qadiani sile pata porongodo.

 

O tesiwaju ninu iwe re pe ko si ohun to kan ni mo nipa boya Jesu ku tabi won kan-an mo ori-agbelebu bi ko se pe ohun to je mi logun nisinsinyi ni Bahai esin ona otito. Gege bi a ti gbo, pe o tun tesiwaju pe ko si ohun to kan oun nipa esin Islam ati pe ko da oun loju pe ooto ni igbagbo awon musulumi. (ma’az Allah).

(Adily Ummat, karadi, 3 September, 2003)

 

Nibi mo fe fa akiyesi eyin onkawe si pe ogbeni Abu Bakr yii gba Ahmadiyyat lerongba pe Islam ni. Nigba ti ko ri itelorun-okan loi o ti lero ko fi Ahmadiyyat sile nikan, o tun bu enu-ate lu Islam. Ti o ba je looto lo n wa otito, ni agbara Olohun, Olohun (Allah) yoo too sona Islam otito lojo kan. (Amin)

 

IKU/PIPA PANDIT LEKHRAM

Iroyin tesiwaju lati inu Al-Fatwa tateyin wa).

 

Eyin onkawe wa! Ninu iwe atejade Al-Fatwa Agbaaye ti onipele kokandinlogbon a se afihan awon iroyin pelu eri to daju ti ‘Jamaat fi akole akomona han “Feran gbogbo eniyan, ki a si ma korira eniken.” Bawo ni won se wa n huwa si alatako won. Ninu atejade yii a se apejuwe bi Mirza Ghulam Ahmad Qadiani se n huwa si awon alatako re. Iroyin yi farape ti Lekhram ninu Al-fatwa ateyinwa.

 

Mirza Ghulam Ahmad ti bere irinajo esin gege bi erusin ati soro-soro Islam. Lati ibere pepe, ti o ti bere si tako Hindu Arya samaj ninu awon oro re nigba ti o wa n Lahore.

 

Leyin to pada si Qadiani, nipa ipolowo, lore-koore lo maa n pewon nija. Ko se eleyii lati polongo esin Islam biko se ki o le loruko ki o si gbajumo. Gbogbo awon ipolowo wonyi wa lara awon akojopo ti Jamaat te jade ni olu-ile-ise won ni London.

 

Braheen-e-Ahmadiyya kede pe Ayanfe

 

Ni odun 1880, Mirza Ghulam je ki o di mimo fun gbogbo eniyan pe Olohun lo yan oun lati kowe Braheen-e-Ahhmadiyya ni aadota ipele lati ridi otito Islam. Nigba kan naa lo n pe awon ti kii se Musulumi ki won ko ohun ti won mo nipa iwe naa.

 

Laije pe won da esin Islam sile fun ija-esin, Mirza Ghilam maa n soro pelu ibinu nigba ti o ba n ba awon keferi wi ninu iwe yii. Latari eyi, o so oju abe niko ti o fi je pe awon onigbagbo (Christian) tabi Hindu maa n ko ara won nijanu nigba ti won ba n ka iwe yii. Eleyi gbin eso ibinu ati ikorira sokan awon kiristieni (Christian) ati Hindu si esin Islam ati awon Musulumi ti o wa laarin won. A ipawo eyi lara Pandit Lekhram, nigba ti o pee ni no nitori Takzeeb Braheen-e-Ahmadiyya. Eyi ko jamo nkankan biko se akojopo oro-ibaje ati isodi aimo lo. O si kun fun itabuku ati idunran mo eniyan lona aito si awon olooto ati eniyan mimo, paapaa isorin egan si awon ojise Olorun (Allah).

 

Lekhram fi eyi han nipa iwa-ika inu re. Idi opin je jade nigba ti Braheen-e-Ahmadiyya soro odi si awon ojise mimo Muhammad SAAW ti Mirza Ghulam Ahmad si jiya ese re lakori ise owo re.

 

Dipo ki won kowe to loye lori esun aito ti won fi kan Lekhram, se ni Mirza Ghulam bere si kede ise iyanu. Mo so pe ninu atejade Al-Fatwa opo igba ni Lekhram di Mirza Ghulam lowo lati sise iyanu to n so kiri.

 

Dajudaju, sise ise iyanu ko tii koja agbara Mirza Ghulam eletan eniyan. Lakoko o gbiyanju lati pa Lekhram lenu no nipa fifya jee, sugbon nigba ti o rii wipe Lehkram ko bikita fun gbogbo alumo-koroyi oun ni odun 1886 o ko iwe kan ti o pe akole re ni “Surma Ghashme Arya ninu eyi ti o pe Hindu Arya Samaj (nibi ti Lekhram ti je okan lara awon olori) fun adura (Mubaila) sinsin lodun naa.

 

Nigba naa won yoo duro fun idajo Olohun fun odun kan gbako.leyin ti odun kan ba koja ti onkowe yi ko ba ri ijiya ki o si joro tabi ko sokale so alatako, oun fun ra re (Mirza) yoo sanwo itanran ti oye re je RS 500//=”

 

Leekan si Mirza Ghulam pe Hindu Arya Samaj nija wipe ko si enikeni to le fesi si iwe oun.

 

Iwe ti a pe ni Surma Ghashme Arya yii, nigba ti a n foro jomi-toro oro pelu Lala Murlidhar, Drawing Master, Hoshiarphr eyi to tu asiri igbagbo eke Ved, nipa eyi ti a rii pelu idaniloju pe ko si Arya kankan ti o le ko nipa igbesubu iwe yii.

 

Pelu gbogbo kulekule Mirza Ghulam, Hindu Arya fesi.

“tesiwaju sii iwe ilewo ti akole re je “Surma Chashme Arya Kee Haqeeqat Anr fun Feraib Ghulam Ahmad (OtitoSurma Chashime Arye ati Eko Etan mi).

 

Leyin ti o te iwe pe fun Mubahila, Pandit Lekhram jade lojkoroju wa pade Mirza Ghulam. No odun 1888 ipenija Muhahila je itewogba; O tewe Muhahila-nama gege bi adehun pe ni odun 1889 pe Lekhram yoo ti kagbako ijiya nla sugbon ti ohunkohun ko sele, awon mejeeji paroro. Leyin ni Mirza Ghulam bere si pariwo ise iyanu kiri. O tun kuna nibi bakan naa..

 

Janab Mirza Saheb. Namaste,…idi wiwa mi lati Pashawar si Qadan niyii, bayi mo wa nibi ni ireti mo fe jeri si ise iyanu re, isele meriyiri, awon agbara ati awon ami orun ati pe ki a to le jiroro lori awon ipilese eko miran, a gbodo yanju oro yii pelu awon eniyan ti a kasi, …nibi o ye ki a ranti pe jijoko maa fidi ododo mule niwaju awon olufokan sin yato, sugbon ijerisi laarin awon ologbon ati oloye eniyan yato. Mo si ni ireti pe e o buyi fun mi nipa fifesi. Ma se se awawikankan, bakan naa mo n ro yi wipe ti iwo ba ni idi otito kan, fi han mi (ami orun) bi bee ko, mo bee o nitori Olohun, Jawo (lati maa pe ara re ni ohun ti o ko je)… lati owo: Lekhram. (leta Lekhram si Mirza Ghulam, Roohani Khazain vol. 12 p. 113).

 

Sugbon Mirza Ghulam ko le fi agbara kankan han. Bee ni Lekhram si n tesiwaju ninu iwe kiko re sii.

 

Nigbeyin, gbogbo leta ti won ti n ko, lati odun (1885-1893) won fohun sokan eyi ti Mirza Ghulam gbe jade ninu iwe re.

 

Adehun eyi ti emi ati Lekhram fenu ko lori akiyesi “Ami” ati oro-iwe re ti Lekhram fi owo ara re ko, niyii…akotan adehun yi ni pe ti a ba so asotele kan fun Lekhram ti o si je pe o jasi iro ti a si gbaa gege bi eri otito ti esin Hindu yoo je ohun to pon dandan fun eni ti o so asotele (Mirza Ghulam) ki o gba esin Arya tabi ki o san owo itanran RS 360/= fun Lekhram, eyi ti awon gbodo san si ile – itaja ogbeni Shram pa ti o je Olugbe Qadian. Ti o ba je pe otito ni alasotele n wi a o gbaa bi eri. Otito ti Islam, je pe o pon dandan fun Lekhram lati gba esin Islam. (Istafta, Roohani Khazain, vol. 12p. 117).

 

O han kedere bi oju-ojo ninu oro yii pe nigbakugba ti a ba fe kede asotele, nigba imuse pe Lekhram yoo wa laaye, yoo ri amuse asotele, o si je dandan fun-un pe ki o gba esin Islam leyin akiyesi re, sugbon laisi laaye re, ko si awuyewuye pe a n je eleri ohun abami ati agbara Mirza Ghulam, tabi yoo le so ni gbangba nipa igbagbo Islam ti o ba je pe o ti ku nigba ti asotele naa yoo ti wa si imuse.

 

Labe adehun yii, Mirza Ghulam kede awon asotele wonyii.

 

Asotele ljiya atorunwa

Nisinsinyi pelu atejade asotele yii mo fe ki o han si gbogbo musulmi patapata ati awon Arya (Hindus) ati awon onigbagbo (Christians) pelu awon elesin miiran wipe laarin odun Mefa lati oni ti o je ogunjo osu keji odun 1893 (February 20th, 1893), iru ijiya ti o tun ga ju iponju ni khaariqz-Aaadat (ti a ko le fenu so tabi ki o ju oye eda lo.. Rashid) (se ki se okan lara awon aisan ati iponju ti o je adamo ati alaileru ti o je pe nigba niiran eniyan yoo ye tabi ki o parun) pelu iberu Olohun, (eyi ti o fi ibinu Olohun han) Igi sokale sori eniyan, o ye ki o ye yin yekeyeke emi ko wa lati odo Olohun tabi mo ni ajosepo pelu emi Olohun. (iyen ni pe a gbe asotele yi lori iro tabi otito)” (Roohani Khazain vol: 12p. 118).

 

Ninu abala miran Mirza Ghulam tun so ninu iwe yii kannaa,

“Bayi mo tun n jewo pe,… ti o ba ni arun iba tabi irara tabi ki o tile je aisan onigba-meji ti ara re si mokun to ni gbaa bi asotele ati pe laisi aniani ogbon alumo koroyi ati etan ni yooo je.” (Roohan Khazain vol. 12 p. 17)

 

Oni ojo-isegun, ogunjo osu keji, odun 1893nigba ti mo wonu emi lati se awari ijiya atorunwa yii, Olohun fihan mi pe lati oni di odun mefa eni yii yoo kagbako iponju pelu ijiya nla nitori ahon re, gege bi ijiya fun pipegan ojise mimo SAAW iponju nla yoo de baa. Bayi pelu atejade asotele yii mo fe ki o han gbangba si gbogbo Musulmi, Aryas (Hindu), kiristeni ati gbogbo elesin yoku pata pe ti ijanba ko ba sele sii laarin odun mefa sibi ti a wa yii (eyi ti o je khariq-e-Aadaat (ti o lodi si adamo tabi ti o koja oye eda lo… Rashid) ti ko ni eruOlorun, eri pe n ko wa lati odo Olorun, beeni, n ko ni ohunkohun se pelu re. Sugbon ti o ba si je, pe iro ni mo fi asotele yii pa mo setan fun ijiya-kijiya ti o ba wa sori mi, mo si setan lati

pokunso. Pelu gbigba mi, o han gbangba, pe ohun itiju ati abuku ni fun eni ti o ba so asotele eke. (Roohani khazain vol. 12 p. 15).

 

Khaariz-e- Aaadat-Lodi si Adamo, tabi adamodi.

 

O ye ki a kiyesi gege bi oro Mirza Ghulam, iru ijiya yen ye ki o je khariq-e-Aadat. Ki ni ohun ti Mirza Ghulam mo nipa oro yii? E je kii a woo: “ Ohun ti ko lafiwe, eyi gan –an ni a n pe ni Khaariq-e- Aaadat”

“ Laye yii ohun ti ko ni ijora ni Khaariq-e- Aaadat. (Haqeeqil Wahi, Roohani Khazain Vol. 22p. 204).

 

Lakotan:

                Awon ayolo oro wonyi ni a le la kale lati inu iwe Mirza Ghulam:

1.             Odo Olohun ni asotele nipa Lekhram ti, o si peju odun mefa.

 

2.             Ijiya re yoo si dabi khaariq-e-Aaadat ni pa eyi ti ko si iru re.

 

3.             O se pataki fun Lekhram ko wa laaye titi asotele yoo fi wa si muse.

 

4.             Ti asotele naa ko ba si se, a je pe Mirza Ghulam Ahmad Qadiani di OPURO funfun balau, ijiya si to sii sege bi ero re, yio po kunso

 

5.             Ti asotele yii ko ba se bakan naa yala ki mirza Ghulam gbesin Arye Hindu tabi ki o san owo itanran RS. 360 fun Lekhram.

 

Gege bi asotele yii, laarin odun mefa iyen ni pe lati ogunjo osu keji odun 1899, o ye ki ijiya ti ko ni afiwe lode aye yi, eyi ti a da pelu iberu Olohun lokan sori, nipa bayi Mirza Ghulam iba ti roo, ki oun naa si gba lati gba esin Islam. Sugbon iru nnkan bee ko sele. Dipo bee won tan-an pa.

 

Afihan eri ti o daju

Ni ipaniya ti won ti ro tele, o soro lati ri idi okodoro nipa apaniyan ati awon to roo tabi gbimo re. Nitori naa awon Oluwadii gbekele eri to daju lati gbe ejo won le. Ninu iwadii esun ipaniyan aye  se pataki. E je ki a wo ohun to sele niya iku Lekhram ati eri to daju ti a ni.

 

Leyin ti Mirza Ghulam te asotele re jade gege bi ise re, o ti kede amuse asotele naa bi bee ko, o ti mo daju pe iranlowo olohun jinna si oun. Olohun nikan lo rinu, eri idaniloju naa wa nibi, eyi ti o je ki a mo ohun ti Mirza Ghulam n gbero.

 

Lekhram je odomokunrin ti o lomi lara ti ojo ori ‘re’ ko ju ogbon odun lo. Oun (Mirza Ghulam) kan le die ni aadota odun ni pelu aisan to ti di baraku sii lara. Oniruuru iponju lo si pago tii pelu oke aimoye arun. Bi o tile je pe, eri ni yoo je fun wa ati mo ohun ti o wa lowo eniyan tabi lowo Olohun. (Siraji-e-Muneer, Roohani Khazain vol. 12 p.17.

 

Mirza Ghulam gbe asotele miiran jade leyin igba die,

“Loni ti o je ojo kejila osu kerin odun 1893/14 Ramadhan 1310AH, nigba ti mo n toogbe ni owuro, mo ba ara mi ninu ile nla kan ati awon ore mi kan si wa pelu mi, logan mo ri oburewa okunrin ki ti o bani leru ti o si dabi eni pe eje n jade ni iwaju re wa o si duro ni iwaju mi. mo woke, mo si woye pe, mo ri eda titun ti kii se eniyan, sugbon ti o je okan lara awon angeli tabi moleka iparun ti eru re si muni lokan. Bi mo ti n woo o beere lowo mi wipe ibo ni Lekhram wa, o si tun daruko elomiran pe ibo ni oun naa wa. Logan lo ye mi pe eni yii ni a ti yan lati je Lekhram pelu elomiiran niya sugbon n ko lee ranti eni ti enikeji n se, bee ni eyi dami loju pe awon ti mo ti kede tele. Ojo Monday ni eyi ni deede agogo merin idaji.

 

“Wa basharnee abbi mubasherin sa tarefo yaum al-eid wa aleid aqnab… itumo… ihinrere-ayo Olohun ni a fi fun mi wip laipe iwo yoo da ojo Eid mo… Olohun seleri o si dahun adura mi lori alagidi ati ota Olorun ati Rasool, ti o je Lekhram Pandit, o si so fun mi pe dandan ni ki o ku.

 

 

Subttan Allah!! Olorun Mirza Ghulam ko ha buyi fun adehun laarin ojise re ati alatako re; amo saa adehun ati isotele ni amo saa adehun ati isotele ni je awon orisa ni o fi won han ojise re!!!

WON GUN LEKHRAM LOBE PA; SE OJULASAN NI?

Lojo kefa osu keta, odun 1897 won pa Lekhram nipa gigun lobe nikun. Ahmadiy Qadiani Murabbis ati awon oniwaasu so pe moleka lo pa Lekhram ati wipe asotele onigbala naa ti wa si imuse.

 

Eyin onkawee mi, e ka asotele Mirza Ghulam Ahmad ati adehun laarin oun ati Lekhram finni-finni gege a ti koo saaju ninu iwe yii.

Nje apeere wa wipe won yoo pa Lekhram? Ohun ti asotele n fihan ni agbara tabi ami to ju oye eda lo, iyanu ti ko lafiwe ati ami orun kii se nipa iku Lekhram. Nje iku Lekhram je atubotan isele oju lasan? Isele ti o wopo ni ki a gun eniyan lobe pa. A le ba apaniyan lowe nipa sisan owo oya/ise re fun-un. Nitori naa ki ni ohun ti o koja oye eniyan ninu ipaniyan yii? Ati wipe o ti wa ni akosile Mirza Ghulam ti o ti so pe.

 

“Ohun ti ko lafiwe, lona miran ewe a le pee ni khaariq-e- Aaadat.

 

Khaariz-e-Aaadat ni a ka si ohun ti ko ni ijora / afiwe lode aye yii.

 

Ohun to sele I wipe okunrin alagabagebe kan n dibon gege bi olufokansin kan wo aarin awon akekoo Lekhram o si n wa aiye, logan to ri pe Lekhram nikan da wa lo gun un pa ti o si na papa bora.

Iroyin wonyi ni a ri ninu iwe laka atigba-de-igba Ahmadiyyat lati karachi “ohun irahti”.

 

Ni ojo satide tii se ojo kefa, osu keta odun 1897 ni a sapejuwe pe pandit Lekhram wa ni ilaji ihoho ti o n gbadura sindhiya (bi o se n josin) ni yara oke. Leyin ti o josin tan, o fara lele nitori ikun re ti o tobi. Musulim ti o gba shudh (fari o si di Hindu) n joko nitori pelu aso to da bora. O gun Lekhram lobe nikun ti o fi je pe gbogbo ifun re tu sita.

 

Ohun ti Mirza Ghulam so nipa isele yii niyii. Ise owo awi ni a ti ri kedere ninu oro Lekhram. Wiwa eniyan sodo re pe ki o gba shudh, ti o si fokan tan eni naa debi pe o mu u wonu iyewu re, ti o pinya pelu awon alejo re lale, awon mejeeji lo ku sile, lojo keji Eid ni o si fe se ise yii, lojiji ti Lekhram dide nibi ti o ti n ko n kan ti o si na ara ati ikun re siwaju, obe oloju meji naa sise ijamba, titi di akoko iku re Olohun dee ni ahon ti o fi je wipe pelu gbogbo ogbon ati imo ti mo ti sotele fun un ko figba kan funra pe mo funra si Mirza Saheb, titi di oni owo ko te apaniyan naa gbogbo iwonyi ni ise Olohun eyi ti o n fi titobi ati agbara re han.

 

Awon onkawe ni lati ka awon akosile yii finnifinni. Bi Mirza Ghulam se gbe isele igba ikehin Lekhram, bi o ti le je pe o je ohun itiju, sibe a ri awon ibeere pataki, BAWO NI MIRZA GHULAM SE MO NIPA RE? BAWO si ni MIRZA GHULAM SE MO PE LOJIJI NI LEKHRAM DIDE NIBI TI O TI N KOWE. TI O NA ARA RE TI IKUN RE SI YO SITA ATI IGBA TI WON GUN-UN LOBE NIKUN? Eniyan meji pere lo mo nipa re; eni ti o paniyan ati eni ti won pa. Beeni Olohun (Allah) si mo nipa re bakan naa. Sugbon Mirza Ghulam ko figba kan so o ninu iwe re pe Olohun fi isele naa han ohn. Lekhram ko si laye mo lati wa so pato ohun to sel.

 

Eni ti o le so fun Mirza Ghulam ni okan ni apaniyan funrare.

 

Nje Ahmadi / Qadiani kankan le so fun wa irufe ibasepo to wa laarin Miza Ghulam ati apaniyan ti o mu iroyin wa si etigbo re? Ati wipe ki lo fa ti Mirza Ghulam ko le fi irufe eni onitohun sowo si awon olopaa? Ti apaniyan naa ko ba si lara awon omoleyin re, nigba naa n je o seese wipe agbanipa ni?

Nibi, oro mirza Ghulam miran tun fanimora:

 

Asotele onise eke ko lee wa si imuse laelae, Olohun dide sii ki iran eniyan ma ba dibaje gege bi Lekhran se fi ogbon arekereke aye polongo mi wipe emi yoo ku larin odun meta, ki ni se ti oun tikarare ko lee padi apo po mo apaniyan ki asotele ma baa se?

 

Oro yii fi han gbangba pe Mirza Ghulam mo bi o se le ri apaniyan lati pa enikeni.

Iwe iranti atigbadegba Ahmadiyya ko bayii pe:

Awon eniyan so wipe (iyawo ati iya Lekhram) so pe won ri apaniyan naa ti o sokale bo lati ategun Mirza Bashir Ahmad omo Mirza Ghulam ko bayii,

Gege bi oro iyawo Lekham ati bee bee lo, a gbo pe leyin ti o pa Lekham tan o gun oke o si wo inu aja ile lo.

 

Ibeere niyi: Ti o ba je pe moleka / angeeli lo pa Lekham bi Ahmadi se fe ki a gbagbo, ki lo de to fi dara po mo awon olusin ti o si wa aye lati pa Lekham, abi lehin ti o ti paa tan, ki ni idi ti o fi sokale ti o si tun goke pada? To ba tile je pe o wa  gege bi aferi, iba ti pora mo inu yara nibe ambosi-bosi pe enikeni yo gan-an ni re . Tabi angeli / moleka le paniyan lairi niwaju gbogbo awon to n josin – awowi gbaa ni eyi

Eri to daju niwonyi, ti o si da awon olopaa agbegbe loju pe ote didi ati rikisi niyi eyi ti o je pe Mirza Ghulam lowo ninu re. Odindi igba meji gbako ni wonde ilee re, sugbon oun paapaa kii se ope.

Awon eniyan wonyi mo lokan ara won pe ise Olohun niyi ati pe kii se idimo eni to so asotele, sibe o tun pe ijoba ki won wa ye ile oun wo nipa idasile irokeke mimuse ijosin pelu awon to n bo maluu.

Lati ago olopaa won be ile re wo lojo kejo osu kerin odun 1897.

Owo ko te apaniyan naa, Bee ni ijoba oyinbo (British Government) ko ri ohunkohun se sii bikose yiye ile re wo lasan, pelu gbogbo atenumo awon Hindu. Won fenuko lati fedo lori ororoo fun ipinnu nla.

Awawi asan miran fun ise iyanu ti ko sele. Kin ni ere oku-opuro ju wipe ki orun fi ami han an ki aye si woran re?

 

Mirza Ghulam ko oro etan tikarare.

A gba itoni emi ati iru omoleyin, ti o buru ju aja ati igbe aye aimo awon maa so asotele nile, ati wipe pelu owo ara won ati pelu ogbon alumo-koroyi ati etan won gbiyanju pe won mu ti ara elomiran se

 

Ipe si yiyan Khalifa tuntun ti Jamaat Ahmadiyya, Mirza Masroor Ahmad.

A fi towotowo pe Khalifa karun –un Mirza Masroor Ahmadi Qadina, yala ki o wa siwaju tabi ki o se Mubahila pelu wa lori oro Lekhram bi bee ko yoo bura ( pelu ijiya latorun ti o ba bura eke ) pe Mirza Ghulam Ahmadi Qadiani ko lowo ninu iku Lekhram nitori iku re ko wa latodo eniyan kankan bikose lodo angeli / moleka, nipari wipe asotele Mirza Ghulam Ahmad Qadiani lo se.

 

Ibewo Ahmadi atijo, Ahteshamul Hag Abdulbari si Belgium laipe.

Olori awon Asodi si Ahmadiyya / Qadiani ni Mumbai India, be Belgium wo ni osu kejila odun 2003. Ni akoko ibewo yii won ri eni ti o sese gba Islam,  eni ti o ti wa ninu igbekun latowo ijo ( jamaat) Ahmadiyya. Alhamdolillah nigba ti arakunrin Ahtesham salaye fun-un iru iwa Ahmadiyya n hugan-an o fi ijo naa sile leyin naa won pe e wa si gbongan ijo ni Anti –wep lati jiroro lori agbegbe Muballighs. Agbegbe Murabbi Nasir Ahmad Sindh soro nipa anfani awe gbigba lede oyinbo  / geesi.

 

Ni opin oro re, niwaju gbogbo eniyan Atesham gbiyanju lati beere awon ibeere kan lori Mirza Ghulam Ahmad Qadiana, oludasile ijo itesiwaju Ahmadiyya, sugbon won daa duro, sugbon lehin eleyii, o ni anfani lati soro ni apejopo awon Ahmadi nipa awon oro Mirza Ghulam.Murabbi Nasir Ahmad Sindh soro fun awon Ahmadi yooku. Lara awon ti o pese nibe ni ogbeni Hashmi, Malik Naeem, Khalid Iqbal, Hafeezbutt saheb, Chaudhary Mansoor Ahmad siakoti ati awon yoku. Ni wa ju won  Mubahila mu aye laarinAhtshan ati awon Ahmadi otito ati iro, won si so ni gbangba pe ki egun Olohun (Allah) wa sori awon opuro / oniro ni sido pe Laanatallah ala al kazibben

Arakunrin Ahtesham ro ogbeni murabbi ki o ba oun wa gbo iwe ti mirza Ghulam Ahmad ko pe oun yoo san saheb pinnu lati baa wa won sugbon o yi ipinnu re pada. Ni akoko isoro yi murabbi saheb ati ch. Mansoor se?

 

Ahmad Sialkoti binu repete won si bere si bura fun elesin Islam tuntun yii, won tile gbiyanju ati naa. Arakunrin Ahtesham ran won leti pe biba ara wa ja kii se ona ti a le fi waasu esin Islam. O si so fun won pe ti won ba de mosalasi awon musulumi iniruuru iwa ni won yoo ri.

 

Ki Olorun fun awon omoleyin Ahmadiyya won ni isiju lati mo otito yato si iro ati hidayah lati ri ona ti o to. Amin.

 

Wa maa alaina ila- albalaagh.

Wassalam ala mum- ittaba’a al-huda.

Dokita Syed Rashid Ali.


» تاريخ النشر: 26-11-2009
» تاريخ الحفظ:
» شبكة ضد الإلحاد Anti Atheism
.:: http://www.anti-el7ad.com/site ::.