:Fatwa 29
  Non - Arabic Articles Yoruba

: Fatwa 29
: webmaster
n>  to yato si esin Islam lesa awon Hindous leniti nfenu ate jewon latile firan siwon. Awon apejuwe melo kan re :

« Eleyi nise atipe awon eniyan wonyi ni opuro, esin nwon, igbagbo nwon, Olohun nwon ati Baagwan je awon eye ile aiye lasan abi igberaga lasan, abi orilede nwon abi eya nwon ….. nipa bee tani yo pe nwon ni Pundit ji, Guruji ati Swami ji ? (Braheen Ahmadiyya Apakini Roohan Khazain, Vol 1 p 107) »

« Egbe awo tuntun yi to wa latilu Inde ti nwon si npepade esin nwon ni Arya Samaj, awon ojo re, asaaju nwon, niti paapa oludasile egbe awo yi ni ogbeni kan ti nje Pundit Saheb ti itumo oruko re nje Diyamand. Gbogbo awon ede awo re ati asayan oro ti egbe awo yi da sile tori Vedas,kosi ninu esin abalaye Hindous abi ninu apapo awon asayan oro ati ede awo toti wa tele. Awon kan ninu re je ero tie fun rare »

(Braheen Ahmadiyya, Roohani Khazain Vol 1 p 72)

            « Nisisiyin ire Arya ! mo ba e yo ! Gbogbo ododo jeti Olohun nyin Permeshuwar latara ijeri Pundit Diyamand fun rare. O han wipe Olohun nyin Permeshwar je ara kan to tobi ti nma subu sori ile kan gegebi awon emi yoku o si see je gegebi awon eweko. Nidi eyi ni ma fi ndi Remchander nigbamiran atipe nigbamiran a ma di khrisna ati Much. Atipe nigbakan, o wa lori aworan elede ti nba awon to wa woran re sere leniti nje ounje pataki (imi, igbe). » (Roohani Khazain vol 2 p 395)

            « Permeshwar farajo awon omo nika mewewa labe okun idodo, awon onilàkaye loye »  (Roohani Khazain vol p 114)

            Awon oro ote, ifiran lowa ninu Braheen Ahmadiyya. Elesin Krist abi Hindou kan ko le ka oro yi ki ara ma taa. Awon oro tutu nbe tole fi salaye awon nkan wonyi to fi oro kobakungbe, oro ibanuje won yi so . Iru isokuso Mirza yi da ikorira inunibini ti koni ipekun sokan awon elesin Krist ati awon Hindous si awon musulumi.

            « Mirza Saheb dojuko awon Hindous ati awon omobirin nwon buwon tara ninu awon orisirisi ipele atejade iwe Braheen ati ninu awon atejade iwe to je ti ipolongotiijo Ahmadiyya npin kakiri. Ni oju awe kokandilogun ti iwe re « Shahna-e-Haq » owi bayi : « Eyin ko lati fa awon omobirin nyin fun mi fe laya nitoripe eyin nsewadi oro mi » Ninu iwe re, « Surman Chasme Arya », o soro buburu si awon omobirin Arya, osi bu awon orisa nwon. Lafikun o fi imisi re deruba awon Hindous. Iru awon atejade bayi lo moju awon Hindous ranko, gbona eje nwon, gbingi oro aïnipekun sokan nwon » (Asha’at Us Sunnah vol 18 p 14).

            Pandit Lekhram Pershwari ti Ahmadiyya, o wi bayi ninu iwe re ti akole re nje : « Takzeeb Braheen ».

            « Mirza Saheb kede wipe gbogbo eniti ki nbase musulumi ododo to ba ri awon eri ododo fi satako iwe Braheen Ahmadiyya oun yio fun-un ni 10.000 R. Pandit Lekhram ko iwe atako yi lori akole : (Takzeeb Braheen). Akojo eebu ti-i doju tini oro kobakungbe oro ibanuje lo fi fesi ninu iwe yi. Oun o ro wipe latijoti  Olohun ti da aiye ti awon eniyan ti nsemi ninu      re, enikan ti koja ala ninu isokuso si awon ojise abi awon enito sumo Olohun tobi Pandit se soro si Mirza Ghulam ninu iwe re. Bi eniyan ba fi emi ododo ati isedeede sagbeyewo oro yi yio han si-i kedere wipe Mirza ghulam Ahmad Saheb lo firan si Pandit, owun lo fa a lahan jade lofi koja ala ninu isokuso si esin Islam ati awon ojise Olohun ».

IWE TI PANDIT LEKHRAM KO SI MIRZA

            Ni 24 Juin 1893, Pandit Lekhram kowe si Mirza Ghulam Ahmad bayi wipe :

            « Bi oba jewipe akoogba ni enito ba kowe tako Braheen, nje eyin ni alakoko alaïdara. Nitoripe gegebi oro AL-Qur’an, eti salaïmore (kufr) si olohun, eyin le koko firan siwa, nitori eyi lafi fesi. Bi ki-i ba seyin lekoko firan siwa ni Permeshwar o daju wipe awa koni aniyan atikowe tako esin Islam. Bayi, bi o ba sewipe ohun ti Olohun ko fe ni, nje ile nyin ni ibinu arami yio koko sokale si ni Qadian. Bi oba sewipe mo ngbija arami ni, aïdara ni mo se, ibawi Olohun yio sima bami.

Ikede Mirza to so powun fe pate atifi agbara iseyanu towun han saiye-Nje awon

aranse Olohun se bee ?

            Latara pipin atejade iwe re Braheen Ahmadiyya kakiri aiye, Mirza Saheeb ro wipe awon mutumuwa nwon yio ma kokiki ise iyanu towun kakiri gbogbo agbaiye. Sugbon igida oro ko ribee ! o barare ni eniti ko gba oriyin kankan. Awon atat onimo ijinle nipa esin Islam so wipe kéféri (alaïmore) ni Mirza lehin iforo Jomitoro oro nwon.Mirza yi awon ilana re pada. Ero re ni kio fiseyanu re yi fi ko awon eniyan laya je. Ohun ti npe ni agbara atodolohun wa owun na ni iseyanu abi idan.

            Ni odun 1885, o se ipolongo kan to si pin egbegberu atejade iwe re fun awon Anglais ati awon Urdu.

            O fi npe awon asaaju elesin to yato si Islam ati awon asaaju esin Islam wipe ki nwon wa wo iseyanu towun.

            Bi eyin ba nseyemeji lori ododo esin Islam ati awon ami olohun e wa si Qadian gegebi oluwadi ododo ki e si rerayin sile fun odun kan eyin yio fi oju arayin ri awon ami wonyi. Sugbon pelu majemu wipe (ki aniyan nyin je ti oluwadi ododo) atipe lehin igbati e ba ri awon ami yi, eyin yio kede wiwonu esin Islam nyin, eyin yio si so amikan ti eri. Bi e ba wa pelu aniyan yi, daju daju eyin yio ri ami Olohun yi. Olohun loti sadewun yi, kosi iyemeji nibe »

            « Ero wipe ki nsiseyanu yi ki-i sero okan temi funrami bi kosepe Olohun alagbara julo lo pami lase re. Atipe asotele iro idunu yi ni wipe awon ti iwe yi ba te lowo nwon yio dake teriba »

            « Bi eyin ba wa ti e ko ri ami kankan lati odo Olohun lehin odun kan ti e lo, awa yio fun nyin ni 200 Rs fun osu kookan gegebi owo atunse abi gba mabinu ».

            Mimo fun Olohun o ! iru eemi wo leyi latile fi agbara Olohun han. Taani enito le wa odidi odun kan ni Qadian aroko ti Olohun ti binu si pelu Mirza, ki o gbagbe igbesi aiye re ati ebi re fun odidi odun kan nitori awon ami to ruju ti enikankan ko mo igbati awon ami yi yio yo lati owo Mirza ?

            atipe iru iwa jamba wo ni majemu re to da fun enito fe ri ami Olohun yi wipe ki o ni aniyan to dara (aniyan oluwadi ododo) ? Bi enikan ko bari awon ami Olohun yi, bayi mirza yio so wipe koni aniyan oluwadi ododo ni.

Ojise Olohun lododo ni iwa alaponle ninu awon isele bawonyi

            Nje Akehinde, ipekun awon ojise Olohun, Annabi Muhammad (SAW) da iru awon majemu bawonyi fun awon kuffar Mecca ?

            Nje Annabi toro lodo nwon wipe ki nwon bawun gbe reti ami Olohun kan to ruju siwon fun odidi odun kan lalaïkomogba ti yio sele pato ? Rara o, ko ri bee. Nigbati awon kuffar Mecca toro lodo re wipe ko siseyanu kan fun awon, Annabi ko seyemeji, kosi da majemu kankan fun nwon, kosi fun nwon lakoko kan. Lesekese lo fi osupa han nwon  ti osi pin si meji logbogba. Irawo nla olori awon irawo pin si meji, leyiti awon oluworan yi ri-i kedere bayi wipe ipinkan osupa yi wa lori apata nla kan, ipin keji wa lori apata nla keji loto (ewo Sahih Bukhari). Kafir kan toro lodo Annabi (SAW) wipe ki awon okuta wewe soro lowo Annabi. Lesekese, ni Annabi (SAW) sa awon okuta wewe sowo ni nwon njeri wipe Oba bi Olohun kosi atipe ojise Olohun ni Annabi Muhammad (SAW) ti Kafir na ngbo-o ketekete. Ko da majemu kankan siwaju, beeni ko da akoko kan, kosi se adayanri aniyan dara dara koto da a lohun. Ise ti afi ran-an ni kio fi ododo han awon eniyan, biwon ba gba biwon ko ba gba. Iyen ni edun okan re to gaju nitoripe Olohun ni olufinimona.

            Eleyi ni iwa rere, iwa aponle, iwa iteriba ipekun awon ojise Olohun.

            Ituno ohun ti a npe niseyanu owun ni ohun ti nkagara ba eniyan, ohun ti o ju lakaye awon eniyan lo, sise re naa koja agbara gbogbo mutumuwa. Pelu ase oba alagbara julo, oba ati oludari ile aiye, awon iseyanu wonyi a ma sele lati owo awon anigbagbo ododo wonyi latifi ola ati iyi awon ojise wonyi fi han wipe lododo olohun oba to ranwon nise nbe pelu nwon. Oba to seto ile aiye alagbara giga alase alewi lese lori ohungbogbo. Lesekese ni awonyi ri bee latile mu awon olugbagbo ododo teriba fun Olohun atipe ki igbagbo awon ti nwon gba awon ojise gbo le lekun.

            Oro kan pataki to tun ye ka ranrawa leti re nipe ojise kankan ko fi iseyanu re fi gberaga, owun yio fi awon eniyan sile ki nwon ma so – o.

            Towun -tibe, awon iwa opuro yi yato pata - pata si tawon ojise Olohun. Awon olukawe wa yio ri-i ka ninu awon oju ewe ti nbowayi :

            Iwe ti pandit lekhram ko si Mirza Ghulam.

            Lesekese ti pandit ri ikede naa, lakaye re so fun –un wipe ko siso lori iro ohun ti mirza nperare. Gbogbo igba ninu re fi nbaje lori ona ti mirza gba yepere esin hindoue ati awon iwe won osi ri ona satako gbarare sile. O kowe si-mirza  lati salaye fun- un wipe owun yio wa gbe Qadian :

            « Mo ka iwe nyin ti e pin kakiri ileroyin ti murtazai ti lahore ninu eyiti olohun payin lase wipe gbogbo eniti ki nba se musulumi to ba wa silu Qadian lodo nyin fun odun kan ti ko ri ami Olohun kankan ti ko di musulumi kori itelorun, eyin yio fun-un ni 200 Rs ni osoosu gegebi gbamabinu abi owo atunse. Lati wadi ami Olohun, mo gbaradi lati wa sodo nyin pelu majemu wipe ki emasan 200Rs fun ni osoosu, ki e lo da 2400Rs sile ifowopamo ti ijoba funmi nitori aboto peye. At ipe ki e pinu lori majemu wipe bi owun kosi gba esin Islam lehin odun kan ti mo fi gbabe nyin, lehin ami olohun kan ati awon iseyanu, tobaribee eyin koni ko 2400Rs naa fun mi. Fun odun kan owo yi yo wa nile  ifowopamo ijoba, eyin kosi gbodo gba a. Mo gba lati di omo akeko nyin fun odun kan »

(Iwe Mirza Ghulam ti 3 Avril 1885, to wa ninu Raees-e- Qadian latowo Rafiq Dilawari, p 163)

Esi ti Mirza Ghulam fun Pandit – Awon majemu ti ko to

            Inu bi Mirza Ghulam gidi nigbati o ri esi ti Pandit Lekhram fun un Eleyi ni ilana re ti ma nto, a ma gbiyanju latifi Pandit Lekhram ha senu panpe oro ki o fi korareyo lowo Pandit. Owi bayi ninu akosile re :

            « Ninu atejade iwe mi, awon olumo eni aponle awon asaaju ijo ni oro mi nbawi, awon to sewipe gbigba tiwon yio ko ipalara ba opo eniyan. Sungbon eyin kosi ninu awon eleyen ti oro mi nbawi, toba sewipe ero mi kose deede to jewipe eyin ni asaaju ijo nyin loni, toba ribee o daraju, emi ki yio dayin lamu pupo.

            E pe gbogbo awon asaaju ijo mararun, Arya Samaj Qadian, Arya Samaj Lahore, Aeya Samaj Am ritsar, Arya Samaj Ludhiana, Arya Samaj Reshawar, gbogbo awon ijo wonyi ni nwon gbodo bura lori wipe Pandit Lekhram ni asaaju oludari wa, ti nwon ba gba majemu yi, nwon yio ri awon ami melo kan, gbogbo nwon yio si gba esin Islam kia-kia. Eniyan yepere ti ko leto wipe ka jojo ma foroJomitoro oro ni oun o kayin kun ti e koba le parapo sasaro pelu ijo mararun kie mu ipinu kan to yanju wa fun mi ni nkan bi ose meji si akoko ti awa yi.

Esi ti Pandit Lehram fun-un

            « Owe yi lo bayi : « ohun ipate ni eyin eri, ki-i sohun jije » Mo ro wipe eyin yio mu adewun nyin se gegebi akosile nyin ninu atejade nyin, sugbon mo tanrami ni, oro ko ribee. Imoran nyin tie gbe jade simi wipe ki awon ijo Arya Samaj mararun gbami ni asaaju ati oludari nwon, fi han wipe ododo ni oro owe ti nso bayi wipe : « ki-i ba ologbon ewe kio ma riwi » bawo ni awon omolehin Arya Samaj mararun se le tewogba esin Islam lori ijeni nipa bura fi gbami lasaaju oludari nwon ?

            Seyin fe di omolehin Arya ni ? Sawon omoyayin, awon onbi nyin ati gbogbo musulumi Qadian yoku nwon yio darapo mo esin Arya ni ? Laye-laye oro kole ribee. Mirza Saheb ! Gbogbo awon aba nyin ti koni itumo kankan ko ba eniyan losi ebute rere kan bikose ona iruju. Bi eyin ba darapo mo esin Arya, lehin opolopo iwadi ti e se, eleyi yio ma je awijare to daju wipe esin ododo ni Arya. Beena nidakeji ki awon Arya Samaj di musulumi ododo nitorimi yio je eri to fojuhan ninu iseyanu esin Islam. Latigbati aso ti si lori iro nyin latara awon Arya Samaj ti Qadian, mori wipe oun o puro tanrami lori oro ti mo so bayi wipe : « Aïpe ori ni kia dan eniyan wo ! Towun tibee, e moomo sa latise nkankan leniti nyera fun ibere » (Iwe ti Pandit kosi Mirza Ghulam ni 9 Avril 1885 eyiti akosile re nbe ninu Raees-e-Qadian latowo Rafiq Dialawani p 164)

Awawi miran latenu Mirza Ghulam

            « Awon olola eniyan ni a fi owo 200Rs yi lele fun. Bi mo ba fi 200Rs lele fun gbogbo eniyan, nibo ni oun o tiri owo nla to bee ? Bi  eyin ba ri ebun iru owo yi nibomiran o temilorun. E fiyemi wipe eni pataki bee nbe ni odo nyin... odi oroyan funyin latiwa si Quadian ki ero yen ba le kuro lokan nyin atipe ki e le ri aridaju.» (Iwe Mirza Ghulam si Pandit ni 16 Avril 1885 ninu akosile iwe Raees-e-Qadian lati owo Rafiq Dialawarip 163)

Asotenumo Lekhram

            « Mirza Saheb ! Itumo ikede nyin akoko ko yewa rara lopin igbati iwe nyin ti 7 Avril nsoro to yato si iwe nyin ti 16 Avril. Eleyi fi han wipe oro nyin ntakorawon. Ebe ti mo tun nbeyin nipe bi adewun nyin ba jododo, ti eyin je olusododo, oluwadi ona ododo, to jewipe Oluwa sayin lesa latifi gbogbo mutumuwa mona ododo,e lo fi 2400 Rs owo odun kan sile fowopamo ijoba ko ma je 200 Rs ni osoosu fun oluwadi otito iseyanu nyin.

            E fun mi ni aridaju wipe bi emi koba ri itelorun ti nko gba esin Islam lehin odun kan labe tito nyin, ti nkori awon ami Olohun ati iseyanu, nje eyin yio gbe 2400 Rs naa funmi atipe fun odidi odun kan ni owo naa yio fiwa nile ifowopamo ti ijoba. Lopin igbati ojewipe Olohun lo sayin lesa lododo, kilode ti eyin nko latipe iru adewun bayi ! ti e nko iru owobayi lati san ? Nigbati o jewipe ki-i se kia-kia, lesekese ni ododo naa yio sele, ti eyin si ni igbagbo ododo si awon iseyanu nyin ko to ki eyin sa lati mu adewun nyin se. Bi o ba je ododo ni ikede ati ipolongo nyin wipe Olohun fi han yin wipe owun  sayin lesa seyin lojise re ajewipe eyin gan ti gberayin sori ate polongo arayin sekarimi ninu opolopo isele, eyi koni je ki ndake teriba gba awon ohun ti e nperayin. Olohun sadewun funyin, Nisisinyi eyin funrayin ko gba-a gbo. Bawo latile gba wipe ako gbodo so-o felomiran nigbati eyin funrayin koni igbagbo to rinle si-i. Gbogbo awon awawi nyin ti efe fi pari fanfa edekoyede ati ikede nyin wipe nigbati orun ba bere si-i yo nibiwo re, e o san owo yi. Eleyi yo farajo abuku funru onilakaye bi-i tiyin. Nitoripe eyin ki npe adewun ni awon omolehin Arya kankan kose fe wa sodo nyin mo. Mo ko-o ni akotunko ni opolopo iba wipe emi funrami yanrami latile sewadi ododo agbara iseyanu nyin. Mo gba lati je omo akeko nyin ati wiwa bayin gbe Qadian fun odidi odun kan. Niwonba akoko yi, ti eyin ba tun ye adewun yi, koni si anfani ninu ikowe sirawa mo » (iwe Mirza Ghulam ti 30 Avril 1885, ti akosile re nbe ninu Raees-e-Qadian latowo Rafiq Dialawari p 164)

Mirza fesi bayi – Mo fi majemu kan kun-un

            Nigbati Mirza mo daju wipe Lekhram koni kuro nilu re wasi Qadian lalaïkosi ipinu kankan lori oro owo yen, o pada gba beebe wipe owun yio gbe owo yi kale pelu ifi majemu tundun lele :

            « Nidakan, eniyan pataki yi yio gbe 2400 Rs kale, midakeji eyin naa yio gbe 2400Rs kale sile itaja Muhajin (Muhajin je onile itaja kan ni awon aroko, a ma ya awon eniyan lowo pelu gbigba ere lori oju owo nigbati nwon ba fe san-an pada, eyi yio je ibawi fun kiko ti eyin ko lati gba esin Islam, ko ma je ohun iranti fun eniti Olohun ba gbe isegun fu. » (iwe Mirza Ghulam ti 17 Avril 1885 ninu akosile Raees-e-Qadian latowo Rafiq Dilawari p 163)

Esi Pandit Lekhram     

« Ipile ikowe sirawa ni ikede nyin ti e funka nilese iwe iroyin ti Murtazai nilu Lahore ni eyi ti e so pato wipe Olohun payin lase wipe ki e ma pe awon eniyan sinu esin Islam. Enikeni tobawa bawon gbe Qadian fun odidi odun kan atipe lehin igbati o ba ri ami Olohun ati iseyanu, ti kosi gba esin Islam, yin yio fun-un ni owo atunse gbamabinu ti nje 200 Rs fun osu kookan, ohun ti nje 2400 Rs fun odun kan. Nisisinyi, e titun gbe majemu miran jade…… Omoyami owonjulo ! Eese ti eyin nye adewun ti e se funrayin atipe kilode ti e kofe se deede ? Nje ilana awon oluberu Olohun leyi ? Nisisinyi, ni e sese kede wipe ohun ti e so siwaju eti ko-o je. Ki e to se ikede iseyanu nyin, eti gbodo darayin loju wipe eyin yio siseyanu yi leyiti yio lapa lara eniti o ba ri-i-ti yio gba esin Islam lehin re daju-daju. Itumo iseyanu lododo ni ohun ti nkagara ba awon eniyan. Nigbati alatako eni koba kagara teriba gba fun-un, akoni ka-a kun iseyanu. Eyi nipe eyin funrayin nseyemeji siseyanu nyin, wipe Lekhram koni gaagbo. Nidi eyi ni eyin fi nda majemu tuntun loni. Towun tibe, latile muse ya : « mo loba opura nile re » mo gbaradi lati gba majemu tuntun yi leniti nfi 2400 Rs lele. » (Iwe Mirza Ghulam ti 20 Juillet 1885, to lakosile ninu Raees-e-Qadian latowo Rafiq Dilawari p 168)

Lehin gbigba majemu tuntun yi wole, Lekhram kowe si Mirza Ghulam leniti nso bayi:

“Mo nseyemeji siyin e salaye ami Olohun naa funmi, e so ojo ati osu ati odun ti eyin yio fi han wa ki awa le mo-o siwaju.“ (Iwe Mirza Ghulam ti 20 Juillet 1885, to wa ninu akosile Raees-e-Quadian latowo Rafiq Dilawari p 168).

 

            Awon ogbon ewe ti Mirza nda latile bo lowo Lekhram

            « Emi ko le da awon majemu miran latile se ikini keji iseyanu naa han nyin. Nje mole fiseyanu naa han nyin bi ? Emi ko mo ohun ti yio wa sele ? Emi ko je nkankan yato si iranse Olohun. » Emi ko mo ami ti olohun yio fi han wa. Mo mo wipe ami yi yio ju agbara eniyan lo. Olohun yio fi ami ti yio da awon mutumuwa lagara han. Majemu naa ni kie fun esi wipe beeni mole siseyanu abi beeko mi kole siseyanu. Awon oludajo naa koni si ninu esin enikankan ninu awa mejeji, sugbon ni ona meji ni ao ti yan nwon… » (Iwe Mirza Ghulam ti akosile re wa ninu Raees-e-Qadian latowo Rafiq Dilawari p 170)

            Lekhram ntopipin laïfin Mirza Ghulam

            « Nigbati o wunyin wipe ki awon ijo alatako mejeji fi owo lele koba dara ki eti fi sinu akosile ikede nyin takoko gegebi olutayo meji ti-i ma fowo lele fun idije, e kole yi awon majemu naa da, be sini eko gbodo pawonre. Bi kosepe iruju wa ninu akosile nyin ni, koda eniti koni lakaye pipo koni damu jina koto gboyin ye, yato si awon idamu ti nkoju mi latara ikowe siyin. Awijare ti ko fi si igbagbo fun adewun nyin, owun ni ifunnu nyin ti ko fese rinle ati awon ohun ti e koje ti eyin nperayin. Otito nipe eyin lu agogo enu nyin fi se ipolongo latile fi soro aje nyin. Idi niyen ti mo fini kie lo fi owo yen pamo.

            Sile ifowopamo ti ijoba. Eyin jebi bi eba ro wipe pelu awon majemu buburu nyin enikankan koni fe hararemo Qadian fun odidi odun kan laarin awon agbe ati awon alaïmokan, atipe lafikun bi enikan koba fun esi, Nwon yio gba awon aba iro ohun ti eyin ko je ti e nperayin. Towun tibi mo se dide latile siso lori awon iro nyin nitori awon idi pataki ti moti salaye nwon siwaju, awon eniyan ti gbiyanju lati gboriyin funmi. Etun sese  ronu gbe ogbon ewe miran jade latifi satako ikede nyin.

            Leniti nso bayi : « Eyin ni ikansoso iranse ti Olohun yan. »  Ohun ti e ko sori awon ila meji akoko to je ti iwe ikede nyin fi ododo iranse Olohun ti e nperayin han, ati kiko ti e ko oruko eni aponle Hazart Eisa, e fi arayin we-e niyen. Kosi laïfin nibi kata awon eni aponle onimo ijinle ninu esin Islam ji. Nitori gegebi orun lo han si gbogbo awon musulumi wipe Hazrat (Muhammad) ni ipekun awon ojise. Kilode ti igbimo nla to jeti asofin esin Islam fi gbe oro ibawi soke fun iru eni bee ? Nitoripe anseni lode koto tile, ehinkunle lota wa inu ile laseni ngbe. Njeeyin sowipe eko mo ami ti Olohun yio fi hanwa ? Idi pataki ti olohun tori re sayin lesa fun ise pataki. Kilode ti eyin ko mo awon asiri ise nyin siwajue ? Nigbati eyin ko mo orisi ami ti Olohun yo fi han wa, kilode ti e kede ami olohun lalaïko gba iyonda lodo Olohun ? Nigbati eyin ko gba Bissimillah gbo ninu imisi nyin, kilefe wa rise ? O han wipe latara aïmokan nyin, sisayin lesa funse pataki gegebi iranse ki-i se ati odo Olohun, oba olumo ikoko ati gbangba. Eleyi ni ibukun Satani. Mo toro lodo nyin wipe ki e fi awon ami ti o ju agbara awon eniyan lo han wa, A ko bere juyen lo. Siwaju eti ye-e- sugbon nisisinyi eko apakan awon oro nyin je, latibi ami Olohun e wa gba ami keji, e fi ami yi naa suwa loju nitori e ko mo bi yio tiri.

            O han porogodo wipe aba nikan nyin nda kole jokuta iro nyin po. E kan tie polongo arayin lasan. Lehin igbati e tewo gba gbogbo iwonyi emi ko mo okunfa ti e fi nda majemu yi, ti e fi nbere wipe ki nmukan ninu bee ni, beeko, ao yan awon oludajo, lotito bi aba ngbe oro kan yewo ti iyemeji si wa ninu apakan oro yi, ani latiri awon oludajo ni. Sugbon lopin igbati awon mutumuwa koni imo ikoko, nwon nbe ninu okunkun awon isele niyen. Bi eyin naa bawa ninu okunkun iseyanu nyin, yio dara wipe ki e sise yanu nyin niwaju awon oluso  awon ewure, e darijiwa. Kaka ki a ma wo iseyanu ti e nfi ifunnu se, o dara funwa kia gbele wa » (Iwe Mirza Ghulam ti 5 Août 1885, ti o wa ninu Raees-e-Qadian latowo Rafiq Dilawari p 171 172)

Mirza toro lodo Pandit wipe ki o wa si Qadian ki awon fi suru ati ife to oro naa

            « Agara da Mirza tenu-tenu, oro pesije fonilakaye. Lehin osu meta, Pandit fiwe ranse si Mirza fun iranti. Esi ti Mirza fun-un nipe Qadian ko jina tobo se lero re. Ewa pade mi, pelu ireti wipe ao fipinu sinu awon majemu naa. »

(Takzeeb Braheen Ahmadiyya latowo Rafiq Dilawari p 171 – 172)

            Oju osu marun lo ti Pandit ati Mirza Saheb fi nkowe sirawon, ti awon oriran riran iwe iroyin Punjab fi npi kakiri, gegebi Aaftaab Punjab, kohinur ati bee-bee lo (Takzeeb Braheen Ahmadiyya, latowo Pandit Lekhram, ninu iwe Raees-e-adian latowo Rafiq Dilawari p 171 – 172)

            Latigbati Mirza Saheb tiri itiju ninu ikowe sira eni laarin awon mejeji, akotun ri oripa ikowe sira eni naa ninu iwe Ahmadiyya mo. Loju aiye Mirza Saheb ni nwon ti pin iwe Takzeeb Ahmadiyya ati Zameena kakiri. Oka a owa nrahun desun awon oro kobakungbe, awon oro ti ko barawon mu ti olo sinu pupo ninu awon iwe re Mirza Saheb kole le ko nigbati nwon npolongo ikowe sira eni laarin nwon ninu Zameena de Takzeeb.

Pandit Lekhram ni ilu Qadian

            Lehin igbati Pandit gbawe ipe, kia-kia ni Pandit lo dahun latile fi ipinu sori awon majemu ilana naa. Leekan si-i Mirza gbiyanju latiri wipe owun ye ipade yi. O se pupo ti Pandit jafafa, emu ni Pandit ki-i mu nkan ti lagbede. O lemo-o tipe-tipe bi ema agbo. Towun tibee Mirza gbiyanju lati bolowo Pandit. Pandit enito sise ijoba ninu awon olopa fun odun gboro ko fi Mirza lorun sile. Lojo ojokan Pandit joko ti Mirza Ghulam nile Mirza latile fi ipinu sinu awon smajemu ti owun yio fi wa si Qadian fi wo ami Olohun naa. Ninu iforoJomitoro-oro, gbolohun « Khawariq-e-Aadaat »  yo sinu fanfa naa. Pandit so bayi wipe: « yiyi eto aiye pada » Ase ti Olohun fun obe ni ko ma ge nkan, ase ina ni koma jo gbogbo nkan, ase igi ni ko fese mule. Toba jewipe pelu olohun, e le yo ase gige nkan kuro lara obe, ki e yo ase jijo nkan kuro lara ina, kie fun igi lase ko ma kiri, to ba ribe emi yio di musulumi lesekese. Bi eyin ko ba le siseyanu iru eyi, e o di omolehin Arya, ki e simi ifenu rofo, agada owo dun be gedu afenu wako ki-i jaamu. »

            Mirza Saheb so bayi

            « Itumo Mau’jiza (iseyanu) koniyen ninu AL-Qur’an »

            Pandit fesi wipe :

            « Nigbati gbolohun yi kosi ninu AL-Qur’an, bawo ni awa sele mu eri ninu AL-Qur’an fi dahun oro yi ? »

            Mirza Saheb ntenumo-o wipe gbolohun yi wa ninu AL-Qur’an Pandit Lekhram gbe AL-Qur’an fun Mirza wipe : ko dakun jowo ki o fi gbolohun Mau’jizah fi han owun ninu AL-Qur’an. (otito nipe gbolohun yi kosi ninu akojo gbolohun AL-Qur’an)

Mirza Saheb wa gbolohun yi ninu gbogbo oju ewe Al-Qur’an fun iseju melo kan. Kori nkankan to jo-o. Nigbanaa owa ri mo daju leniti njewo so bayi : « Mo ko oro mi je, gbolohun yi kosi ninu Al-Qur’an Pandit Lekhram so ninu iwe re bayi wipe lakoko yi Hakeen Kitten All, ALA Inhale Chained, Pandit Jai kitten, Ala Saheb, omo egban abi aburo Mirza Saheb, Mirza Kamaluddin, Mnice Ali ati arugbo onirin ajo kan nwon wa nijoko ti nwon renkan wipe ki Mirza mase pe isele yi niro ».

(Takzeeb Braheen-e-Ahmadiyya latowo Pandit Lekhram p 86 o wa ninu Raees-e-Qadian latowo Rafique Dilawarin p 172 – 173)

Awon ibura, igbera eni sepe Pandit Lekhram ati awon itiju ti Mirza ri.

Pandit se iwonba to lese nitori ki Ilihaami Saheb (Mirza) ma se sa mo. Ki o gba awon majemu ti a pinu lori re lati fiwa gbe Qadian fun iwonba odun kan. Igida ti Pandit ko le yi Mirza Lokan pada. Nigbati osu-u, o simi gbogbo ariyanjiyan lori awon majemu lilo gbe Qadian fun odun kan. Dipo eleyen o toro lowo Mirza wipe ki a siseyanu ki owun ri lesekese. Ni gbogbo ojo kookan ni Pandit Lekhram nlo be Mirza wo nile re leniti nso bayi fun-un : « Bi eyin ba je olododo ninu aba ti e nda, e fiseyanu melo kan han mi » Mirza kori nkankan se han-an yatosi idorikodo lehin itiju nla nitoripe ohun ti nbere lodo re wipe ko se han owun, a ma sele latara iseyanu ti ki-i wa latowo opuro bi Mirza. Kia-kia ni Pandit ko awon ogogorun Hindeus (Arya) jo ni oja Qadian nibito ti nso kobakungbe oro si Mirza leniti nfi-i se yeye atowun ati ohun ti npeni igbagbo ati ipaya Olohun re. Awon eniyan nrerin takiti, lehin igbanaa Pandit seri pada lo sile pelu idunu ati itelorun.

Mirza Saheb rahun nipa isele yi ninu iwe re, « Faryaad-e-Dard ». Lapejuwe iwe to ko nipa isele yi re :

« Fun gbogbo awon ojo ti lekhram fi finu fedo soro buburu rekoja ala si esin islam, kobakungbe oro, oro ibanuje ti-i wamije loju eni ni nso simi. Ninu awon oro ifiran to so simi, o salaye wipe owun yio wa si Qadian lati foroJomitoro-oro lori awon majenu wiwa gbe Qadian fun iwomba osu kan. Emi ko losi aroko re lo pade re, mi osi fiwe ranse si-i. Ife inure lofiwa si Qadian. Ninu awon oro ifiran re to rekoja ala re, niwaju gbogbo awon hindous to wa laye naa, o gbeQadian fun nkan bi ojo meedogbon ti ko fi simi ninu isoro simi, lojo kankan, oro bi kile o faya ti bomoleti je ni nso simi. Loja ati ni awon ona ti awon musulumi nto ni nduro soro ibanuje, oro yakinlala bi ina bi ogun, awon oro sokutu wowo sokutu wowo si awon musulumi. Beeni nsoro ti-i dajale si Annabi Muhammad (SAW) dedi wipe mo kilo fun awon musulumi wipe ki nwon o mase losibi ipade re nitoripe enikankan kole doju ko-o. ope ni f’Olohun oba toni ki awon musulumi gba ikilo ki nwon o mase lo. Ogoro ninu olala oloye musulumi ni nwon wa desun Pandit funmi ni gbogbo awon ojo yen ti fi nbu Annabi Muhammad (SAW). Mori wipe ara ntawon, ni moba parowa funwon wipe onirin ajo ni Pandit. O wa fun iforoJomitoro oro ni. Moni ki nwon se suru. Ola imoran ti mo gba awon musulumi ni nwon fi koraro dake laïkofesi pelu wipe Pandit ko simi ereke ebu ni sise. Ojoojumo ni Pandit nwa sodo mi wa toro wipe ki nfi awon ami Olohun kan fi han owun abi iseyanu melo kan leniti nfimi se yeye. Pandit a ma wa lowuro abi losan latile wa bu Annabi Muhammad (SAW) ati lati bu enu ete lu esin Islam. Gegebi Asaaju buburu ti elesin Krist Pandit a ma so bayi : « Annabi nyin (SAW) ko siseyanu kankan atipe ikankan ninu awon asotele re ko pada ribee. Awon Mullahs kun iwe nyin fun awon iseyanu latile gbogo sagbega fun esin nyin ni ».

(Fayad-e-Dard Latowo Mirza Ghulam p. A. O wa ninu Raees-e-Qadian Latowo Rafiq Dilawani p 175 – 176).

Mirza loti, agara da-a kole siseyanu kankan.

Gbogbo bi Pandit se nda yeye Mirza sile nita gbangba, to si nyeye esin Islam to nbu Annabi Muhammad (SAW) ninu ile Mirza beena lo ntoro lowo Mirza wipe ko siseyanu melo kan han owun. Kiniba kodi Mirza lati siseyanu koda boba sekan soso Pandit ? Toba sewipe Mirza ba ni agbara kan lododo latifi se awon iseyanu ? Kiwa niyi tori latodo Annabi Muhammad (SAW) ? Kilode ti ko gba fun Pandit, eniti nfojoojumo fi soro si Annabi Muhammad (SAW) ? Lehin igbati o perare ni iranse Olohun eniti Olohun yo nda agbara iseyanu fun, Ese towa dake palolo niwaju Lekhram ?

Awon aba ati oro igberaga ti nbo wonyi wa lati enu Mirza : « Iyato to wa laarin emi ati awon ojise to siwaju mi nipe, mo siseyanu to po beeni asotele mi po to jododo. Niti papa daju-daju awon iseyanu mi ati awon asolete mi koni afiwe ati afijo pelu ti awon ojise ti nwon siwaju mi wa. Awon iseyanu nwon da gegebi itan sugbon awon iseyanu temi ogoro ninu awon eniyan ti nwon foju ri-i nwon le jeri wipe awon iseyanu nla ti ko legbe ni nwon. Ogoro ninu awon eniyan ni agba nla aiye ni nwon jeri re sugbon ti awon ojise ti nwon siwaju mi kotun sikan laiye mo yato siti Annabi Muhammad (SAW) ti mo jeri re ati Al-Qur’an to je ijeri ati itoka aiye raiye. Emi ni eni naa ti ogoro ninu awon eniyan fojuri apakan ninu awon iseyanu ati asolete re ti nwon si jeri si-i. »

(Ikede Mirza Ghulam, Roohani Khazain vol 18 p 460 – 461).

Towun tibee, eri to fojuhan ti aba yi nipe pelu wipe ota esin Islam kan lo sun Mirza kangiri, koda kole siseyanu kansoso han-an.

O foju han kedere wipe kosi ododo eyito fi nkere bi omona igun ninu awon aba ti nda eyiti nfi nperare ni eniti Olohun yan ni iranse re atipe owun ni agbara latile siseyanu abi wipe Olohun sadewun fowun wipe ami Olohun kan yio towo towun sele. Niru akoko itopinpin bee nigbati ota Islam kan nbu enu ate lu Islam to nsoro si ojise nla Muhammad (SAW) nita gbangba, kosi ona ti Olohun kofi ni fi ami re kan han latowo enito gbe dide ni iranse re latile fi gbee nija. Yato sipe kole siseyanu kankan, ko tie bori ota re ninu gbogbo ariyanjiyan ti nwon se lori ododo esin Islam. Kaka iyen, o yi awon musulumi lokan pada, tewon ro wipe ki nwon o mase fun Pandit lesi. Eyi fihan peete-peete wipe itunje iro to fojuhan gberegede ni awon aba ti nda wipe iranse Olohun ni owun, ateyi to fi nso wipe Olohun fihan owun wipe owun yio fi awon ami towun han ni Qadian atipe owun Mirza yo siseyanu. O paromolohun ni enito mo koto dojuti-i niwaju otan esin Islam yi. Igida ! Mirza ko kakosile lori ogiri.

Ona awawi ati itunije miran latowo Mira.

Ipe awon Arya si Mubahila kan.

Lehin iponju ti ori latara isubu itiju to subu niwaju osebo kafir (Lekhram), ni odun 1886, Mirza te iwe kan jade ti akole re nje « Surma charm-e-Arya ». Ninu iwe yi o npe awon alaponle Arya losibi Mubahila. O so wipe awon ami Mubahila yi yio sele lehin odun kan. Lagbara Olohun ninu Al-Fatwa ti nbo, eyin yio ka atele itan Pandit Lekhram, eyito se wipe iku lo wa kehin re, lo pari re.

Ike Olohun ati ola re ko ma bayin.

Dr Syed Rashid Ali.

Dr Seyd Rashid Ali

P.O. BOX : 11560

Fax: 971.9.2442846

Dibba, Al-Fujairah

United Arab Emirates

E-mail: rasyed@emirates.net.ae

 
   
 

[ 1] [2]
:   admin       (   )
: 0 /5 ( 0 )

: 26-11-2009

: 4108