« Fatwa 29 »






AL-FATWA INTERNATIONAL N° 29 

ABERE NI ORUKO OLORUN OBA AJOKE AIYE ASAKE ORUN

IFOROMITORO ORO AGBEYE ELEKEKANDILIGBON

ITUMO RE LATI EDE FRANÇAIS LOSI YORUBA

-----------------**-----------------

            Eyin olukawe wa eni aponle

            Assalaamu alaykum wa Rahmantu LLahi wa Barakatuhu.

            Eleyi ni onka tuntun Al-Fatwa.

            Asaaju (Imam) Jamaat Ahmadiyya, Mirza Tahir ti Qadian ti ku.

            Eniti nperare ni Imam ati khalifath ijo Ahmadiyya, Mirza Tahir Ahmad Qadian ti ku ni 19 Avril 2003. Gbogbo enikookan wa ni yio pada ku ni ojo ojo kan, sugbon biku ba npa ojugba eni a ma koni logbon.

            Ni 1988, Mirza Tahir Ahmad pe ipe igbera eni sepe (imuje) niwaju Olohun lati mo eniti nbe lori ododo laarin, osun asaaju Jamaa Ahmadiyya ati awon musulumi ododo ti agbaiye (Mubahila).

            Mubahila ni sababi iparun Mirza Tahir Ahmad enito kirare senu panpe Olohun ti kole bo kuro ninu re titi ti o fi jepe iku.

            Awon olumo ijinle nipa esin Islam ni agbaiye parapo pe Mirza Tahir Ahmad ni opolopo igba lehin ipe kansoso ti oun peni 1988 ; sugbon Mirza Tahir ko laya latile dawun ipe nwon nitoripe oun gangan mo wipe bina ba njo ni papa abawu toba bekeke sina a fi emi arare sofo ni.

            Opolopo ninu awon olumo ijinle nipa esin Islam, gegebi Syeed Abdul-Hafeez Shah lati foju koju fun Mubahila yi gegebi sunna Anabi-Muhammad (SAW) sugbon o ma se o ti Mirza Tahir Ahmad sa, ko laya lati foju koju fun Mubahila yi mo.

            Syeed Abdul Hafeez Shah, asaaju ati oludasile ijo alatako Jamaa Ahmadiyya so wipe oun pe Mirza Tahir Ahmad ni odun 1994, 1995, 1997, 1998 ati ni odun 2000 si Mubahila sugbon o dake bi oyaya ko fesi.

            Ni odoodun lati odun 1989 Maulana Manzoor Ahmed Chinoti nlo si ilu London latilo ri-i fun Mubahila, sugbon igida Mirza Tahir olori onibaje palolo, alasise ko fohun.

            Oto ki a ranrawa leti wipe baba Mirza Tahir Ahmad, ogbeni Mirza Basheer Uddin Mahmud ti oje khalifa keji je olori ibaje, olori sina, onifekufe, oluba okunrin egbe re sun gegebi awon ijo LUT.

            Alaïnitiju ti ko ko omo bibi re lobirin lati basun ati gbogbo awon obirin ti olohun se leewo.

            Igida ! Mirza Tahir Ahmad ha rare mo Gressenhall, ibugbe re. Ogbologbo Ahmadi, Ahtesham-ul-Hag Abdul Bari eniti-o di ogbontarigi ninu ijo alatako fun Jamaa Ahmadiyya ti Mumbai oun naa pee fun Mubahila ni opolopo igba. Paapa ni odun 1995, o losi ibupe nwon latile foju koju pelu Mirza Tahir Ahmad, sugbon o sa ko jepe.

            Towun-tibe, Mirza pada sise nipa ijewo wipe ki ogbeni Mr Mohammed to je asoju re nilu Karachi (Pakistan) pelu olumo ijinle nipa Islam, ogbeni Ilyas Suttar ti ilu Karachi bakanaa faya kaya Jomitoro–oro nilu karachi ni 3 Juin 1999 eyi lori ipe ti Mirza Tahir Ahmad ti pe lati odun 1988. Nibujoko foro Jomitoro-oro yi, eleri meta-meta gbodo wa fun ikini keji nwon lasikonaa. Ni 30 Juillet 1999, niwaju gbogbo awon asoju Jamaa Ahmadiyya tilu kookan ni gbogbo awon orilede agbaiye eyiti onka nwon nje 18500 ti nwon pejo silu LONDON fun ipade odoodun ti awon Ahmadiyya ma nse, ibe ni ogbeni Mirza Tahir Ahmad ti tewo gba igbera eni sepe ti osele laarin olumo ijinle nipa esin Islam ogbeni Ilyas Suttar ati Mr Mohammed ti-i se asoju re nilu Karachi (Pakistan) leniti nso bayi wipe : « Titi iwoyi odun ti nbowa ibawi ati ibinu Olohun yio sokale sori opuro » ko pe ti ibinu Olohun bere si-i rojo le opuro lori Ni 20 Août 1999 nigbati Mirza Tahir Ahmad nse khutubath ni ojo Jimaa nilu Norvège, Mirza ferareku, aagana aïpe ori kolu-u lojiji. Nwon sare gbee losile iwosan oyimbo nilu LONDON ibiti nwon ti toju re fun osun kan. Ni 10 Septembre 1999, ose waasu iseju mewa, laarin re loti jewo wipe aarun opolo (were) nda oun laamu, eyini sababi isoro ti oun ni lati salaye oro ati lati fesi oro, oun naa ni okunfa ti oun ki-i fi wa je ipe lopolopo igba. Ko le sadura ojo yen dele, ogbeni Ataul-Mujeed Rashed lo ropo re lojo yen. Lehin igbadie ni okiki nkan ka kiri wipe isokuso re ti npoju ninu Khutubath ojo Jimaa, nigbamiran ewe, a ma kirun jJmaa ni Rakaath kansoso, a salamo. Ibawi Olohun yi safihan wipe opuro ni Mirza Tahir ati Mirza Ghulam Ahmad Qodiani. Ilyas Suttar nbe laiye pelu alekun ibukun ati alafia Olohun lasiko yen. Jamaa Ahmadiyya dake roro lori awon isele to nsele le hin Mubahila yi. Gbogbo awon mutumuwa nbirawon leere wipe : « Ta-a wani olododo laarin awon mejeji ? » Sugbon Mirza ko teru to le fesi titi ti o fi ku.

            Iwa jibiti, ogbon ewe nla miran ti Mirza Tahir Ahmad fi nda awon mutumuwa lopolo ru niro pipa nipa onka awon eniyan to ndara pomowon ninu Jamaa Ahmadiyya lati 1993, Mirza Tahir Ahmad nso bayi wipe : « ni odoodun ni onka awon eniyan ti ndarapmo Jamaa Ahmadiyya ndi ilopo meji. Gegebi oro re, to badi odun 2000 onka awon eniyan to darapo mowon gbodo ma je 20.000.000. Iro nla ti gbogbo awon omo ijo re ko gbagbo, eyi ni sababi ti omowe, ojogbon Munawwar Malik eniti a bi sinu Ahmadiyya nilu Jhelum lorilede Pakistan fi kuro ninu Ahmadiyya bo sinu esin Islam (ope ni f’Olohun). Omowe Munawwar Malik te atejade kan ti nwon polongo re sinu iwe iroyin osoosu Laulaak ti Multan ninu re loti siso lori iro ti nwon pa nipa onka yi. Akosile yi nbe ninu site lori adresse : http://www.alhafeez.org/rashid/figures.htm

            Isoro miran ti Mirza Tahir tun ba pade ni osu melo kan siwaju, owun niti ehin igbati Jamaa Ahmadiyya yo oguna gbongbo kan ti-i dato lenu igbin, omowe Hadi Ali Chaudhary eniti nwon fi esun kan wipe o ngbowo agbatele o si npawo ijo mole Hadi Ali Chaudhary kowe ti akole re nje : « Awon omolehin Satani » lori ilana ati abe ase Mirza Tahir eyito fi ngbogun ti awon alatako Jamaa Ahmadiyya. Mirza doju oro ati ija komi ati Syeed Abdul Hafeez lehin yiyo to yomi kuro ninu Jamaa Ahmadiyya.

            Hadi Ali Chaudhary bere si tunasiri ti Mirza Tahir Ahmad ati awon agba iranse Ahmadiyya ngba fi kowoje. O siso lori awon ona ti nwon ngba fi ko awon owo nlala ati awon ebun ati owo itore ti awon omolehin ijo Ahmadiyya nda.

            Sibe sibe, iponju, inira ati itiyu ti Mirza Tahir ri lehin Mubahila to sele laarin oun ati Ilyas Suttar ati Ahtesham-ul-Haq ati Maulana Manzoor Chinoti ati awon ijo alatako Jamaa Ahmadiyya ninu Islam ki-i se nkan to pamo si enikeni. Lotito nipe tibi tire ni awaiye, iponju ati aare ati inira je awon ohun ti Olohun fi daiye. Kosi eniti-i ko ipe iku to bade. Sugbon ti ikan ninu awon isele yi ba yo si enikan lehin Mubahila, ami pataki lo je. Mirza Tahir Ahmad gan funrare lo so bayi ninu akosilere pe : « Ki opuro laarin awon mejeji ku fi olotito s’aiye ». Ninu (Malfoozat, Roohani Khazain II vol-9 p. 440).

            Ogbeni Ilyas Suttar, Ahtesham-ul-Haq, Maulana Manzoor Chinoti Syeed Adbul Hafeez Shah ati emi na wa ni alafia ninu ibukun ati idera ati ogo Olohun negbati Mirza Tahir Ahmad Qadiani, arole kerin ti ku ni 19 Avril 2003, eyi yio ma je ohun arikogbon fun gbogbo mutumuwa, arawaju to jin si koto, nse loko ero to ku logbon. O semi laanu pupo fun-un ! Ti ko fura se laakaye ronu si we igbehin ti Ahtesham-ul-Haq ko si-i eyito fi npe si ironu piwada gba esin Islam mu lati fi ri iyonu Olohun siwaju ko to ku. Ebe wa ni ki Olohun pa Mirza Tahir po mo baba re (Mirza Mahmud) ati baba baba re (Mirza Ghulam Ahmad) se ijo nwon lokan. Amin.

_______________________________________________________________

Iwe ti nwon fi ranse si Arole Kaarun to sese joye.

Eni aponle wa Mirza Masroor Ahmad Qadiani Saheb.

Ike Olohun ati alafia re ko maa be pelu awon eniti ntele ona to to.

            A bayin yo fun ewe oye te ja latije asaaju Jamaa Ahmadiyya Mori-i ka ninu iwe iroyin ojoojumo « Khabrain » wipe e kilo fun awon amolehin ijo yin ati awon iranse Qadiani ki nwon o ma tun foro Jomitoro-oro atipe ki nwon o ma tun se Mubahila pelu enikankan mo. Ti iroyin yi ba je ododo, eyi nsafihan wipe atunbotan buburu Mirza Tahir seku to nko royi-royi bayin lopolo. O sile jasi wipe e nwa ona ete omiran abi ki o je wipe iku oro ti asaaju yin ku nderu bayin. Latara iwe yi mo fe tana imole awon oro pataki kan si opolo nyin. Toba je wipe eyin fe ri eko ko ninu iku oro ti asaaju nyin Mirza Tahir ku.

            E se ranti wipe awon gbolohun Mubahila laarin Ilyas Suttar ati Mirza Tahir wa lati enu Mirza Tahir funrare ni odun 1988.

            Isubu re ninu Mubahila yi safihan wipe opuro ni Mirza Ghulam Ahmad Qadiani. Mo beyin wipe ki e fi atunbotan buburu ti Mirza Tahir sarikogbon. Ipada sinu esin Islam ni ona abayo to daraju latifi korayin yo ati gbogbo awon emi ti eti si lona fi seti bebe ina lati awon ogorun odun to niye sehin. Eleyi ni ona ere nje lodo Olohun ati orire aiye ati orun ati atunbotan rere tioba yeyin si. Olohun yio si san nyi lesan rere.

            Nida keji, mo npeyin si ipade f’oro Jomitoro-oro latile mo iyato laarin awon ododo ati awon iro ti Mirza Ghulam Ahmad Qadiani pa sile.

            Efunrayin ni akin okan latile wa jepe mi yi.

            Pelu ogo Olohun moti gbaradi lati faya kaya pelu nyin.

            Lojo oni mo fe ki e fun mi lesi wipe arole kaarun ti gbaradi lati faya kaya pelu mi.

            O rorun wipe ki e ma ti-i gbaradi lati faya kaya foro jomitoto-oro pelu mi abi ki a te-e sile naa, nitori ina to sese joyin koja eyi ni iku Mirza Tahir lehin Mubahila to sele laarin awon mejeji. Sugbon kosi isoro kankan ninu ipade foro Jomitoro-oro yi.

            Bi eyin ba jepe yi, yio fese nyin rinle lori ipo arole gegebi asaaju tuntun fun Jamaa Ahmadiyya atipe yo fun nyin ni anfani lati mo iyato laarin o dodo ati awon iro ti Mirza Ghulam Ahmad Qadiani pa sile niwaju gbogbo mutumuwa.

            Laïpe mo nreti esi iwe ti mo ko siyin.

            Ike ati alafia Olohun ko ma be pelu awon eniti ntona otito

            Dr Syed Rashid Ali

            Dibba Al-Fujairah

13 Mai 2003.

IHA WONI JAMAA AHMADIYYA KO SI AWON ALATAKO RE ?

            Otito koro. Atemora ati akin okan nla ni afi ngba otito. Imona a ma wa lati odo Olohun oba afinimona fun eniti nbawa ona otito lati mo. Eto tiwa ni ki a fi ona ododo fi mo awon eniyan. Awon atejade iwe ti awon ijo alatako Jamaa Ahmadiyya ko lori iwe iro ati awon iroyin iwa ibaje eniti nje Mirza Ghulam Ahmad Qadiani, da rogbodiyan sile di isu atayanyan fun awon omolehin Jamaa Ahmadiyya. Tori wipe nwon ko mo ona abajade kuro ninu eha ti nwon kosi, nwon nlo ogbon ewe nwon npaja lobo, nwon nfi gaga fi bo awon eniyan loju, ki nwon o mase ridi otito oro naa. Opolopo igba ni nwon a ma so funwa wipe ka ko awon oro wa je nitoriple alasokoje ni awon naa. Nwon a ma kowe bi « Iranse Satani » ninu eyiti nwon a ma bu enu ete lu awon omo ijo wa ati awon iwe ti atejade. Towun tibe, nigbamiran nwon a ma doju ija ko gbona ko awon alatako nwon latile ko nwon laya je ki nwon o ma le soro, igbamiran nwon a gbiyanju dogbon fiwon ha si enu ofin ijoba abi ki nwon o pawon nipakupa.

            Awon apejuwe to jofu han re :

IKU OGAGUN ZIAL-UL-HAQ

            Ni odun 1974, lasiko oye igbakeji aare orilede PAKISTAN, iyen ogbeni Zulfiqar Ali Bhutto, Igbimo Asofin esin Islam ni orilede Pakistan, lehin iforo Jomitoro-oro olosu mefa, abajade oro nwon nipe nwon fun awon olumo Jamaa Ahmadiyya Qadianiyya ati awon Lahoris ni anfani ati salaye awon idi pataki ti nwon fi nperawon ni musulumi. Nibe ni ofin ti jade wipe awon Ahmadiyya Qadiani ati awon Lahoris nwon ki nse musulumi ododo.

            Ipinu igbimo asofin esin Islam nilu Pakistan labe ase ogagun Ali Bhutto nipe ofin to de awon ti ki nse musulumi lo de awon Ahmadis / Quadianis / ati awon Lahoris. Towun tibi igbimo asofin Islam ni ilu Pakistan se sowipe awon Ahmadis / Quadianis / Lahoris nwon ki nse musulumi ododo, nwon tun nse wasu loruko musulumi ododo nwon fi nfiran si awon musulumi ilu Paksitan awon ti onka nwon ju 150 millions lo. Ni odun 1984, ogagun Zia-ul-Haq AARE ORILEDE PAKISTAN ka ofin ti igbimo asofin se kun. O fowo si-i leyito sewipe owa di ofin amulo ninu iwe ofin ijoba, Oro yi bi awon Ahmadis / Quadianis / Lahoris ninu, bawon ninuje, nwon kaa kun ese ti koni idariji ohun to fa sababi iku eemo, iyanu ti ogagun Zia-ul-Haq ku ninu isele jamba oko ofurufu. Towun tibi oti se han wipe awon Ahmadis Qadianis lowo ninu iku re, nwon gbiyanju debi wipe awon ti nwon fi esun apaniyan fi kan nwon ko foju ba ile ejo.

IKU MAULANA YUSUF LUDHAINVI

            Apejuwe miran to tun sele laïpe yi owun naa ni iku oro ti nderuba gbogbo mutumuwa ti Maulana Yusuf Ludhainvi ku losan gangan. Ni nkan bi ogun odun sehin ti o fi bere si ni siso kuro lori awon iro nlala ti Jamaa Ahmadiyya Qadianiya npa ninu awon atejade ati awon iforo Jomitoro-oro re. Maulana Yusuf te iwe to po to fi tu asiri iro awon Qadianis. Ni owuro 18 Mai 2000 to jade kuro nile re latilo silese khatme Nabuwwat ni karachi, awon alapa eniyan ti nwon gun keke afesewa ni nwon da iban bo-o ni nwon pa-a. Nwon salo lehin igbati nwon yinban fun awako re. Omo re si farapa leyi to po. Titi dojo oni awon alapata eniyan nwon nrin arinyan ninu ilu yi lalaïko jiya ese nwon.

            Omo iya Ahtesham-ul-Haq Abdul Bari ti nwon fi esun apaniyan fi kan latifi sakoba fun-un.

            Ahtesham-ul-Haq, ogbologbo Ahmadis, nsemi nilu INDE. Baba re fese rinle ninu Jamaa Ahmadiyya. Lehin igba gboro gbogbo awon ebi re di omo ijo Ayhmadiyya. Nwon jogun aye nla kan to je wipe awon ti nwon bi sinu Ahmadis / Qadianis ni nwon ma nlo aye naa. Towun-tibe-e lehin odun melo kan, baba Ahtesham bere si seye meji si Ahmadiyya, sababi to fi gba esin Islam oun ati awon omo re nigbati oku sidede ki o jepe iku. Ope ni f’Olohun. gegebi ise nwon, awon iranse ati omolehin Qadianis bere si nderu bawon wipe ki nwon pada sinu Jamaa Ahmadiyya. Bi ojo se ngori ojo, ni Ahtesham-ul-Haq-fi nsiso lori awon iro Jamaa Ahmadiyya, o wa di oguna gbongbo ninu awon ijo alatako Jamaa Ahmadiyya leniti nko awon musulumi ododo leko to si nsalaye awon ona alude apade owo ehin ti nwon nje. Ope ni f’Olohun. O rin irin ajo to po nilu Inde to fi nsiso lori iro Jamaa Ahmadiyya. O bori gbogbo awon omolehin Qadianis ninu gbogbo ipade iforo Jomitoro-oro ti nwon jojose. Opolopo ninu awon to sese wonu Ahmadiyya nilu inde ni nwon pada jade kuro ninu re. Ahtesham lo silu London latilo pe arole ni ipade iforoJomitoro oro, Mirza sa kole jepe.

            Ikan ninu igbiyanju Jamaa Ahmadiyya latile fi di Ahtesham lenu lati so ododo, nwon fenu ba omoluabi re je nwon tun gbiyanju lati sakoba fun-un, nwon lo ogon jamba lati fi yo oun ati ebi re kuro ninu Building Al-Haq. Ehin awon isele yi ni nwon fi esun ipaniyan fi kan omo iya Ahtesham Abdul-Bari Latifi sakoba fun-un sugbon oba alagbara ko-o yo kuro ninu re nigbati ko mo nipa re adupe fun Oba ododo.

Iwa ibaje Mirza Basheeruddin Mehmud (omo Mirza Ghulam Ahmad Qadiani to je

arole keji fun Jamaa Ahmadiyya) ati isekupa Bashir Masri.

            Baba Bashir Masri, Abdur rehman Masri tewogba ohun to farajo esin Islam loju re lati owo Mirza Ghulam Ahmad Qadiani. O si di ikan pataki ninu awon omolehin to mu sasa ninu Jamaa ni akoko ti hakeem Nuruddin ati Mirza Mehmud wa lori khalifa. Abdur Rehman Masri se awon ore nlala fun Jamaa. Mirza Mehmud, omo Mirza Ghulam Ahmad Qadiani. Je gbajumo onipansaga.

            Loju aiye baba re loti fita ba omodebirin kan ninu awon o mo ti omolehin baba re kan bi lasepo. Sugbon nwon pa oran yi mole laarin oun ati baba re ati awon omo ijo baba re. Nigbati o wa di khalifa Qadiani, awon odomodekunrin ati awon odomodebirin ati awon odomodebirin ati awon abileko ti ilu Qadiani lofi iwa ibaje re fi da loro. Koda, omobirin re Ummatul Rasheed ko bo lowo bibasun re. O daku ninu isele buburu laarin oun ati baba re. Iya re, iyawo Mirza Mehmud satako re bayi wipe : « Kilo le fa iru ikanju bayi, e basi se suru fun odun kan sikeji ? O fin daraju nitoripe kole sa losibi kankan. Se eyin ko ri awon obirin miran ni ? »

            Nigbati ikan ninu awon ebi re da-a lebi lori iwa ibaje yi esi ti nwon gbo lenu re ni wipe : « Awon eniyan ma go-o debi wipe, nwon roko kan, nwon si logi sinu re, nigbati awon igi yen wa dagba ti nwon so eso rere, nwon wa nsope elomiran ni yio ka awon eso re elomiran ni yio je nwon.

            Nwon bi Bashir Masri ni odun 1914 silu Qadian. O di omo odun mejidilogun, odomode to rewa tilu Kashimir, lojo ti Khalifa pe-e sile re fun idi oro kan laarin oun atie o jo o loju pupo nitoripe eni owo ati agbegba bi oba ni Khalifa je fun Jamaa. Kotojo ko tosu to fi wipe eni yepere ni Khalifa yi nigbati Bashir Masri ri bi Khalifa se ko awon odomodekunrin ati awon odomodebirin jo sinu aafin re latile ma jewon nipa bawon lasepo ati bi awon omodo re naa se njerawon nipa barawon lasepo lojure, tosi je ohun to dara loju re. Lehin igba gboro kori orun sun mo loru, leniti nkigbe ti ko mo bawo ni yio se jade ninu ahamo yi. Abajade re nipe, o sakin okan o ko oruko awon eniti nwon nipin ninu isele yi ati awon ojo ati osu ati agogo ti awon isele naa nwaye, o si gbe akosile yi fun baba re. O si salaye gbogbo awon isele naa fun-un. Nibere pepe baba re koni igbagbo si oro yi. Sugbon lori asotenumo omo re, nitori idaniloju o pada sewadi lodo khalifa. Abalo Abalo ori-i wipe ododo ni omo towun nso. O kowe lopolopo si « HUZOOR » re. Mirza Mehmud wa so fun-un wipe kio ko awon oro to so sinu awon iwe yen je, ko sowipe oun ko so be mo abi kio jade kuro ninu Jamaa. Eo mawa gbo awon isele to nwaye lehin ijade yi lenu Bashir Masri ninu awon oro to nbowa yi.

            « Lehin igbati moti jade kuro ninu egbe pansaga asebaje parapo ti oludari nwon je khalifa, igbesi aiye mi bo sinu ewu. Awon alapata eniyan re nsomi latise ni suta. Latile fi segun re, ona ti ko lero re ni mo gba yo si-i. Nigbati mo lo koju re fi atejade mi ti mo fi tu gbogbo awon asiri awon iwa ibaje re ati awon odale ti nwon njo se-e ati awon agogo, ojo, osu odun han-an. Mosi salaye fun-un wipe moti pin-in fun awon otokulu pelu majemu wipe ki nwon o fan-an ka. 

            Bi nwon batile gbo wipe khalifa seku pami abi nwon femiku idehin igbati mo gbe igbese yi ni mo tori ifokanbale, mo wa nrin arinyan nilu Qadiani.

            Bi mo se nri alekun iwa ibaye yi, beeni ayikonigbagbo mi fi nlekun titi mo fi di alaïmore f’olohun. Akoko isoro loje fun mi ni igbessi aiye mi. Gbogbo igbati mo fi ri inira, ti nko ri ona abajade irorun kankan, mo gbodo salaye re fun baba mi. Inira nla lo nje fun-un. Gegebi eko ko gbodo gba oro odomade kunrin gbo lalaïkose iwadi to peye. O si bere si sewadi labenu kope ko jina kotori agbandaju wipe ododo ni oro mi.

            Baba mi kowe si khalifa wipe ko salaye oro yi fowun lekunrere abi ti oba ri bee kio fi oye sile. O ma se-o, ti ko fun baba mi lesi kankan. Sugbon lehin iranti meji khalifa so fun awon Jamaa wipe oun ti yo abdur –rehman masri ati gbogbo awon ebi re kuro ninu Jamaa. Gbogbo awon iwe meteta ni nwon pin kakiri ilu Inde lehin igba gboro.

            Itumo eyi nipe Jamaa koni bawon se rara mo. Igbesi aiye wa bo sinu ewu debi wipe ijoba fi awon ologun fi role wa ka fun odidi ojo kan fun aabo wa. Enikankan ninu wa ki-i jade bikose pelu olopa. Pelu gbogbo awon ona ifura ati isora wonyi osangangan ni awon alapata eniyan bamija ati awon meji ninu awon ore mi ti a jojo rin lojo yen, ti nwon si gun ikan nigbaya ti nwon si pa-a. Nwon si ko nkan bo enikan lorun ati ejika leyiti o fi gbele iwosan oyimbo fun ojo gboro. Ninu ija naa emi naa fi kondo owo mi dapa sara ikan ninu awon odaran yi. Awon odaran yoku ni nwon gbee salo, sugbon awon olopa to pa eje re titi nwon fi ri-i timole. Lehin ojo gboro nwon pada ju-u sile lehin igbati idajo wipe ko mo nkankan nipa iseleyi.

            Eleyi ni ejo abosi to foju han ti ijoba Qadian ma nda. Leyito sewipe ijoba Qadian lo seto isinku re. Khalifa gangan lo dari eto isinku ore mi ti awon odaran yi pa.

            Lehin isele buburu yi, igbimo ijo awon musulumi ti nwon npeni « Majlis-e-Ahrar-ul slam » fi awon eniyan ranse fi kun awon olopa ijoba fun aabo wa. Nwon ko awon ago siwaju ile wa.

            Jamaa mirza (Ahmadiyya) pa adapa iro fi sakoba, fi ba okiki baba mi je ati latile fi run owo re ati awon dukiya re. O soro lati gbo bukata omo mokanla nigbati gbogbo awon ona ti owo nba wole ti mo-o – debi wipe ota awon ohun eso re ati gold ti ebi to fi ngbo bukata awon omo re. Olori tunasiri to fa ibanuje fun wa lakoko yi, owun lile ti nwon le awon omo nile we fun owo ilewe. Awon alaye ija yi ati egan, ilara inunibini to wa labe re ni awon oniwe iroyin ilu Inde pin kakiri agbaiye.

            Ijoba Qadian ati apakan awon ara ilu yi fara ni ebi latifi lewa kuro nilu tipa-tipa. A losi lahore. Baba mi darapo mo ijo lahori pelu wipe ko fi bee siyato, nla kan laarin igbagbo nwon ati tawon Qadianis. Ijeni nipa, imotara eni nikan kofi bee joba nilu lahore. Gbogbo akoko wonyen mo dawa loto mi ni. Gegebi oro mi nisaaju nipe inira yi so igbagbo ododo mi nu.

Towun – tibee mo bere si-i darapo pelu awon asaaju ijo Ahrar awon eniti nwon dami mo gidi. Ninu won ni syed ataullah shah Bukhari, Maulana Habibur-Rehman Ludhainvi, Chaudhary Afzal-Haque ati Maulana Mazhar Ali Azhar. Mori nwon ni omo iya esin Islam gidi eni ifokantan, atata onigbagbo ododo.

Ohan ninu isesi baba mi wipe ko faramo aïgbagbo mi denu. Tinu temi funrami si nbaje.

O si nso fun mi wipe gbogbo igba ni oun fi nbe Olohun funmi kole fi ona otito fi momi. Esi mi ni wipe o nsadura fun enito tiku saiye ti nwon koti-i-gbe sin-lehin iforoJomitoro oro to gun o gbami nimoran wipe ki nma kirun sadura. Mo wa bere si-i kirun sadura gegebi ase baba mi. Mo wa nwi bayi ninu adura mi : « Olohun mi ti o ba nbe lododo, fi amito dara kan han mi, mase fiya aïgbagbo mi fi jemi ».

Botile jepe adura yi farajo ti alaïgbagbo o si ntako lakaye awon onigbagbo gidi, o fun mi ni awon abayori to dara ninu imole ati imona Olohun. Laarin odun kansoso ti mo fi tera mo adura yi mo lala meji telerawon. O tipe ti awon alayi fun mi lami orisi eniti mo je ati ohun ti oun o pada je lojo iwaju. Ohun ti aye ko gbami lati salaye re funyin nibi lekun rere. Ala keji gun o si yemi, osi sopo morawon dara-dara. Ni adayanri loto fun eru elese gegebi temi kosi iyemeji wipe agbara kan wa toju gbogbo agbara lo eniti a npe ni Olohun. Enu mi gbaa lati funyi niro wipe nipari ala mi, Olohun fi han mi wipe alaïgbagbo, elegan, onilara ni khalifa Mirzai.

Lehin awon alayi, igbagbo mi lekun, mo wa di musulumi ododo. Oloogbe Syed Ataullah Shah Bakhari fimi han Maulana Mohammed Ilyas oludasile Jamaa Tablighi, nilu Mehroli ti ko jin silu Delhi nibiti moti tun esin Islam gba lododo ni 1940. Konge ore ni, sheikh-Al-Hadith ti ilu Inde, Maulana Muhammed zakariyah wa nibe, lehin irun Magrib ti Maulana Ilyas siwaju ki funwa. Gbogbo awon Jamaa ti onka nwon nlo bi ogoji sadura fun mi.

Ni odun 1941, mo pinu lati lo si ila-orun AFRICA pelu awon inira to nkoju mi.

Niduro ni ebute oko ofurufu (Port) ti ilu Bombay mo ka ayath yi : « E ha se nyin ti eyin ki yio fi ja ni oju ona Olohun ati fun awon alaïlagbara ninu awon okurin ati awon obirin ati awon omode, awon ti nwipe ; Oluwa wa muwa jade kuro ninu ilu yi ti awon ara re je alabosi, ki o si fun wa ni oludabobo kan lati odo re, ki osi funwa ni oluranlowo kan lati odo re ».

Lehin ogun odun ti mo se ni AFRICA, mo losi Angleterre ni 1961.

IJOYE IMAM NI WOKING

            Ni odun 1964, nwon fimi joye Imam ni mossalassi Shahjehan ni Woking nilu Angleterre. Eleyi fa iranti awon isele toti rekoja. Dr Leitner lo ko Mossalassi yi ni odun 1889 pelu asajo owo awon musulumi ilu Inde. Lehin igba gboro nwon yan igbimo ti yio ma dari eto owo to nwole ati eyi to njade. Lakoko yen Jamaa Ahmadiyya koïti firare han, iditi igbimo fi gbe idari eto owo to nwole ati eyiti njade fun awon ijo lahoris niyen.

            Ni odun 1968, awon igbimo eleto esin Islam melo kan gboro si-i nwon fese rinle ni Royaume-Uni, awon ti nwon nlekun ninu igbogun ti awon Lahoris latile gba mossalassi Kuro lowo nwon so-o di ibupade keko awon musulumi ododo. Akowe agba ati Akapo ijo yi ni nwon gbe oye Imam yi fun mi. Mo so funwon pato wipe oni sunna gidi ni moje. Mofi melo kan ninu awon atejade iwe mi fi han won. Nwon wipe awon ti gboro mi siwaju ohun toje anfani nla kan funmi. Nwon funmi niro idunu wipe ajele agba ti ilu PAKISTAN ti nje olori igbimo to ndari mossalassi yi bu owo lu iwe adewun igbase ti mo ko ami wipe o lowo si-i.

            Lehin igba die ti mo gbase ni mossalassi yi, mo farajo Mirzai loju awon eniyan mitoripe nkan bi aadorin odun ole marun siwaju awon Mirzai ni nwon njoye imam ni Mossalassi yi.

O se awon musulumi lemo biwon sele fi oni sunna fi joye Imam lojiji be. Mowa bo sinu ajaga meji. Awon iriran mi ati tijo mi ati iriran awon Lahoris ati tawon Qadianis loju ona igbo lo hungbo ko farajorawon. Beeni awon musulumi nka a kun eri to daju wipe mirzai ni mi, bikoba ribee nwon ki yio fimi joye Imam. Eleyi lo fa aïkogbora eni ye laarin emi ati awon oni sunna egbemi ti nbe ninu comité naa.

            Ero okan mi ki nkakiri awon ilu musulumi latile mo bawo ni awon eniyan nsesin Islam yi. Irin ajo yi gba odun meta ninu eyiti mo se 45.000 kilomètres ti mo fi sabewo awon ilu ti nwon ju ogoji lo. Siwaju ki nto kuro ni Mossalassi yi, mo fura mo daju wipe owo awon musulumi ododo ni Mossalassi yi wa. Mirzai meji abi meta pere lo wa ninu awon olori igbimo ti ndari re, enu nwon toro, ese nwon rinle, nwon kaju osuwan. Nwon ti gbese wiwa imam Mirzai kan lehin ijade kuro nibe mi.

            Lehin opolopo fanfa laarin emi ati awon apakan omo iyami muslumi, mo pepade pelu gbogbo awon egbe eleto esin Islam ati ti Eire ni Mossalassi ti East London. Ni 20 Juillet 1986 awon to jepe ju ogorun kan ninu awon asoju. Mo salaye oro naa funwon atipe mo gbodo bere irin ajo temi nipari odun yi atipe awon Mirzai ti lo gbogbo igbiyanju ati akikanju latifi Mirzai egbe won joye Imam ki nto lo.

            Isele pataki inu ija yi nipe gegebi akosile ofin, akoko igbimo nwon ti pari nigbati ise kiko Mossalassi ti pari. Awon musulumi ko mo nipa ofin yi titi di ojo ti mo salaye re funwon lekunrere.

            Ipinu to jade ninu ipade yi owun nipe ki nwon o tun igbimo miran yan ti yio ma dari awon eto owo Mossalassi Woking atipe ki nwon gbe Imam oni sunna to kaju aye naa sibe. Lafikun nwon gbodo yo awon Mirzai ti nbe ninu igbimo to ndari eto Mossalassi yen kuro atipe ki nwon o ma tun fi Iman Mirzai kankan fi joye nibe mo. Lori isese ti mo fi da Mossalassi yi pada fun awon musulumi ti mo si fi kuro ni Angleterre losi irin ajo temi ninu osu Novembre 1968 niyen.

            Ero awon ti ki-i se musulumi ni wipe iyapa enu abi atako to wa laarin wa pelu awon mirzai wa latara ikorira ati aïko lemi idariji loju ona esin. Awon ti ki-i se musulumi, nwon ko mo iyato laarin awon eko ofin Ahmaddiya ati awon eko ofin awon musulumi ododo, nidakeji awon obileje parapo, ota Islam to fese rinle, nwon nsepolongo ona anu ti nwon fi nwa anfani nwon loju ona oselu ati awon ona oro aje nwon ninu agbaiye esin Islam. Olubori awon iwa ibaje yi ni idagbasoke iberu awon musulumi ododo nipa ifayegba awon Qadiani lati sohun ti nwon nfé, eyito le ko awon odo nde musulumi ododo lese nipa eko rere.

IKU FAKHRUDDIN MULTANI

            Atata Ahmadi ni Fakhruddin Multani enito bura ifi gbogbo ara ati emi fi tele ofin Ahmadiyya niwaju Mirza Ghulam Ahmad Qadiani. O kuro nilu ti nwon ti bi-i (Multan) losi Qadian nibiti oti sile itaja toje ti iwe osi fi gbogbo igbesi aiye re ati dukiya re fi sin Jamaa ati ebi Mirza Ghulam Ahmad Qadiani. Awon iwa ibaje iba okunrin lasepo ti nwon fi esun re kan Mirza Mehmud so-o di eniyepere ti awon eniyan koni igbagbo si mo.

            Yato siti Abdur-Rehman Masri, o toro lodo khalifa wipe ko salaye ninu khutuba wipe adapa iro ni awon esun ti nwon fi kan oun, atipe, bi khalifa ba puro, ki ibawi Olohun de si-i. Bee nwon si gbodo yan awon eniyan kan ti nwon yio sewadi esun yi fini-fini ti nwon yio si mu abo wa fun Jamaa. Gegebi isesi nwon, ohun ti ati mo ti a enreti Khalifa yo oun ati gbogbo ebi re kuro ninu Jamaa. Itan to gun ni. Sugbon lehin odun mejilelogbon, nwon yo multani kuro lori oye pelu gege ikowe lasan. Itumo eyi ni wipe enikankan ninu Qadian ko gbodo bawon soro, baa ni ajose abi ta nkankan fun-un titi kan awon ounje.

            Akosile Fakharuddin Multani re :

            « Nigbati nwon kede yiyomi kuro ninu Jamaa, ohun ti nwon so nipe kosi ajose ati eku kiki laarin Jamaa ati Fakhruddin. Sibe-sibe lododo, itumo re nipe :

Nwon ko kayawo ati awon omo mi kun mo nitoripe temi ni nwon nse.

Nwon ko fun omo owo iyawo mi lait mo nitoripe omo mi ni.

Nwon ko fun omo odo ti nwe fun olokunrin iyawo mi wipe ko mase wa mo.

Nwon le awon to haya ile lodo mi jade tipa-tipa.

Nwon le Shamsuddin tima nbami taja kuro nile itaya mi.

Nwon ko ipaya ati ipahinkeke ba iyawo ati awon omo mi nigbati oje wipe gbogbo igba ni awon odaran fi nyinpo ile mi.

Nwon ko fun awon olutaja wipe nwon ko gbodo taja funwa mo.

Nwon ti la awon ona ti nwon yio fi bu enu ate lu business mi, somi di olosi ki nle ma ri ohun fun iyawo ati awon omo je mo.

Lehin igbati nwon doyinkale mi, awon ole ko awon dukiya mi lo, fun ohun bi odun metala ni awon isele buburu bayi fi ntelerawon.

Loju window ile mi, awon odomokunrin tiwa nibe nigbakugba, ti mo basi pana fun aabo mi, apakan ninu nwon a ma borawon si ihoho omoluabi niwaju iyawo ati omobirin mi.

Nwon le awon omo mi kuro nile iwe.

(Ododo ohun to nsele ikede yiyomi kuro ninu Jamaa to je ohun eema lati enu Fakhruddin Multani).

Bi khalifa Qadiani, Mirza Mehmud ba ro wipe latara ifara nimi ni oun yo fi jemi nipa lati jawo nipa awon igbese mi, biti ibura ninu khutuba ati yiyan ijo ti o sewadi to peye lori  esun yi ; o npuro tan rare danu ni. Fakhruddin Multani ati Abdur-Rehman Masri tesiwaju ninu awon ibere nwon latara awon iwe ti nwon fi nranse si-i khalifa ilana yi pada osi soro ibinu siwon ninu khutuba, o fi gbin ibinu siwon sokan awon omolehin re.

« Ni 6 Août 1937, Khalifa Sahed se Khutuba igbehin ni ojo jimaa ninu re ni inubiti awon omedhin ati awon olopa re si awon ota re (Multani, Bashir Masri ati awon yoku) ni ojo keji ni 7 Août ni deede agogo merin ati abo, lakoko irun Ansr, Maulana Fakhnuddin Saheb, Hakeem Abdul. Aziz Saheb ati Hafiz bashir Ahmad Masri Saheb, Hakeem Abdul. Aziz Saheb ati Hafiz Bashir Ahmad Masri Saheb ti nwon nse omo shaikh Abdur-Rehman Masri, gbogbo awon meteta nlo si ago olopa, iyen 100 mètres sile nwon, nibiti nwon ti bawon ja pelu eelo ija ti nwon ti pan enu re kale. Ohun ija yi wo igbaya Fakhruddin Saheb Multani da-a lu debi wipe o wonu edoforo re. Nigbati nwon dapa si Abdul Aziz Saheb lenu ati ikan ninu ereke re.

Osangangan ni nwon jamba Fakhruddin Multani. Owo lule niwaju aafin khalifa ti eje ndanu lara re pelu inira nla Enikankan ko sun mo-o lati solojojo re.

            Awon ijo eleto esin Islam ti nwon wa fun ati ma siso lori awon iwa ibaje jamba ti awon Ahmadiyya ba se ti oruko nwon nje Majlis - e - Ahrar ko tete gbo, sugbon nigbati nwon wa gbo, nwon s’olojojo nwon, nwon kowon lo sile iwosan oyimbo ti Gurdaspur. Fakhruddin Multani ku sile iwosan naa ni 13 Août 1937. Laarin egberu Ahmadis ti isele buburu yi soju won, kosi enito laya ati sododo. Jeri tako awon odaran wonyi. Yato si Gurbakhish sing (MBBS) enito nile iwosan oyimbo kan ladugbo naa ti isele jamba yi sele loju re, enito laya lati sododo jeri tako awon odaran wonyi towun tibi awon Ahmadis se sadewun owo nla fun-un wipe ko dake. Lori eri re ni nwon fi dajo iku fun AZIZ Ahmad Qadiani to paniyan. Mirza Mehmud, Khalifa keji seto adura isinku re o larinrin loruko ajeriku omolehin Ahmadiyya.

 

Mirza Ghulam, Hindu Arya Samaj ati Pandit Lekhram

Lehin isubu ipalara ti awon India ri ninu ija ominira ti nwon doju re ko awon amunisin iran funfun awon Britain, awon musulumi India ri adanwo to ga. Ikini awon Britanniques gba ijoba lowo nwon, nidakeji awon iranse Krist ati awon Hindous Arya Samaj nsepolongo, waasu  to lagbara latile ko awon alaï mokan musulumi sinu esin nwon. Fun itesiwaju ninu awon ona ti nwon la sile, awon asaaju amunisin iran funfun gbe Mirza dide ni iranse nwon latile pin idapo sokan ijo musulumi yeleyele ki o si ku Islam gidi danu kuro ninu okan awon musulumi ki nwon mase lagbara lati jagun gbarawon sile lowo awon amunisin iran funfun.

            Iranse Islam ni oruko ti Mirza nperare fun awon musulumi Nigbati ode Lahore ni odun 1869 lori wipe oun njagun soju ona esin Islam, o bere si-i pe awon iranse krist ati awon asaaju ijo Arya Samaj fun awon iforo Jomitoro oro loju ona esin. Ero  re ti nfipepe wonyi ki-i se ipepe soju ona esin Islam, sugbon o fi ntan awon musulumi Inde je ni. O dasasa nipa gbajue. Oripa nla ni ipolongo to lose nilu Lahore ni. Gbogbo awon ibiti ngba Eleyi ni igbese akoko latile fese jije iranse Islam re rinle. Towun tibi Mirza kose da lahan to, ti kosi lagbara ninu iforo jomito oro. Sugbon o mowe te jade. Ninu itan ijo Ahmadiyya a kori afihan wipe Mirza foroJomitoro oro pelu awon alatako re to si bori nwon ri. Beeni ohun iyanu ni oro siso re je fun awon alaïmokan ninu awon alatako re, sugbon bi omowe kan ba satako re, yo gbiyanju gbona ewe foro de-e-mole, ko-o laya je fi jije iranse re fi deruba-a-

            Lehin igbati ose osu melo kan ti o fi da rogbodiyan esin sile ni Lahore, Mirza Saheb wonu ilu Qadian leniti nsepolongo pelu awon ikede. Ero re lori gbogbo awon ise wonyi ki-i se ipepe soju ona Islam sugbon o nfe ki okiki ma kan kari aiye. Isoro si awon Arya Samaj je apakan ninu awon ero re lori ilana ipolongo re to bere ni odun 1877. O pin apa kini iwe re Braheen Ahmadiyya ni odun 1980 ninu eyito so wipe oun ni eniti Olohun gbe dide latile wa fi ododo esin Islam ye awon araiye. Eyini ibere ise re kuro latibi iperare ni eniti Olohun gbe dide Mirza rora tesiwaju leniti nperare ni oluso esin d’otun, o tun nperare ni Messia, o tun nperare ni Hindu Avtar, Olohun Khrishna. Ifiran si awon elesin Arya Samaj ni ero Mirza Saheb ti nfi nperare ni Hindu Avta.

            Awon ilana wa fun ipepe soju ona esin Islam Olohun so sinu AL-Qur’an :

            « Pe ipe si oju ona Oluwa re pelu ogbon ati wasi to dara, bawon jiyan pelu eyito dara (ni oro). Dajudaju Oluwa re oun lo mo ju nipa eniti o mona » (Qur’an 16 : 125).

            « E mase bu awon enikan ti nwon sin nkan miran lehin Olohun nitori ki nwon ma ba bu Olohun niti ikoja enu ala pelu aïmokan » (Qur’an 6 : 108).

            Towun tibee-bi aba sagbeyewo awon ilana ti eniti nperare ni olupepe soju ona esin Islam, Mirza Ghulam nto, ao ri oye wipe ko mo awon eko waasu atipe aïleko ati moto-moto, ijora eni loju ndamu re. Fun awon egberu odun koja sehin, awon musulumi ati awon elesin  Hindows nsemi nilu Inde ninu ifokanbale, ife, ifowo sowopo ati iteriba to ga. Ori imo ni ariyanjiyan nwon joko si, nwon si nma se deede laarin arawon, nwon ki nsi burawon benle barawon ja dipo jarawon logun. Sugbon lehin dide awon Britanniques silu inde, gbogbo nkan lo yipada. Iranse nwon Mirza ghulam farabale sise naa bi awon alawo funfun se fee si.

             Lehin awon ikede ti mirza Ghulam se, awon Hindous bere si bu enu ete lu esin Islam ati oludasile re. Ohun ti ko sele ri lati awon ogogorun odun sehin. Bawo lase debe ? itan to gun ni. Ni odun 1877, Mirza kede wipe oun yio te iwe kan ti akoke re yio ma je « Braheen Ahmadiyya » leyeti ipele re yio je aadota eyiti fi nsalaye ododo esin Islam. O so bayi wipe : gbogbo enito ba ni awon awijare to fese rinle fi satako atejade oun yi oun yio fun-un ni 10.000 Rs (owo to o ni, ni odun 1880). Nwon bere si ra atejade naa loja Nwon si nkaa pelu ibanuje, lowoti Mirza se satako awon Hindous ati bose bu awon orisa won.

            Vedas ati Shasters. Ninu awon ipele alakoko ninu Braheen Ahmadiyya, awon ikede re ati awon atejade re miran, Mirza a ma soro si awon elesin miran  to yato si esin Islam lesa awon Hindous leniti nfenu ate jewon latile firan siwon. Awon apejuwe melo kan re :

« Eleyi nise atipe awon eniyan wonyi ni opuro, esin nwon, igbagbo nwon, Olohun nwon ati Baagwan je awon eye ile aiye lasan abi igberaga lasan, abi orilede nwon abi eya nwon ….. nipa bee tani yo pe nwon ni Pundit ji, Guruji ati Swami ji ? (Braheen Ahmadiyya Apakini Roohan Khazain, Vol 1 p 107) »

« Egbe awo tuntun yi to wa latilu Inde ti nwon si npepade esin nwon ni Arya Samaj, awon ojo re, asaaju nwon, niti paapa oludasile egbe awo yi ni ogbeni kan ti nje Pundit Saheb ti itumo oruko re nje Diyamand. Gbogbo awon ede awo re ati asayan oro ti egbe awo yi da sile tori Vedas,kosi ninu esin abalaye Hindous abi ninu apapo awon asayan oro ati ede awo toti wa tele. Awon kan ninu re je ero tie fun rare »

(Braheen Ahmadiyya, Roohani Khazain Vol 1 p 72)

            « Nisisiyin ire Arya ! mo ba e yo ! Gbogbo ododo jeti Olohun nyin Permeshuwar latara ijeri Pundit Diyamand fun rare. O han wipe Olohun nyin Permeshwar je ara kan to tobi ti nma subu sori ile kan gegebi awon emi yoku o si see je gegebi awon eweko. Nidi eyi ni ma fi ndi Remchander nigbamiran atipe nigbamiran a ma di khrisna ati Much. Atipe nigbakan, o wa lori aworan elede ti nba awon to wa woran re sere leniti nje ounje pataki (imi, igbe). » (Roohani Khazain vol 2 p 395)

            « Permeshwar farajo awon omo nika mewewa labe okun idodo, awon onilàkaye loye »  (Roohani Khazain vol p 114)

            Awon oro ote, ifiran lowa ninu Braheen Ahmadiyya. Elesin Krist abi Hindou kan ko le ka oro yi ki ara ma taa. Awon oro tutu nbe tole fi salaye awon nkan wonyi to fi oro kobakungbe, oro ibanuje won yi so . Iru isokuso Mirza yi da ikorira inunibini ti koni ipekun sokan awon elesin Krist ati awon Hindous si awon musulumi.

            « Mirza Saheb dojuko awon Hindous ati awon omobirin nwon buwon tara ninu awon orisirisi ipele atejade iwe Braheen ati ninu awon atejade iwe to je ti ipolongotiijo Ahmadiyya npin kakiri. Ni oju awe kokandilogun ti iwe re « Shahna-e-Haq » owi bayi : « Eyin ko lati fa awon omobirin nyin fun mi fe laya nitoripe eyin nsewadi oro mi » Ninu iwe re, « Surman Chasme Arya », o soro buburu si awon omobirin Arya, osi bu awon orisa nwon. Lafikun o fi imisi re deruba awon Hindous. Iru awon atejade bayi lo moju awon Hindous ranko, gbona eje nwon, gbingi oro aïnipekun sokan nwon » (Asha’at Us Sunnah vol 18 p 14).

            Pandit Lekhram Pershwari ti Ahmadiyya, o wi bayi ninu iwe re ti akole re nje : « Takzeeb Braheen ».

            « Mirza Saheb kede wipe gbogbo eniti ki nbase musulumi ododo to ba ri awon eri ododo fi satako iwe Braheen Ahmadiyya oun yio fun-un ni 10.000 R. Pandit Lekhram ko iwe atako yi lori akole : (Takzeeb Braheen). Akojo eebu ti-i doju tini oro kobakungbe oro ibanuje lo fi fesi ninu iwe yi. Oun o ro wipe latijoti  Olohun ti da aiye ti awon eniyan ti nsemi ninu      re, enikan ti koja ala ninu isokuso si awon ojise abi awon enito sumo Olohun tobi Pandit se soro si Mirza Ghulam ninu iwe re. Bi eniyan ba fi emi ododo ati isedeede sagbeyewo oro yi yio han si-i kedere wipe Mirza ghulam Ahmad Saheb lo firan si Pandit, owun lo fa a lahan jade lofi koja ala ninu isokuso si esin Islam ati awon ojise Olohun ».

IWE TI PANDIT LEKHRAM KO SI MIRZA

            Ni 24 Juin 1893, Pandit Lekhram kowe si Mirza Ghulam Ahmad bayi wipe :

            « Bi oba jewipe akoogba ni enito ba kowe tako Braheen, nje eyin ni alakoko alaïdara. Nitoripe gegebi oro AL-Qur’an, eti salaïmore (kufr) si olohun, eyin le koko firan siwa, nitori eyi lafi fesi. Bi ki-i ba seyin lekoko firan siwa ni Permeshwar o daju wipe awa koni aniyan atikowe tako esin Islam. Bayi, bi o ba sewipe ohun ti Olohun ko fe ni, nje ile nyin ni ibinu arami yio koko sokale si ni Qadian. Bi oba sewipe mo ngbija arami ni, aïdara ni mo se, ibawi Olohun yio sima bami.

Ikede Mirza to so powun fe pate atifi agbara iseyanu towun han saiye-Nje awon

aranse Olohun se bee ?

            Latara pipin atejade iwe re Braheen Ahmadiyya kakiri aiye, Mirza Saheeb ro wipe awon mutumuwa nwon yio ma kokiki ise iyanu towun kakiri gbogbo agbaiye. Sugbon igida oro ko ribee ! o barare ni eniti ko gba oriyin kankan. Awon atat onimo ijinle nipa esin Islam so wipe kéféri (alaïmore) ni Mirza lehin iforo Jomitoro oro nwon.Mirza yi awon ilana re pada. Ero re ni kio fiseyanu re yi fi ko awon eniyan laya je. Ohun ti npe ni agbara atodolohun wa owun na ni iseyanu abi idan.

            Ni odun 1885, o se ipolongo kan to si pin egbegberu atejade iwe re fun awon Anglais ati awon Urdu.

            O fi npe awon asaaju elesin to yato si Islam ati awon asaaju esin Islam wipe ki nwon wa wo iseyanu towun.

            Bi eyin ba nseyemeji lori ododo esin Islam ati awon ami olohun e wa si Qadian gegebi oluwadi ododo ki e si rerayin sile fun odun kan eyin yio fi oju arayin ri awon ami wonyi. Sugbon pelu majemu wipe (ki aniyan nyin je ti oluwadi ododo) atipe lehin igbati e ba ri awon ami yi, eyin yio kede wiwonu esin Islam nyin, eyin yio si so amikan ti eri. Bi e ba wa pelu aniyan yi, daju daju eyin yio ri ami Olohun yi. Olohun loti sadewun yi, kosi iyemeji nibe »

            « Ero wipe ki nsiseyanu yi ki-i sero okan temi funrami bi kosepe Olohun alagbara julo lo pami lase re. Atipe asotele iro idunu yi ni wipe awon ti iwe yi ba te lowo nwon yio dake teriba »

            « Bi eyin ba wa ti e ko ri ami kankan lati odo Olohun lehin odun kan ti e lo, awa yio fun nyin ni 200 Rs fun osu kookan gegebi owo atunse abi gba mabinu ».

            Mimo fun Olohun o ! iru eemi wo leyi latile fi agbara Olohun han. Taani enito le wa odidi odun kan ni Qadian aroko ti Olohun ti binu si pelu Mirza, ki o gbagbe igbesi aiye re ati ebi re fun odidi odun kan nitori awon ami to ruju ti enikankan ko mo igbati awon ami yi yio yo lati owo Mirza ?

            atipe iru iwa jamba wo ni majemu re to da fun enito fe ri ami Olohun yi wipe ki o ni aniyan to dara (aniyan oluwadi ododo) ? Bi enikan ko bari awon ami Olohun yi, bayi mirza yio so wipe koni aniyan oluwadi ododo ni.

Ojise Olohun lododo ni iwa alaponle ninu awon isele bawonyi

            Nje Akehinde, ipekun awon ojise Olohun, Annabi Muhammad (SAW) da iru awon majemu bawonyi fun awon kuffar Mecca ?

            Nje Annabi toro lodo nwon wipe ki nwon bawun gbe reti ami Olohun kan to ruju siwon fun odidi odun kan lalaïkomogba ti yio sele pato ? Rara o, ko ri bee. Nigbati awon kuffar Mecca toro lodo re wipe ko siseyanu kan fun awon, Annabi ko seyemeji, kosi da majemu kankan fun nwon, kosi fun nwon lakoko kan. Lesekese lo fi osupa han nwon  ti osi pin si meji logbogba. Irawo nla olori awon irawo pin si meji, leyiti awon oluworan yi ri-i kedere bayi wipe ipinkan osupa yi wa lori apata nla kan, ipin keji wa lori apata nla keji loto (ewo Sahih Bukhari). Kafir kan toro lodo Annabi (SAW) wipe ki awon okuta wewe soro lowo Annabi. Lesekese, ni Annabi (SAW) sa awon okuta wewe sowo ni nwon njeri wipe Oba bi Olohun kosi atipe ojise Olohun ni Annabi Muhammad (SAW) ti Kafir na ngbo-o ketekete. Ko da majemu kankan siwaju, beeni ko da akoko kan, kosi se adayanri aniyan dara dara koto da a lohun. Ise ti afi ran-an ni kio fi ododo han awon eniyan, biwon ba gba biwon ko ba gba. Iyen ni edun okan re to gaju nitoripe Olohun ni olufinimona.

            Eleyi ni iwa rere, iwa aponle, iwa iteriba ipekun awon ojise Olohun.

            Ituno ohun ti a npe niseyanu owun ni ohun ti nkagara ba eniyan, ohun ti o ju lakaye awon eniyan lo, sise re naa koja agbara gbogbo mutumuwa. Pelu ase oba alagbara julo, oba ati oludari ile aiye, awon iseyanu wonyi a ma sele lati owo awon anigbagbo ododo wonyi latifi ola ati iyi awon ojise wonyi fi han wipe lododo olohun oba to ranwon nise nbe pelu nwon. Oba to seto ile aiye alagbara giga alase alewi lese lori ohungbogbo. Lesekese ni awonyi ri bee latile mu awon olugbagbo ododo teriba fun Olohun atipe ki igbagbo awon ti nwon gba awon ojise gbo le lekun.

            Oro kan pataki to tun ye ka ranrawa leti re nipe ojise kankan ko fi iseyanu re fi gberaga, owun yio fi awon eniyan sile ki nwon ma so – o.

            Towun -tibe, awon iwa opuro yi yato pata - pata si tawon ojise Olohun. Awon olukawe wa yio ri-i ka ninu awon oju ewe ti nbowayi :

            Iwe ti pandit lekhram ko si Mirza Ghulam.

            Lesekese ti pandit ri ikede naa, lakaye re so fun –un wipe ko siso lori iro ohun ti mirza nperare. Gbogbo igba ninu re fi nbaje lori ona ti mirza gba yepere esin hindoue ati awon iwe won osi ri ona satako gbarare sile. O kowe si-mirza  lati salaye fun- un wipe owun yio wa gbe Qadian :

            « Mo ka iwe nyin ti e pin kakiri ileroyin ti murtazai ti lahore ninu eyiti olohun payin lase wipe gbogbo eniti ki nba se musulumi to ba wa silu Qadian lodo nyin fun odun kan ti ko ri ami Olohun kankan ti ko di musulumi kori itelorun, eyin yio fun-un ni 200 Rs ni osoosu gegebi gbamabinu abi owo atunse. Lati wadi ami Olohun, mo gbaradi lati wa sodo nyin pelu majemu wipe ki emasan 200Rs fun ni osoosu, ki e lo da 2400Rs sile ifowopamo ti ijoba funmi nitori aboto peye. At ipe ki e pinu lori majemu wipe bi owun kosi gba esin Islam lehin odun kan ti mo fi gbabe nyin, lehin ami olohun kan ati awon iseyanu, tobaribee eyin koni ko 2400Rs naa fun mi. Fun odun kan owo yi yo wa nile  ifowopamo ijoba, eyin kosi gbodo gba a. Mo gba lati di omo akeko nyin fun odun kan »

(Iwe Mirza Ghulam ti 3 Avril 1885, to wa ninu Raees-e- Qadian latowo Rafiq Dilawari, p 163)

Esi ti Mirza Ghulam fun Pandit – Awon majemu ti ko to

            Inu bi Mirza Ghulam gidi nigbati o ri esi ti Pandit Lekhram fun un Eleyi ni ilana re ti ma nto, a ma gbiyanju latifi Pandit Lekhram ha senu panpe oro ki o fi korareyo lowo Pandit. Owi bayi ninu akosile re :

            « Ninu atejade iwe mi, awon olumo eni aponle awon asaaju ijo ni oro mi nbawi, awon to sewipe gbigba tiwon yio ko ipalara ba opo eniyan. Sungbon eyin kosi ninu awon eleyen ti oro mi nbawi, toba sewipe ero mi kose deede to jewipe eyin ni asaaju ijo nyin loni, toba ribee o daraju, emi ki yio dayin lamu pupo.

            E pe gbogbo awon asaaju ijo mararun, Arya Samaj Qadian, Arya Samaj Lahore, Aeya Samaj Am ritsar, Arya Samaj Ludhiana, Arya Samaj Reshawar, gbogbo awon ijo wonyi ni nwon gbodo bura lori wipe Pandit Lekhram ni asaaju oludari wa, ti nwon ba gba majemu yi, nwon yio ri awon ami melo kan, gbogbo nwon yio si gba esin Islam kia-kia. Eniyan yepere ti ko leto wipe ka jojo ma foroJomitoro oro ni oun o kayin kun ti e koba le parapo sasaro pelu ijo mararun kie mu ipinu kan to yanju wa fun mi ni nkan bi ose meji si akoko ti awa yi.

Esi ti Pandit Lehram fun-un

            « Owe yi lo bayi : « ohun ipate ni eyin eri, ki-i sohun jije » Mo ro wipe eyin yio mu adewun nyin se gegebi akosile nyin ninu atejade nyin, sugbon mo tanrami ni, oro ko ribee. Imoran nyin tie gbe jade simi wipe ki awon ijo Arya Samaj mararun gbami ni asaaju ati oludari nwon, fi han wipe ododo ni oro owe ti nso bayi wipe : « ki-i ba ologbon ewe kio ma riwi » bawo ni awon omolehin Arya Samaj mararun se le tewogba esin Islam lori ijeni nipa bura fi gbami lasaaju oludari nwon ?

            Seyin fe di omolehin Arya ni ? Sawon omoyayin, awon onbi nyin ati gbogbo musulumi Qadian yoku nwon yio darapo mo esin Arya ni ? Laye-laye oro kole ribee. Mirza Saheb ! Gbogbo awon aba nyin ti koni itumo kankan ko ba eniyan losi ebute rere kan bikose ona iruju. Bi eyin ba darapo mo esin Arya, lehin opolopo iwadi ti e se, eleyi yio ma je awijare to daju wipe esin ododo ni Arya. Beena nidakeji ki awon Arya Samaj di musulumi ododo nitorimi yio je eri to fojuhan ninu iseyanu esin Islam. Latigbati aso ti si lori iro nyin latara awon Arya Samaj ti Qadian, mori wipe oun o puro tanrami lori oro ti mo so bayi wipe : « Aïpe ori ni kia dan eniyan wo ! Towun tibee, e moomo sa latise nkankan leniti nyera fun ibere » (Iwe ti Pandit kosi Mirza Ghulam ni 9 Avril 1885 eyiti akosile re nbe ninu Raees-e-Qadian latowo Rafiq Dialawani p 164)

Awawi miran latenu Mirza Ghulam

            « Awon olola eniyan ni a fi owo 200Rs yi lele fun. Bi mo ba fi 200Rs lele fun gbogbo eniyan, nibo ni oun o tiri owo nla to bee ? Bi  eyin ba ri ebun iru owo yi nibomiran o temilorun. E fiyemi wipe eni pataki bee nbe ni odo nyin... odi oroyan funyin latiwa si Quadian ki ero yen ba le kuro lokan nyin atipe ki e le ri aridaju.» (Iwe Mirza Ghulam si Pandit ni 16 Avril 1885 ninu akosile iwe Raees-e-Qadian lati owo Rafiq Dialawarip 163)

Asotenumo Lekhram

            « Mirza Saheb ! Itumo ikede nyin akoko ko yewa rara lopin igbati iwe nyin ti 7 Avril nsoro to yato si iwe nyin ti 16 Avril. Eleyi fi han wipe oro nyin ntakorawon. Ebe ti mo tun nbeyin nipe bi adewun nyin ba jododo, ti eyin je olusododo, oluwadi ona ododo, to jewipe Oluwa sayin lesa latifi gbogbo mutumuwa mona ododo,e lo fi 2400 Rs owo odun kan sile fowopamo ijoba ko ma je 200 Rs ni osoosu fun oluwadi otito iseyanu nyin.

            E fun mi ni aridaju wipe bi emi koba ri itelorun ti nko gba esin Islam lehin odun kan labe tito nyin, ti nkori awon ami Olohun ati iseyanu, nje eyin yio gbe 2400 Rs naa funmi atipe fun odidi odun kan ni owo naa yio fiwa nile ifowopamo ti ijoba. Lopin igbati ojewipe Olohun lo sayin lesa lododo, kilode ti eyin nko latipe iru adewun bayi ! ti e nko iru owobayi lati san ? Nigbati o jewipe ki-i se kia-kia, lesekese ni ododo naa yio sele, ti eyin si ni igbagbo ododo si awon iseyanu nyin ko to ki eyin sa lati mu adewun nyin se. Bi o ba je ododo ni ikede ati ipolongo nyin wipe Olohun fi han yin wipe owun  sayin lesa seyin lojise re ajewipe eyin gan ti gberayin sori ate polongo arayin sekarimi ninu opolopo isele, eyi koni je ki ndake teriba gba awon ohun ti e nperayin. Olohun sadewun funyin, Nisisinyi eyin funrayin ko gba-a gbo. Bawo latile gba wipe ako gbodo so-o felomiran nigbati eyin funrayin koni igbagbo to rinle si-i. Gbogbo awon awawi nyin ti efe fi pari fanfa edekoyede ati ikede nyin wipe nigbati orun ba bere si-i yo nibiwo re, e o san owo yi. Eleyi yo farajo abuku funru onilakaye bi-i tiyin. Nitoripe eyin ki npe adewun ni awon omolehin Arya kankan kose fe wa sodo nyin mo. Mo ko-o ni akotunko ni opolopo iba wipe emi funrami yanrami latile sewadi ododo agbara iseyanu nyin. Mo gba lati je omo akeko nyin ati wiwa bayin gbe Qadian fun odidi odun kan. Niwonba akoko yi, ti eyin ba tun ye adewun yi, koni si anfani ninu ikowe sirawa mo » (iwe Mirza Ghulam ti 30 Avril 1885, ti akosile re nbe ninu Raees-e-Qadian latowo Rafiq Dialawari p 164)

Mirza fesi bayi – Mo fi majemu kan kun-un

            Nigbati Mirza mo daju wipe Lekhram koni kuro nilu re wasi Qadian lalaïkosi ipinu kankan lori oro owo yen, o pada gba beebe wipe owun yio gbe owo yi kale pelu ifi majemu tundun lele :

            « Nidakan, eniyan pataki yi yio gbe 2400 Rs kale, midakeji eyin naa yio gbe 2400Rs kale sile itaja Muhajin (Muhajin je onile itaja kan ni awon aroko, a ma ya awon eniyan lowo pelu gbigba ere lori oju owo nigbati nwon ba fe san-an pada, eyi yio je ibawi fun kiko ti eyin ko lati gba esin Islam, ko ma je ohun iranti fun eniti Olohun ba gbe isegun fu. » (iwe Mirza Ghulam ti 17 Avril 1885 ninu akosile Raees-e-Qadian latowo Rafiq Dilawari p 163)

Esi Pandit Lekhram     

« Ipile ikowe sirawa ni ikede nyin ti e funka nilese iwe iroyin ti Murtazai nilu Lahore ni eyi ti e so pato wipe Olohun payin lase wipe ki e ma pe awon eniyan sinu esin Islam. Enikeni tobawa bawon gbe Qadian fun odidi odun kan atipe lehin igbati o ba ri ami Olohun ati iseyanu, ti kosi gba esin Islam, yin yio fun-un ni owo atunse gbamabinu ti nje 200 Rs fun osu kookan, ohun ti nje 2400 Rs fun odun kan. Nisisinyi, e titun gbe majemu miran jade…… Omoyami owonjulo ! Eese ti eyin nye adewun ti e se funrayin atipe kilode ti e kofe se deede ? Nje ilana awon oluberu Olohun leyi ? Nisisinyi, ni e sese kede wipe ohun ti e so siwaju eti ko-o je. Ki e to se ikede iseyanu nyin, eti gbodo darayin loju wipe eyin yio siseyanu yi leyiti yio lapa lara eniti o ba ri-i-ti yio gba esin Islam lehin re daju-daju. Itumo iseyanu lododo ni ohun ti nkagara ba awon eniyan. Nigbati alatako eni koba kagara teriba gba fun-un, akoni ka-a kun iseyanu. Eyi nipe eyin funrayin nseyemeji siseyanu nyin, wipe Lekhram koni gaagbo. Nidi eyi ni eyin fi nda majemu tuntun loni. Towun tibe, latile muse ya : « mo loba opura nile re » mo gbaradi lati gba majemu tuntun yi leniti nfi 2400 Rs lele. » (Iwe Mirza Ghulam ti 20 Juillet 1885, to lakosile ninu Raees-e-Qadian latowo Rafiq Dilawari p 168)

Lehin gbigba majemu tuntun yi wole, Lekhram kowe si Mirza Ghulam leniti nso bayi:

“Mo nseyemeji siyin e salaye ami Olohun naa funmi, e so ojo ati osu ati odun ti eyin yio fi han wa ki awa le mo-o siwaju.“ (Iwe Mirza Ghulam ti 20 Juillet 1885, to wa ninu akosile Raees-e-Quadian latowo Rafiq Dilawari p 168).

 

            Awon ogbon ewe ti Mirza nda latile bo lowo Lekhram

            « Emi ko le da awon majemu miran latile se ikini keji iseyanu naa han nyin. Nje mole fiseyanu naa han nyin bi ? Emi ko mo ohun ti yio wa sele ? Emi ko je nkankan yato si iranse Olohun. » Emi ko mo ami ti olohun yio fi han wa. Mo mo wipe ami yi yio ju agbara eniyan lo. Olohun yio fi ami ti yio da awon mutumuwa lagara han. Majemu naa ni kie fun esi wipe beeni mole siseyanu abi beeko mi kole siseyanu. Awon oludajo naa koni si ninu esin enikankan ninu awa mejeji, sugbon ni ona meji ni ao ti yan nwon… » (Iwe Mirza Ghulam ti akosile re wa ninu Raees-e-Qadian latowo Rafiq Dilawari p 170)

            Lekhram ntopipin laïfin Mirza Ghulam

            « Nigbati o wunyin wipe ki awon ijo alatako mejeji fi owo lele koba dara ki eti fi sinu akosile ikede nyin takoko gegebi olutayo meji ti-i ma fowo lele fun idije, e kole yi awon majemu naa da, be sini eko gbodo pawonre. Bi kosepe iruju wa ninu akosile nyin ni, koda eniti koni lakaye pipo koni damu jina koto gboyin ye, yato si awon idamu ti nkoju mi latara ikowe siyin. Awijare ti ko fi si igbagbo fun adewun nyin, owun ni ifunnu nyin ti ko fese rinle ati awon ohun ti e koje ti eyin nperayin. Otito nipe eyin lu agogo enu nyin fi se ipolongo latile fi soro aje nyin. Idi niyen ti mo fini kie lo fi owo yen pamo.

            Sile ifowopamo ti ijoba. Eyin jebi bi eba ro wipe pelu awon majemu buburu nyin enikankan koni fe hararemo Qadian fun odidi odun kan laarin awon agbe ati awon alaïmokan, atipe lafikun bi enikan koba fun esi, Nwon yio gba awon aba iro ohun ti eyin ko je ti e nperayin. Towun tibi mo se dide latile siso lori awon iro nyin nitori awon idi pataki ti moti salaye nwon siwaju, awon eniyan ti gbiyanju lati gboriyin funmi. Etun sese  ronu gbe ogbon ewe miran jade latifi satako ikede nyin.

            Leniti nso bayi : « Eyin ni ikansoso iranse ti Olohun yan. »  Ohun ti e ko sori awon ila meji akoko to je ti iwe ikede nyin fi ododo iranse Olohun ti e nperayin han, ati kiko ti e ko oruko eni aponle Hazart Eisa, e fi arayin we-e niyen. Kosi laïfin nibi kata awon eni aponle onimo ijinle ninu esin Islam ji. Nitori gegebi orun lo han si gbogbo awon musulumi wipe Hazrat (Muhammad) ni ipekun awon ojise. Kilode ti igbimo nla to jeti asofin esin Islam fi gbe oro ibawi soke fun iru eni bee ? Nitoripe anseni lode koto tile, ehinkunle lota wa inu ile laseni ngbe. Njeeyin sowipe eko mo ami ti Olohun yio fi hanwa ? Idi pataki ti olohun tori re sayin lesa fun ise pataki. Kilode ti eyin ko mo awon asiri ise nyin siwajue ? Nigbati eyin ko mo orisi ami ti Olohun yo fi han wa, kilode ti e kede ami olohun lalaïko gba iyonda lodo Olohun ? Nigbati eyin ko gba Bissimillah gbo ninu imisi nyin, kilefe wa rise ? O han wipe latara aïmokan nyin, sisayin lesa funse pataki gegebi iranse ki-i se ati odo Olohun, oba olumo ikoko ati gbangba. Eleyi ni ibukun Satani. Mo toro lodo nyin wipe ki e fi awon ami ti o ju agbara awon eniyan lo han wa, A ko bere juyen lo. Siwaju eti ye-e- sugbon nisisinyi eko apakan awon oro nyin je, latibi ami Olohun e wa gba ami keji, e fi ami yi naa suwa loju nitori e ko mo bi yio tiri.

            O han porogodo wipe aba nikan nyin nda kole jokuta iro nyin po. E kan tie polongo arayin lasan. Lehin igbati e tewo gba gbogbo iwonyi emi ko mo okunfa ti e fi nda majemu yi, ti e fi nbere wipe ki nmukan ninu bee ni, beeko, ao yan awon oludajo, lotito bi aba ngbe oro kan yewo ti iyemeji si wa ninu apakan oro yi, ani latiri awon oludajo ni. Sugbon lopin igbati awon mutumuwa koni imo ikoko, nwon nbe ninu okunkun awon isele niyen. Bi eyin naa bawa ninu okunkun iseyanu nyin, yio dara wipe ki e sise yanu nyin niwaju awon oluso  awon ewure, e darijiwa. Kaka ki a ma wo iseyanu ti e nfi ifunnu se, o dara funwa kia gbele wa » (Iwe Mirza Ghulam ti 5 Août 1885, ti o wa ninu Raees-e-Qadian latowo Rafiq Dilawari p 171 172)

Mirza toro lodo Pandit wipe ki o wa si Qadian ki awon fi suru ati ife to oro naa

            « Agara da Mirza tenu-tenu, oro pesije fonilakaye. Lehin osu meta, Pandit fiwe ranse si Mirza fun iranti. Esi ti Mirza fun-un nipe Qadian ko jina tobo se lero re. Ewa pade mi, pelu ireti wipe ao fipinu sinu awon majemu naa. »

(Takzeeb Braheen Ahmadiyya latowo Rafiq Dilawari p 171 – 172)

            Oju osu marun lo ti Pandit ati Mirza Saheb fi nkowe sirawon, ti awon oriran riran iwe iroyin Punjab fi npi kakiri, gegebi Aaftaab Punjab, kohinur ati bee-bee lo (Takzeeb Braheen Ahmadiyya, latowo Pandit Lekhram, ninu iwe Raees-e-adian latowo Rafiq Dilawari p 171 – 172)

            Latigbati Mirza Saheb tiri itiju ninu ikowe sira eni laarin awon mejeji, akotun ri oripa ikowe sira eni naa ninu iwe Ahmadiyya mo. Loju aiye Mirza Saheb ni nwon ti pin iwe Takzeeb Ahmadiyya ati Zameena kakiri. Oka a owa nrahun desun awon oro kobakungbe, awon oro ti ko barawon mu ti olo sinu pupo ninu awon iwe re Mirza Saheb kole le ko nigbati nwon npolongo ikowe sira eni laarin nwon ninu Zameena de Takzeeb.

Pandit Lekhram ni ilu Qadian

            Lehin igbati Pandit gbawe ipe, kia-kia ni Pandit lo dahun latile fi ipinu sori awon majemu ilana naa. Leekan si-i Mirza gbiyanju latiri wipe owun ye ipade yi. O se pupo ti Pandit jafafa, emu ni Pandit ki-i mu nkan ti lagbede. O lemo-o tipe-tipe bi ema agbo. Towun tibee Mirza gbiyanju lati bolowo Pandit. Pandit enito sise ijoba ninu awon olopa fun odun gboro ko fi Mirza lorun sile. Lojo ojokan Pandit joko ti Mirza Ghulam nile Mirza latile fi ipinu sinu awon smajemu ti owun yio fi wa si Qadian fi wo ami Olohun naa. Ninu iforoJomitoro-oro, gbolohun « Khawariq-e-Aadaat »  yo sinu fanfa naa. Pandit so bayi wipe: « yiyi eto aiye pada » Ase ti Olohun fun obe ni ko ma ge nkan, ase ina ni koma jo gbogbo nkan, ase igi ni ko fese mule. Toba jewipe pelu olohun, e le yo ase gige nkan kuro lara obe, ki e yo ase jijo nkan kuro lara ina, kie fun igi lase ko ma kiri, to ba ribe emi yio di musulumi lesekese. Bi eyin ko ba le siseyanu iru eyi, e o di omolehin Arya, ki e simi ifenu rofo, agada owo dun be gedu afenu wako ki-i jaamu. »

            Mirza Saheb so bayi

            « Itumo Mau’jiza (iseyanu) koniyen ninu AL-Qur’an »

            Pandit fesi wipe :

            « Nigbati gbolohun yi kosi ninu AL-Qur’an, bawo ni awa sele mu eri ninu AL-Qur’an fi dahun oro yi ? »

            Mirza Saheb ntenumo-o wipe gbolohun yi wa ninu AL-Qur’an Pandit Lekhram gbe AL-Qur’an fun Mirza wipe : ko dakun jowo ki o fi gbolohun Mau’jizah fi han owun ninu AL-Qur’an. (otito nipe gbolohun yi kosi ninu akojo gbolohun AL-Qur’an)

Mirza Saheb wa gbolohun yi ninu gbogbo oju ewe Al-Qur’an fun iseju melo kan. Kori nkankan to jo-o. Nigbanaa owa ri mo daju leniti njewo so bayi : « Mo ko oro mi je, gbolohun yi kosi ninu Al-Qur’an Pandit Lekhram so ninu iwe re bayi wipe lakoko yi Hakeen Kitten All, ALA Inhale Chained, Pandit Jai kitten, Ala Saheb, omo egban abi aburo Mirza Saheb, Mirza Kamaluddin, Mnice Ali ati arugbo onirin ajo kan nwon wa nijoko ti nwon renkan wipe ki Mirza mase pe isele yi niro ».

(Takzeeb Braheen-e-Ahmadiyya latowo Pandit Lekhram p 86 o wa ninu Raees-e-Qadian latowo Rafique Dilawarin p 172 – 173)

Awon ibura, igbera eni sepe Pandit Lekhram ati awon itiju ti Mirza ri.

Pandit se iwonba to lese nitori ki Ilihaami Saheb (Mirza) ma se sa mo. Ki o gba awon majemu ti a pinu lori re lati fiwa gbe Qadian fun iwonba odun kan. Igida ti Pandit ko le yi Mirza Lokan pada. Nigbati osu-u, o simi gbogbo ariyanjiyan lori awon majemu lilo gbe Qadian fun odun kan. Dipo eleyen o toro lowo Mirza wipe ki a siseyanu ki owun ri lesekese. Ni gbogbo ojo kookan ni Pandit Lekhram nlo be Mirza wo nile re leniti nso bayi fun-un : « Bi eyin ba je olododo ninu aba ti e nda, e fiseyanu melo kan han mi » Mirza kori nkankan se han-an yatosi idorikodo lehin itiju nla nitoripe ohun ti nbere lodo re wipe ko se han owun, a ma sele latara iseyanu ti ki-i wa latowo opuro bi Mirza. Kia-kia ni Pandit ko awon ogogorun Hindeus (Arya) jo ni oja Qadian nibito ti nso kobakungbe oro si Mirza leniti nfi-i se yeye atowun ati ohun ti npeni igbagbo ati ipaya Olohun re. Awon eniyan nrerin takiti, lehin igbanaa Pandit seri pada lo sile pelu idunu ati itelorun.

Mirza Saheb rahun nipa isele yi ninu iwe re, « Faryaad-e-Dard ». Lapejuwe iwe to ko nipa isele yi re :

« Fun gbogbo awon ojo ti lekhram fi finu fedo soro buburu rekoja ala si esin islam, kobakungbe oro, oro ibanuje ti-i wamije loju eni ni nso simi. Ninu awon oro ifiran to so simi, o salaye wipe owun yio wa si Qadian lati foroJomitoro-oro lori awon majenu wiwa gbe Qadian fun iwomba osu kan. Emi ko losi aroko re lo pade re, mi osi fiwe ranse si-i. Ife inure lofiwa si Qadian. Ninu awon oro ifiran re to rekoja ala re, niwaju gbogbo awon hindous to wa laye naa, o gbeQadian fun nkan bi ojo meedogbon ti ko fi simi ninu isoro simi, lojo kankan, oro bi kile o faya ti bomoleti je ni nso simi. Loja ati ni awon ona ti awon musulumi nto ni nduro soro ibanuje, oro yakinlala bi ina bi ogun, awon oro sokutu wowo sokutu wowo si awon musulumi. Beeni nsoro ti-i dajale si Annabi Muhammad (SAW) dedi wipe mo kilo fun awon musulumi wipe ki nwon o mase losibi ipade re nitoripe enikankan kole doju ko-o. ope ni f’Olohun oba toni ki awon musulumi gba ikilo ki nwon o mase lo. Ogoro ninu olala oloye musulumi ni nwon wa desun Pandit funmi ni gbogbo awon ojo yen ti fi nbu Annabi Muhammad (SAW). Mori wipe ara ntawon, ni moba parowa funwon wipe onirin ajo ni Pandit. O wa fun iforoJomitoro oro ni. Moni ki nwon se suru. Ola imoran ti mo gba awon musulumi ni nwon fi koraro dake laïkofesi pelu wipe Pandit ko simi ereke ebu ni sise. Ojoojumo ni Pandit nwa sodo mi wa toro wipe ki nfi awon ami Olohun kan fi han owun abi iseyanu melo kan leniti nfimi se yeye. Pandit a ma wa lowuro abi losan latile wa bu Annabi Muhammad (SAW) ati lati bu enu ete lu esin Islam. Gegebi Asaaju buburu ti elesin Krist Pandit a ma so bayi : « Annabi nyin (SAW) ko siseyanu kankan atipe ikankan ninu awon asotele re ko pada ribee. Awon Mullahs kun iwe nyin fun awon iseyanu latile gbogo sagbega fun esin nyin ni ».

(Fayad-e-Dard Latowo Mirza Ghulam p. A. O wa ninu Raees-e-Qadian Latowo Rafiq Dilawani p 175 – 176).

Mirza loti, agara da-a kole siseyanu kankan.

Gbogbo bi Pandit se nda yeye Mirza sile nita gbangba, to si nyeye esin Islam to nbu Annabi Muhammad (SAW) ninu ile Mirza beena lo ntoro lowo Mirza wipe ko siseyanu melo kan han owun. Kiniba kodi Mirza lati siseyanu koda boba sekan soso Pandit ? Toba sewipe Mirza ba ni agbara kan lododo latifi se awon iseyanu ? Kiwa niyi tori latodo Annabi Muhammad (SAW) ? Kilode ti ko gba fun Pandit, eniti nfojoojumo fi soro si Annabi Muhammad (SAW) ? Lehin igbati o perare ni iranse Olohun eniti Olohun yo nda agbara iseyanu fun, Ese towa dake palolo niwaju Lekhram ?

Awon aba ati oro igberaga ti nbo wonyi wa lati enu Mirza : « Iyato to wa laarin emi ati awon ojise to siwaju mi nipe, mo siseyanu to po beeni asotele mi po to jododo. Niti papa daju-daju awon iseyanu mi ati awon asolete mi koni afiwe ati afijo pelu ti awon ojise ti nwon siwaju mi wa. Awon iseyanu nwon da gegebi itan sugbon awon iseyanu temi ogoro ninu awon eniyan ti nwon foju ri-i nwon le jeri wipe awon iseyanu nla ti ko legbe ni nwon. Ogoro ninu awon eniyan ni agba nla aiye ni nwon jeri re sugbon ti awon ojise ti nwon siwaju mi kotun sikan laiye mo yato siti Annabi Muhammad (SAW) ti mo jeri re ati Al-Qur’an to je ijeri ati itoka aiye raiye. Emi ni eni naa ti ogoro ninu awon eniyan fojuri apakan ninu awon iseyanu ati asolete re ti nwon si jeri si-i. »

(Ikede Mirza Ghulam, Roohani Khazain vol 18 p 460 – 461).

Towun tibee, eri to fojuhan ti aba yi nipe pelu wipe ota esin Islam kan lo sun Mirza kangiri, koda kole siseyanu kansoso han-an.

O foju han kedere wipe kosi ododo eyito fi nkere bi omona igun ninu awon aba ti nda eyiti nfi nperare ni eniti Olohun yan ni iranse re atipe owun ni agbara latile siseyanu abi wipe Olohun sadewun fowun wipe ami Olohun kan yio towo towun sele. Niru akoko itopinpin bee nigbati ota Islam kan nbu enu ate lu Islam to nsoro si ojise nla Muhammad (SAW) nita gbangba, kosi ona ti Olohun kofi ni fi ami re kan han latowo enito gbe dide ni iranse re latile fi gbee nija. Yato sipe kole siseyanu kankan, ko tie bori ota re ninu gbogbo ariyanjiyan ti nwon se lori ododo esin Islam. Kaka iyen, o yi awon musulumi lokan pada, tewon ro wipe ki nwon o mase fun Pandit lesi. Eyi fihan peete-peete wipe itunje iro to fojuhan gberegede ni awon aba ti nda wipe iranse Olohun ni owun, ateyi to fi nso wipe Olohun fihan owun wipe owun yio fi awon ami towun han ni Qadian atipe owun Mirza yo siseyanu. O paromolohun ni enito mo koto dojuti-i niwaju otan esin Islam yi. Igida ! Mirza ko kakosile lori ogiri.

Ona awawi ati itunije miran latowo Mira.

Ipe awon Arya si Mubahila kan.

Lehin iponju ti ori latara isubu itiju to subu niwaju osebo kafir (Lekhram), ni odun 1886, Mirza te iwe kan jade ti akole re nje « Surma charm-e-Arya ». Ninu iwe yi o npe awon alaponle Arya losibi Mubahila. O so wipe awon ami Mubahila yi yio sele lehin odun kan. Lagbara Olohun ninu Al-Fatwa ti nbo, eyin yio ka atele itan Pandit Lekhram, eyito se wipe iku lo wa kehin re, lo pari re.

Ike Olohun ati ola re ko ma bayin.

Dr Syed Rashid Ali.

Dr Seyd Rashid Ali

P.O. BOX : 11560

Fax: 971.9.2442846

Dibba, Al-Fujairah

United Arab Emirates

E-mail: rasyed@emirates.net.ae

 
   
 



» تاريخ النشر: 26-11-2009
» تاريخ الحفظ:
» شبكة ضد الإلحاد Anti Atheism
.:: http://www.anti-el7ad.com/site ::.