عرض المقال :Qadiani Hopes Dashed
  الصفحة الرئيسية » مـقـالات الموقـــع » كشف البلية بفضح الأحمدية » Non - Arabic Articles » Yoruba

اسم المقال : Qadiani Hopes Dashed
كاتب المقال: webmaster

Anti Ahmadiyya Movement in Islam

IRETI AWON QADIANI DI OFO

Dr Syed Rashid Ali

Assalam Alaikum,

Opolopo awon Musulumi ni komo nipa ijo awon Qadiani rara, awon ni omolehin enikan to npe ara re ni anabi ohun ni ogbeni Mirza Ghulam ti o lo gbimo po pelu awon kan ti anpe ni British Raj lati fi abuku kan esin Islam nilu India ni asoko odun 19th ati 20th century. Awon ni monafiki ti won npe ara won ni Musulumi. Olori won ti so wipe awa ti a ntele Anobi wa Muhammed (SAW) je keferi. Bakanna ni awon ojogbon Musulumi agbaiye ti panupo pelu orile ede Pakistani wipe awon ijo Qadiani gan ni ki se Musulumi rara.

Nilu Pakistani na awon ijo Qadiani yi lero wipe won tun ma gba won pada si ajo Musulumi lasiko ti Olori ilu na, ti a npe ni Musharraf ti fagi le iwe ofin ilu. Nitori wi pe ijoba Musharraf ko fa ye gba esin Islam bi tatehin wa. Eyi lo muki ijo Qadiani ma lero pe awon ti di Musulumi pada.

Ope ni fun Oluwa, ero awon Qadiani ko wole.

Ijoba so wipe ijo Qadiani kise ijo Musulumi.

Agbenuso fun ijoba ni ojo 24th Feb so pe gbogbo awon toje omo egbe Qadiani ti won pera won ni ijo Ahmadi won ki se Musulumi. Ijoba ko ka won kun Musulumi. Ijoba tun so bakanna pe nkan ti iwe ofin so ni (Ijoba fara mo). Ijoba so wipe ko si iyato ninu ofin ti awon se pelu ofim to wale ni le. Ko si aye fun ijo Qadiani rara ni ilu Pakistan. Won si so pe iro ni oro ta won agbenuso kan so pe Ijoba tuntun kobikita mo nipa Qadiani mo. Gbogbo ikan ti ofin so ni Ijoba faramo. Awon ikan meji ni esin Islam gbagbo. Awon ni Aluquran ati Sunnah Anabi Mohammed (SAW). Gbogbo eniti o ba gba fun Islam ni lati tele ona mejeji na. Eyi to se pataki ju ni wipe a ko gbodo sin nkan miran ayafi Olohun Allah. Eleyi ni idaji akoko ti mususlumi lati gba. Idaji ekeji ni wipe Anobi Mohammed je Ojise Olohun. Awon nkan miran ti Musulumi lati se ati pe ti oni lati gbagbo wa sugbon, awon ti a wi siwaju yi ni o je pataki ju awon oro miran.

Awon elomiran nipa aimokan a ma so eyiti o wun won. A ma so opolopo oro ni ori eleyi ni ojo iwaju, sugbon a so die lori iru awon ijo ti won fi aimokan ko ara won jo gegebi apere –

- Nation of Islam

- The Nation of Gods and Earths (5 Nation of Islam)

- Ijo International Community of Submittes

Awon Ijo Nation of Islam

Awon eleyi pera won ni (Nation of Islam). Won ni igbagbo wipe Olohun kan lowa. Olohun kanna si fi ara han ni abara ogbeni W. Fard Muhammed ni osu July, 1990, ohun ni messiah ti awon omo Christian nreti ohun ni Messiah ti awon omo Christian nreti. Ohun kanna ni Mahdi ti awon ti Musulumi. Sugbon sa, Alukurani, Sura kerin (4) ayat 36 sowipe “Esin Olohun Allah, ki e ma se ba Olohun wa orogun”. Bakana ni hadith Bukhari, “Aisha sope ti eni kan ba so fun yin pe Anabi Muhammed (SWA) ri Oluwa Olohun re, opuro ni onitohun. Nitori pe Olohun Allah so ni Sura kefa (6) ayat 103 wipe kosi oju kan tole ri Olohun”.

Ninu awon nkan ti ijo (Nation of Islam) gbagbo ni igbedide Oku. Ki se igbedide ti ara bi ko se ti emi. Won ni awon ni igbagbo pe iran enia dudu ni won yio jidide ni ti emi. Nitori idi eyi awon ni yio koko dide. Sugbon sa, Alukurani fi da wa loju ni Sura 20 ayat 55 wipe “Lati inu ile ni ati da yin, ninu re ni A o da yin pada si ninu re na ni A o tun gbeyin dide lekan si”. Lehin na Alukurani tun so ni Sura 64 ayat 7 wipe “Awon Alaigbagbo lero pe won koni gbe won dide fun idajo. So fun won pe beni ni Ashe Oluwa mi, A o gbe yin dide. Nigbana ni eyin yio gbo ododo gbogbo nkan ti e gbe ile aiye se. Eleyi si rorun fun Olohun Allah lati se lehin awon nkan meji ti a toka si sehin, awon ijo (Nation of Islam) tun ni igbagbo ninu awon nkan miran yato si ti Islam, eyi ti Alukurani ati Sunna fi ko wa.

Apere eleyi ni nkan ti won so wipe (A wa Musulumi alawo dudu) gbagbo ninu ododo ti o wa ninu Bibeli, bi o ti le je pe won ti da Bibeli ru, awa ni lati se atunse alaye fun awon enia kia won ma ba sina pelu gbogbo modaru towa ninu Bibeli “ Awon abuku to wa ninu igbagbo yi ni pe, Anabi Muhammed ko so pe ki a gba oro Bibeli gbo, ko si lodi si, bakanna Ko si so pe ki a se atunse si oro Bibeli. Awon ijo yi tun so bayi pe “Awa ti a pe ara wa ni Musulumi ododo, akogbodo ko pa ni ogun jija eyi ti o ma gba emi awon enia. Awa ko gbagbo pe won ni lati je wa ni pa lati ko pa ninu awon ogun nitoripe ko si anfani kan kan ninu re ayafi ki Ijoba America ba fun wa ni ile (land) ti o je ti wa eyi ti o le mu ki awa na le ja fun.” Abuku to wa ni nu iru fe igbagbo yi ni pe Alukurani ati Sunnah ti fo oro na si we we, nipa pe ti idi pataki ba wa lati jagun, Musulumi ni lati jagun fun idi pataki.

The Nation of Gods and Earths (5% Nation of Islam)

Ijo yi je eyi ti o ya pa kuro ninu (Nation of Islam) ti a ti soro re wa. Gege bi ti ikeji awon ikan ti won gbagbo ti yato pupo si oro Islam. Ti aba wo awon ikan ti ijo yi gbe dani:- Alakoko, won ni eni akoko je iran alawodudu; ara Asia ni, ohun lo da gbogbo ikan, oun loni aiye ohun baba olaju, olorun gbogbo agbaye.

_ Elekeji Alawodudu gan ni olorun ti oruko re nje Allah, “owo ese ori”.

Gbolohun mejeji yi tako oro Islam, ti o so pe Allah, Olohun ni, Aseda gbogbo ikan. Ninu Alukuraani Olohun Oba sope ohun lo da enia ati gbogbo ikan pata. Nitorina, ko ba oju mu fun enia kan lati pe ara re ni Olohun. Ekeji igbagbo ijo yi fihan wipe aroso ati adada sile ni awon oro na. Eyiti awon ijo yi gbe dani ko ni nkanse pelu Islam. Oga won ti won pe oruko re Yacob, ati enikan ti won pe ni anobi ti oruko re nje W. D. Fard, a ti igbagbo won sori pe awon eniya alawodudu ni o daraju. Sugbon Anabi wa Muhammed (SAW) ti benu ete lu iru oro bayi nipa eleya meya ni oro ikehin ti o so ko to jade laiye ni pa gbolohun yi:-

“Eyin enia mi, Olohun yin, eyo kan soso ni, ati pe baba yin, okan ni (Adam). Gbogbo yin wa lati ebi kan soso ti se Adam. Beni ada Adam lati inu amo kosi ajulo fun omo Arab lori eniti ki se Arab, bakanna, eniti ki ise Arab koju Arab lo. Beni Alawo funfun Ko daraju alawo dudu lo ati pe Alawo dudu ko dara ju alawo funfun lo ayafi ninu iwa mimo ati rere. Nitorina Eni ti odara ju lo ni eniti opaya Olohun”. Fun eniti oba fe mo asiri awon ijo mejeji yi, kio lo ka iwe itan igbesi aiye ogbeni ologbe Malik Al- Shabax (Malcom X).

Ijo Ahmadiyya/Qadiani

Ijo Ahmadiyya ti won dide nilu orilede India labe atilehin ijoba British lo fi igbagbo won ha gege bi eniti benu ete si Islam. Ninu opolopo igbagbo won ni wipe Anabi Mohammed (S.A.W) kise Anobi Ikehin eleyi tio je Okan ninu nkan ti musulumi ni lati gbagbo bakanna ni Quran ati hadith tenu mo oro na ati apapo awon ajogbon ninu Islam.

Quran sura 33 ayat 40 sope:- Eyin enia, Muhammed (S.A.W) koni omo kunrin larin yin, sugbon ohun ni ojise Olohun, ohun si ni igbehin ninu awon Anobi. Atipe Olohun mo ohun gbogbo”. Anabi wa Alaponle Muhammed (S.A.W) sowi pe: Awon Anobi ni ose itosona fun awon omo Israeli. Ti Anabi kan ba papoda, Anobi miran ni yio ropo re sugbon Anobi kan ko ni wa mo lehin mi.

Awon Ahmadiyya je omoleyin enikan ti anpe ni Mirza Ghulam Ahmad omo Qadiani ti oni Anabi ni ohun. O si tokasi awon hadith kan tiko fese mule lati fi yi opolopo oro Alukurani lati fi gbe rare lese sugbon sa, Anabi Muhammad fun rare ti se ikilo:- “Oni asiko kan nbo ti awon opuro bi ogbon (30) (dajjals) eyiti olukaluku yio pe ara won ni Anabi lati odo Olohun (Sahih Bukhari, ati Sahih Muslim). Leyin igba die ti Anabi Muhammad (S.A.W) ku, okunrin kan toje Musailama, lo pe ara re ni anobi. Won si gbe ogun ti pelu awon omo lehin re fun oro iskuso. O je ohun iya lenu lati ri pe ogbeni Musailama ko tako Anabi Muhammad (S.A.W) ati awon omolehin Anabi. O tun je ikan iyalenu pe, iru oro bayi lo tan ara ilu Banu Hunaifa lati gba fun Musailama to pe ara re ni anobi.

Sibesibe, eyi to je apapo ajoro awon saabe (Companions) ni pe isokuso ni ogbeni na so ati wipe won ijo Ahmadiyya ni keferi fun agboye oroyi, eje kalo ka akosile yii:-

“Apere miran to han pe Ahmadiyya ko gba Alukurani ati sunna gbo nipe won ni Jesu ti ku, ati pe Mirza Ghulam Ahmad ni Jesu ti o pa da wa si aiye. Ti a ba tun wo oro to wa ninu Encyclopadia Britanica 1985, Mirza Ghulam Ahmad so pe ki se wipe ohun ni Jesu ni kan, ohun kanna ni Anabi Muhammad, ohun kanna ni Mahammad, ohun kanna ni mahdi, atipe ohun kanna ni Krishna ti se olorun Hindu. Eyi ni la ti mu wa pada si ki esin Islam duro le lori gegebi ije okan Olohun. Bi enikan ba so pe olorun ni ohun, to tun je olorun Hindu, iru eni be ti koja aye re gegebi oro Alukuran. Islam ko fi aye gba iru oro bayi. Ni akotan, Ijo Ahmadiyya ko fara mo Jihad lati le tako agbekale ti Musulumi ko fi fe ijoba amunisin British.

The International Community of Submitters

Awon Ijo olujuraeni sile ti o je omoleyin ologbe Rashid Khalifa, okunrin kan to pe ara re ni ojise Olohun. Awon oro ti o dimu to ohun ti won ni lati yo kuro ninu ijo Islam. Nitori Oro Alukurani sura 33 aya 40 pe: “Eyin enia, Muhammad koni omokunrin larin yin sugbon ohun ni Anobi, Ojise Olohun ohun si ni Igbehin ati opin awon Anabi. Olohun si mo ohun gbogbo.

Anabi Muhammed (S.A.W) ti se ikilo fun Musulumi ki won ma se jin sinu ofin iru awon ijo bayi. Abu Rafi logba Hadith na wa to so wipe Anabi ni “Ma se je ki ri ikan ninu yi ki o ma fi idi rin le ninu ikan ti mo pa lase tabi lewo fun yin (ninu Sunnah Anabi Muhammad ) o si so bayi pe, gbogbo ikan ti a ri ninu iwe Olohun ni a ni lati tele ( Book 40, Number 4558 of Sunnah Abu Dawud).

Bakanna ni Anabi Muhammad (S.W.A) sope iran omo Israeli, awon Anabi ni ojise won. “Nigba ti anobi kan ba papoda, Anobi miran o ma ropo sugbon lehin mi kosi Anobi miran mo ayafi khalifa ni yi o ma ropo mi” (Sahih Bukhari).

Opolopo isina ti ogben Rashid khalifa mu ba awon eniyan ni a ri nitori pe onfe agbara to fe ma lo. Irufe nkan bayi ti mu opolopo enia sina lati gba pipe. Ogbeni Khalifa sope Alukurani kun fun asiri ti oromo mokandinlogun (19). Eleyi je ki won yo ayatmeji kuro ninu Alukurani ki o ba le ma lo fun ikan miran yato si Islam, ayat kansoso kuro ninu alukurani ti je ki ijo yi lodi si Alukuriani sura 2 aya 85 to so wipe:-Se iwo gba apa kan kurani gbo ti o si tako a pa kan bi ? kini idajo iru eni be bi kise abuku ile aiye ati ti Alikiyaoma nibiti a o ti ju won si nu iya to tobi ju lo.

A tun ri ninu iwa ogbeni khalifa-enikan ti ma lo agbara imo ikoko nkan ti yio sele lola. O so asotele igbati aiye yio pare. Sugbon Olohun so ninu Alukuriani sura 7 ayat 187 pe:-“Ti won ba bere lowo re nipa imo asiko na, igbawo ni yi o de? So fun won pe imo asiko na wa lodo Olohun mi. Ko si enikan ayafi Olohun nikan ni O mo asiko na. Ni ojo na, aiye ati orun yio mi titi lojiji ni asiko na yio de. Tiwon ba be re igbawo, so pe imo na wa lodo Olohun!!

Awon ijo ijuraenisile (Submitters) ko gba sunnah Anabi Mohammed (S.A.W) gbogbo rara. Ki se pe won gba apakan gbo, ti won ko gba apakeji, gbogbo sunnah Anabi ni won ko gba. Loju won, Sunnah ki se ona ti Islam. Abuku to wa ninu oro yi ni pe, awon ijo yi ba gbogbo opo islam je pata pata. Nitori pe won ko nile kirun eyi tio je opo keji Islam, bakanna, won ko le yan zaka to je opo keta won ko le gba awe to je opo kerin bakanna irin ajo hajj to je karun, awon ijo yi ko ni le se won ni gbati won tako sunnah Anobi.

Niwon igbati won ti kuna ni merin ninu opo marun, eyi ti fi han wipe awon ijo na ko le pe ra won ni Musulumi.

Anti Movement Ahmadiyya en Islam

Dr. SEYD RASHID ALI

P.O. BOX 11560

DIBBA Al FUJAIRAH, United Arab Emirates

Fax : 00971 9 2 442846

rayed@emirates. net.ae http://alhafeez.org/rashid/

اضيف بواسطة :   admin       رتبته (   الادارة )
التقييم: 0 /5 ( 0 صوت )

تاريخ الاضافة: 26-11-2009

الزوار: 2062


المقالات المتشابهة
المقال السابقة
AlFatwa No 8
المقالات المتشابهة
Qadianis Hopes Dashed
Qadianis Hopes Dashed
المقال التالية
Knowledge of Mirza Ghulam Ahmad Qadiani
جديد قسم مـقـالات الموقـــع
القائمة الرئيسية
البحث
البحث في
القائمة البريدية

اشتراك

الغاء الاشتراك