« 100 Years of Pious Fraud »






OGORUN ODUN SEYIN NINU OJULOWO EKAN ITANJE LATI OWO B.A. MASRI

IPINU IGBIMO ASOFIN ESIN NI AGBARIJO AYE

 

Eyin omo iya wa ninu esin Islam

Lokurin/LobinrinAsalam Alaykum Warahmatullah Wabarakatuhu

Ijo Quadian ti a mo si Mirzaiyat/Ahmadiya to ti wa di nkan to n da ede aiyede sile lode oni. Ni gbogbo agbaye ni awon musulumi ti fikun – lukun lati gbogun ti esin Ahmadiya ninu Islam. Bawo lo se je bayi ? Kilo de ti igbogun tiwon wa le nikeyin aye yii ? Nigba gbogbo ni awon odo ma n bere wipe « eese te n gbogun ti ijo Ahmadiya ? » Nigbati esin Islam si kowa pe ka ni ifarada, ka si kun fun opolopo suuru nigba ti ede aiyede ba waye.

Paapa julo, awon omo oni to gbeko iwe foju inu wo pe a ni lati maa hu iwa kanna si gbogbo awon ijo abi esin yoowu tii ba maa gbogun ti Islam. Fun apeere, awon esin kan gbagbo pe awon ojise olorun kan je omo bibi inu olorun. Awon miran tun kooyan pe ka teriba fun nkan ti olorun da abi igbamiran awon ti ko tie ni igbagbo pe olorun wa rara.

Sugbon, pelu gbogbo ede aiyede yii to n sele, a n se amojukuro fun won. Awon elesin Islam miran ro pe ka fiwon sile, (Mirzais) sori ilana won, bi o se ye won si, fun ekunrere alaye, awon ibeere ijinle lorisirisi ti waye lati ri aridaju lenu awon ijo wonyi. Nje won da ijo yi sile nitooto lati fi tun nkan se gege bi erongba won bi ? Abi won daa sile lati ma huwa makaruru. Loruko esin Islam.

Nibere pepe Quadianiya, iyen ogorun kan odun seyin, awon ojogbon amofin o tete ke gbajari si esin itanje ati ilana saeton yii. Lafikun, ijo yi duro gege bi olutumo esin Islam ati awon ofin ti won fi n se agbega ofin esin lati se atunse Islam nigba naa. Awon ojogbon ninu esin ro pe esin naa ko nii pe ti yio fi lo nile gege bi awon orisirisi esin ti wa, to si tun ti kogba wole. Be ojo se n lo, won sakiyesi pe ijo Quadiyaniya naa tun wa gbile ju bi won se roo lo.

Siwaju sii, o han si awon musulumi pe awon oyimbo geesi lo ran awon Quadiyaniya lowo. Lasiko naa, Ijoba to ko awon orile ede India leru ni awon musulumi gege bi alaida. Ni nkan odun marundinlogoji seyin, awon musulumi dide soro naa, to si sunmo isegun, won si mo oruko re ni :

„Igbogunti odun 1857“.

Awon alamojuto eto ijoba nile Britian ni opolopo alabasepo to poju owo ninu awon Quadiyaniya lati fi ba opo esin Islam je abi paare patapata. Nigba naa awon ijoba ile Geesi n satileyin ati iranlowo fun ijo Quadiyaniya, Nitori eyi ni awon olutewe Quadiyaniya se ma n ko nkan daada nipa ijoba ile Britain ti won si maa n foju fo awon aburu ti won se pamo sile laiko. Won tun te siwaju lati so wipe ise ti awon n se fun awon oyimbo alawo funfun je dandan abi eto ni fun awon musulumi India ninu esin.

Lati fi lee seran lowo lori oro naa, won ka awon aaya Qur’an to n paa lase fun awon musulumi lati tele oro ti awon alase won ba so iyen alase (Brittain) ni India gbodo tele.

Ni igba ti won ka aaya Al-Qur’an yii, won gbagbe pe awon alase naa gbodo wa lati inu esin Islam.

Kii se awon odun akoko nikan ni Quadiyaniya je alabasepo pelu alase (ile Brittain) to ko won leru.

Gbogbo asiko ti esin naa fi bere ajosepo yi ko han sita fun awon musulumi ri.

Loni, kii wa se nkan asiri mo laarin awon ile (ASIA) Indian. Awon Quadiyaniya ba awon ota esin Islam sowo po lati gbogun ti awon orile ede elesin Islam lagbaye.

O jo awon apakan ninu esin islam loju, bi awon ijo Quadiyaniya se n to eto won lese ese ati erongba won lati tun ni ibujoko abi eka kaakiri agbarijo aye.

Die ninu awon eeyan lo mo looto pe awon eka (ibujoko) ti won si kaakiri naa wa fun lati lo se alami, ati pe awon ise olorun bii (Dawah) (Tabligh) to je pe bojuboju Lasan ni won fi n se.

Nipa se eleyi, awon Quadiyaniya papa o mo oun to n sele ni koro, won safihan fun won pe ilosiwaju naa kese jari latara igbiyanju ati isapa won. Ka so tooto, owo nla ni awon ilu to n janfaani lara eto oselu abi oro aje lodo awon orile ede agbaye n na fun won. Awon ota Islam ri awon alabase ati awon alami ninu ijo Quadiyaniya, ni eyi to jeki ise naa wa di irorun fun won nitori bi ijo musulumi ni awon orile ede pupo.

Ni awon odun melo kan seyin, oje iyalenu fun eeyan pupo lati rii pe o je oun irorun fun awon ijo Quadiyaniya lati maa lo si orile ede okeere bii Europe, America, nigba ti elomiran si n foju wina (ri inira) ki won to rin irinajo si awon orile ede naa.

Mo ti so siwaju pe aiyede to wa laarin awon musulumi ati Quadiyaniya da lori ero abosi (oju aye) pe awon wa ninu Islam.

E je ki n fi dayin loju pe kii se nitori ailemoju kuro abi aigbagbo ododo. Ti won ba fi ara won han pe awon o se esin Islam mo to jepe esin mii ni won n se, a ni gbogun tiwon mo, a wa maa mu won gege bii awon esin miran ti a faye gba. A ni iyato laarin awon elesin Islam pelu awon miran, awon iyato miran je nkan pataki, sibesibe a ma n gbiyanju lati fi ye won ninu iforowero olore-sore to si ma n pari.

Aa le mu bi iro kekere nigbati oni jamba kan ba pe ara re ni okan ninu wa, to ba tun wa bere si ni tako awon ofin igbagbo wa to se pataki, E je ki n fun yin ni awon apeere melo kan :

O ti wa ninu akosile pe anabi kan o tun ni wa lati soro Islam leyin anabi Muhamed (S.A.W) bakannaa lo tun ri ninu awon esin to ku. Dajudaju, a mo pe ko si asiko kan ti olorun oba o fi ojise ranse fun idagbasoke emi ati itonisona awon eeyan to n naa da.

Iyen je okan ninu opo igbagbo ninu esin Islam. Awon musulumi gbagbo ninu ise ti awon ojise olorun wa lati je. Eyi to da lori pe olorun fona han wa, to si tun se igbega ninu emi ni eyi to je apapo mejeeji (ifonahan $ igbega emi) ma n mu ikapa wa ninu ogbon abi opolo awon eeyan lawon asiko kookan. Bi awon anabi kookan se n wa pelu iwe mimo won olorun fee be lati lee jeki eniyan gbonju ninu imo eyi tumo si pe ki eeyan lagbara lati ro nkan to niyi, to si dara. Ati ibe ni olorun oba ti yo ofin (shariah) jade latara anabi wa Muhammed (S.A.W). Eyi lo mu ki awon musulumi gbagbo pe dajudaju, anabi miran o ni sokale mo leyin anabi Muhammed (S.A.W).

Ti enikan ba si tun jade wa to pe ara re ni anabi, awon eeyan ma n foju were abi Manafiki wo iru eni bee.

Nigbati Mirza Ghulam Ahmad ti Quadian wa pe ara re ni anabi abi ojise tolorun ran nise bii olutoni sona (bo si pe ara re). Awon ijo musulumi ko jale, won si fi Mirza we oniro, Gege bi mo se salaye lakoko tele, fitina inu esin Islam yi iba ma ti han si gbangba ti ko ba se iranlowo lati odo ijoba orile ede Geesi. Loni won tun wa n ri ati eyin ati iranlowo owo lati odo awon orisirisi ile okeere.

Latara iranlowo naa ni won fi ngbe awon eto ati ipolongo ninu ijo Quadiyaniya.

Pelu bi ti awon ile eko ti po yeleyele to n koni nipa imo ijinle esin Islam ati bi iyapa enu se po to ninu esin, sibe sibe iyapa enu yi ku to irun kankan ninu opo esin Islam.

Nkan meji lo fihan pe ninu esin Islam, a mura wa gege bii omo iya ti a si tun n tesiwaju lati mo itumo awon oro ti anabi muwa.

1) – Pipari Al-Qur’an Majeed gegebi oro tolorun gbe kale fun wa.

2) – IPARI ise Anabi Muhammed (S.A.W) to si je pe oun ni ojise igbeyin tolorun fi ranse siwa.

Ti eeyan ba tapa si nkan mejeeji yi, aga esin Islam ma n wo gege bi ile. Bee ni o di dandan ki eni to je Muhammed (SA) dabi akehinde ninu awon anabi (opin awon anabi) o si tun dabi opo ti ilana esin Islam duro le lori pelu imura eni gege bii omo iya kaakiri agbaye ni awon agbegbe to yi wa ka.

Nitorie lo je pe, gbogbo igba ti awon to n wa ifaseyin ba n gbimo lati satako awon oguna-gbongbo ninu Islam, won ma n bere sii siye meji lori ooto to wa ninu Al-Qur’an, won si ma n foruko anabi Muhammed (SAW) se yeye.

Awon nkan bii atako abi igbogunti bayi ti mo awa musulumi lara to jepe nibikibi ti awon igbogun naa ba ti wa, a ma n mo bi a se koju e. Wahala nla lo ma n tara e jade nigba ti o ba je musulumi kan lo gbogun tiyan gege bi awon ijo Quadiyaniya ti se.

Awon musulumi lee se ki itaje sile (ewu) ma kan won, sugbon ti won ba ri Manafiki (enito foju jo musulumi) ninu won, to n bowa gbogun ti won, ti won ko mo wipe Manafiki ni, o le se won ni jamba gege bi nkan to sele si awon musulumi egbe wa kan.

Nigbati Mirza Ghulam Ahmad da ijo Ahmadiya sile, awon musulumi India wa ninu asiko to le. Awon ojise (asaaju) esin igbagbo si wa lati se ipolongo ati yi pada sinu esin igbagbo.

Bakannaa ni awon ara ile India naa n se ipolongo tiwon ti won si pe ijo naa ni « SHUDHI ».

Latari igbogunti yi, ijoba orile ede Brittain tun n tesiwaju lati ma di awon musulumi lowo.

Lasiko ti igboke-gbodo (fitina) ni Mirza Ghulam Ahmad Quadian jade lojiji. Ninu awon iwe to ko lakoko, ko ko sinu e pe oun loun je anabi ati eni to fe wa so ooto ti won seleri e fawon eeyan.

Won bi mi ni Quadiani ni odun 1914, mo si se kekere mi laarin awon ara ilu mi, mo mo lati ara nkan temi naa n foju mi ri, pupo, ninu awon to wonu ijo Ahmadiya je musulumi ododo ti won si ro pe ijo tawon darapo mo yii, yoo tun nkan se ninu Islam. Ninsin, nigbati ijo yi n lo siwaju ti awon eeyan si tun n po to n dara po mo won, Mirza bere sii fihan awon eeyan diedie to fi je pe loni, igba aromodomo eleeketa ati ekeerin ti Quadian o ri ogbon to n lo lati fi je lori won, to si tun n tan won je. Won o ro pe Mirza Ghulam ti awon baba nla baba re gba bi olutele ofin anabi Ahmad lo wa di anabi Ahmad naa gan-gan lati ori ase ara re.

Lowolowo bayi, won fo agbari fun awon ijo Quadiani ninu igbagbo won, won si gba dajudaju pe ise Mirza Ghulam je asotele ninu esin Islam. Ijo Quadianiya ni igbagbo pe gbogbo eni ti ko ba darapo mo ijo yi, keferi ni. Ninsin, opo ninu won ri pe kii se nkan to dara abi ye ni ki ijo Quadiyaniya kan kirun leyin Imamu Musulumi tabi fun ase lati so yigi. Quadian wa dabi Mecca ti won ma n lo se irinn ajo sile mimo nibe. Pupo ninu awon aaye nibe wa dabi ami olorun gege Qur’an Majeed ti se ma n pe awon aaye kan ni Mecca ni « Sha’air Allah » won si tun ma n pe iyawo ojise yen ni iya awon onigbagbo : Ummul – Mumineen, bi won se ma n pe awon iyawo anabi Muhammed (SAW).

Khalif won keji ni Mirza Basheerubin, Mahmud, omo bibi Mirza Ghulam Ahmad Quadian so wipe ipo ti oun ga ju ti Hadhrat Omar Ibn Khattab, to je Khaleef ekeji ninu

Esin Islam, sibesibe gbogbo eeyan mo pe eni ti ko tele ofin (arufin) keferi ni, ositun je onirinkurin to foju han.

Awon nkan temi naa foju ri ni mo ko sori iwa ibaje ti awon eeyan n lo lati fi ba oye awon eeyan je lo je akoko to si fidi mule saarin awujo Quadiyaniya. Gbogbo nkan ti mo fi tuna asiri ijo Ahmadiya yii, Mo ko sinu iwe kekere kan, mo si te lati fi ranse si Amir awon Quadiyaniya gege bi iwe taa ko to si foju han si gbogbo aye.

A lee ri iwe naa ni awon adress yi :

Maulana Sohail Hassan, 1010 Belmont Road, Tottenham London N 17 680.

Wassalam Alaikum. B.A. Masri,

 

Dr Rashid, Mouvement Anti-Ahmadiyya en Isl

P.O. Bow 11560 Dibba Fujairah U.A.E.

Fax (9719) 2 442846

raseyd@emirates.net.ae

http://-alhafeez.org/rashid am



» تاريخ النشر: 26-11-2009
» تاريخ الحفظ:
» شبكة ضد الإلحاد Anti Atheism
.:: http://www.anti-el7ad.com/site ::.